Ìjà àgbà méjì! Aláàfin gbéná wojú Ọọ̀ni lórí òyè Ọkanlọmọ Oodua tó fi Dotun Sanusi jẹ, Ọọ̀ni, Sanusi àti ọ̀pọ̀ ọmọ Yorùbá fèsì

Oríṣun àwòrán, BBC/ Ooni's Palace
Yatọ si ọrọ ija agba to ti maa n waye tipẹ laaarin Ọọni Ile-Ife ati Alaafin Oyo, eyi ti ọpọ eeyan gbagbọ pe ko ṣẹṣẹ bẹrẹ, amọ awuyewuye miran tun ti suyọ ni ana ọjọ Aje laarin awọn ọba meji yii.
Oye kan ni a gbọ pe Ooni Ile Ife; Ọba Adeyeye Ogunwusi, fi gbajumọ oniṣowo, Dotun Sanusi, jẹ, ti a si tun gbọ pe Alaafin Oyo, Oba Abimbola Owoade, fun Ọọni ni ọjọ meji lati gba oye naa pada.
Yatọ si pe orukọ oye ọhun n da ariyanjiyan silẹ, ti awọn kan n sọ pe Ọkanlọmọ ilẹ Yoruba ni Ọọni fi Sanusi jẹ, ti awọn mi-in si tun ni Ọkanlọmọ Oodua ni, ohun to tun n fa ẹjọ ni atẹjade kan to ti Aafin Oyo wa lori Oye naa.
Ninu atẹjade naa ti Akọwe iroyin Alaafin Owoade, Bode Durojaiye, fi sita lo ti ni afojudi lo jẹ fun Ile Ife lati da nikan fi eeyan jẹ oye to ni i ṣe pẹlu gbogbo ilẹ Yoruba, iyẹn Okanlọmọ Ilẹ Yoruba.
Atẹjade naa sọ pe Alaafin Oyo nikan lo lẹtọọ lati fi eeyan jẹ oye to ba ti kan ilẹ Yoruba lapapọ.
Fun idi eyi, atẹjade lati Aafin Oyo naa paṣẹ pe ki Ọọni gba oye ọhun pada kia laaarin ọjọ meji.
Eyi lo si fa a ti ọrọ naa fi n gbilẹ bii ina inu ọyẹ.
Ọpọ eeyan n sọ pe ki lo ṣẹlẹ gan-an ti atẹjade ti wọn ti lo ede abuku bẹẹ fun Ooni yoo fi ti Oyo wa.
Awọn mi-in n sọ pe Oyo n dana ọtẹ ni, bẹẹ lawọn kan n sọ pe oye wo gan-an ni Ọọni fi Dotun Sanusi jẹ.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Kí ni Dotun Sanusi fúnra rẹ̀ wí?
Lọjọ Aiku ọsẹ yii ni Ooni Adeyeye Ogunwusi (Ojaja Keji), fi Oloye Dotun Sanusi jẹ oye.
Alaaye to wa ninu oye naa ni pe Ọkanlọmọ Oodua ni Ọọni fi Dotun Sanusi jẹ.
Ki i ṣe Ọkanlọmọ Ilẹ Yoruba ti igun Alaafin Oyo tori rẹ ni ki wọn gba oye naa pada.
Gẹgẹ bi Dotun Sanusi funra rẹ ṣe kede loju opo ayelujara rẹ, o ni
" Apọnle nla lo jẹ fun mi lati kede pe wọn ti fi mi jẹ oye Ọkanlọmọ ilẹ Oodua, lati ọwọ Ooni Ile Ife, Oba Enitan Adeyeye Ogunwusi. (Ojaja 11).
Sanusi tẹ siwaju pe nibi eto kan ti Ọonirisa gbe kalẹ, iyẹn oju opo iṣẹmbaye ti wọn ṣe lọna ẹrọ igbalode, ni wọn ti fi oye naa da oun lọla.
'2GEDA' ni wọn pe orukọ agbekalẹ naa, ilu Ibadan ni ifilọlẹ rẹ si ti waye.
Iwadii fi han pe ajọṣepọ ọlọdun pipẹ lo wa laaarin Ooni Adeyeye Ogunwusi ati Dotun Sanusi.
Iroyin si sọ pe ọdun karun-un ree ti Ooni ti fi oye naa sọri Dotun Sanusi, wọn ko wulẹ wuye naa nitori arun Corona to gbode nigba naa ni.
Lọjọ Aiku ọsẹ yii ni Ooni Adeyeye Ogunwusi (Ojaja Keji), fi Oloye Dotun Sanusi jẹ oye.
Alaaye to wa ninu oye naa ni pe Ọkanlọmọ Oodua ni Ọọni fi Dotun Sanusi jẹ.
Ki i ṣe Ọkanlọmọ Ilẹ Yoruba ti igun Alaafin Oyo tori rẹ ni ki wọn gba oye naa pada.
Agbẹnusọ Ooni fèsì sí gbèdéke ọjọ́ mèji ti Alaafin fun Ọọni láti wọ́gilé oyè Ọkanlọmọ, ó ní ìhàlẹ̀ lásán ni
Lati mọ iha ti Oonirisa kọ si gbedeke ọjọ meji ti Alaafin fun un lati gba oye naa pada, BBC News Yoruba kan si Aafin Ile Ife laaarọ ọjọ Iṣẹgun oni ti i ṣe ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹjọ ọdun 2025.
Otunba Moses Olafare, ọga nipa eto iroyin Aafin Ife, lo kọkọ ba BBC News Yoruba sọrọ.
Olafare sọ pe bawo ni Ooni yoo ṣe fi eeyan jẹ oye Ọkanlomo ilẹ Yoruba.
O ni o yẹ ki Bode Durojaiye, to kọ atẹjade lati Aafin Oyo kọkọ wadii oye ti wọn fi Dotun Sanusi jẹc, ko to gbe ọrọ to gbe jade naa sita.
Lẹyin eyi ni Olafare fi atẹranṣẹ ṣọwọ, ninu eyi to ti ni:
"Ṣókí láti Ààfin Ooni''
Lati ọdọ ọga mi, wọn ti paṣẹ fun mi lati maṣe fi atẹjade kankan sita fun ẹyin oniroyin lori ihalẹ lasan ti Alawada Babasala n ṣe.🤣🤣🤣🤣
Ẹ o ni i binu pe mi o ṣe ohun ti ẹyin oniroyin n fẹ.
"A ko le maa pẹlu ọbọ jawura nipa fifun wọn lesi ti ko pọn wa le.
"A ti fi ọrọ naa silẹ fun ẹyin eeyan lati maa dajọ rẹ ni kootu awujọ to wa, ti ẹ si ti n gbọ ẹjọ naa lọwọ.
"Kaka ka dahun si iru eyi, ẹ jẹ ka kuku gbaju mọ awọn ọrọ to le mu iṣọkan wa duro giri, yatọ si awọn eyi to le pin wa niya.
"Ko si atẹjade oniroyin🙏🏻
"Ọjọ meji nikan kọ...!!!"
Bẹẹ ni atẹjade ranpẹ to ti Aafin Ooni Ogunwusi wa naa sọ.

Ọ̀pọ̀ ọmọ Yorùbá koro ojú sí aáwọ̀ tó ń wáyé láàrin Alaafin ati Ọọni
Ohun kan ti ọpọ eeyan tun n kọminu si ninu iṣẹlẹ yii, ni pe ṣe Alaafin Owoade mọ nipa atẹjade onigbedeke ọjọ meji naa ko too jade.
Tabi pe ṣe Akọwe iroyin rẹ lo n da iṣẹ jẹ lọwọ ara rẹ pẹlu awọn ọrọ ti wọn lo tabuku to lo ninu atẹjade naa.
Ẹ o ranti pe laipẹ yii ni Alaafin Abimbola Owoade ba BBC News Yoruba sọrọ ninu ifọrọwerọ ti a ṣe pẹlu ọba naa, to si fi da wa loju pe oun ko ba ẹnikẹni ja.
Kabiyesi Owoade sọ pe ija kankan ko si laaarin oun ati Ooni Adeyeye Ogunwusi.
O ni awọn eeyan to fẹẹ fi iroyin pawo sapo ara wọn lo fẹẹ da rugudu silẹ, ti wọn n gbe ohun ti ko ṣẹlẹ kiri.
Ọpọ eeyan nilẹ Yoruba lo ti n koro oju si atẹjade to ti aafin Oyo wa yii, ti ọrọ naa si n tan kalẹ si i.
Idahun ni awọn mi-in si n wa, si iyatọ to wa ninu Ọkanlomo Oodua ati Ọkanlọmọ ilẹ Yoruba.
Mogaji ilẹ̀ Ibadan náà fèsì
Lara awọn ọmọ Yoruba to ti koro oju si iṣẹlẹ yii ni Mogaji ilẹ Ibadan, Oloye Abass Oloko.
Oloye Oloko bu ẹnu atẹ lu gbedeke ọjọ meji ti Alaafin fun Ooni ninu atẹjade to fi sita.
O ni gbedeke ọjọ meji yii jẹ fifi abuku kan aṣa ilẹ Yoruba to ti wa lọdun pipẹ sẹyin.
Bakan naa ni ẹnikan, Elu omo Elu, sọ pe bi wọn yoo ba yan eeyan sipo ẹni ti yoo maa kọ iroyin fun aafin, ẹni to ni imọ kikun lo gbọdọ jẹ.
Elu Omo Elu sọ pe ọrọ ikilọ ti ẹni to n jẹ Bode Durojaiye kọ naa tini loju, ko si ṣee ronu ẹ rara pe eeyan kan le lo awọn ọrọ alufanṣa bẹẹ, nitori pẹlẹ lakọ o labo.
O ni ifẹ ni Ooni fi n han si Oyo lọjọ to ti pẹ, ṣugbọn o jọ pe Oyo ki I da ifẹ naa pada.
Elu fi kun un pe nnkan abuku ni fun Alaafin to ṣẹṣẹ de ori itẹ lati maa ran iru iṣẹ bẹẹ si Ooni Ogunwusi to n lo ọdun kẹwaa lọ nipo ọba.
Bakan naa lo ni awọn eeyan nla bii Oloogbe Awolowo ati iyawo rẹ, pẹlu awọn oloṣelu nla bii Atiku, Odili ni Ooni Sijuade fi joye ri nigba aye rẹ, ti ko si fa awuyewuye lati ibi kankan.
O ni Dotun Sanusi ti wọn fi joye ti funra ẹ sọ pe Okanlomo Oodua ni oun jẹ, ewo ni Bode Durojaiye n kọ ohun ti ko ṣẹlẹ si.
O ni boya Durojaiye fẹẹ fi ọrọ yii lokiki, tabi ko fẹẹ fi da wahala silẹ ko si fi eyi koju Ooni ni.
Ẹ o ranti pe laipẹ yii ni Alaafin Abimbola Owoade ba BBC News Yoruba sọrọ ninu ifọrọwerọ ti a ṣe pẹlu ọba naa, to si fi da wa loju pe oun ko ba ẹnikẹni ja.
Kabiyesi Owoade sọ pe ija kankan ko si laaarin oun ati Ooni Adeyeye Ogunwusi.
O ni awọn eeyan to fẹẹ fi iroyin pawo sapo ara wọn lo fẹẹ da rugudu silẹ, ti wọn n gbe ohun ti ko ṣẹlẹ kiri.














