Ìdí tí Alaafin fi máa ń kúrò nípò ọba lásìkò ọdún Sango nílùú Oyo

Oríṣun àwòrán, The Alaafin Oyo/Instagram
Lonii ni ọdun Sango to n lọ lọwọ niluu Oyo yoo kaṣẹ nlẹ, oriṣiiriṣii eto ni yoo si waye nibi ajọdun naa lonii l'Oyo.
Oriṣa Sango ati Alaafin Sango kii ṣe ọkan naa sugbọn itan fi idi rẹ mulẹ pe iwa Sango Orisa tawọn Yoruba gbagbọ pe o rọ wa ile aye naa lo wa lara Sango Alaafin.
Ohun iyalẹnu lo jẹ nigba ti awọn oniSango sọ pe, Alaafin ti ilu Oyo, Oba Akeem Owoade, ko gbodọ foju kan ẹni to ba wọ aṣọ Sango jade lasiko ọdun.
Wọn tun fidi rẹ mulẹ pe o ti di eewọ fun Alaafin lati pada si ilu Koso to ti gba Ade Sango lasiko ifinijoye rẹ.
Ka to tẹnu bọrọ, ẹ jẹ ka sọ diẹ nípa Alaafin Tella Oko àti Ọdún Sango.
Bawo ni wọn ṣe n ṣe Ọdun Sango?

Nilẹ Yoruba, ayẹyẹ ọdun Sango ni wọn maa fi n ṣe idanimọ ibẹrẹ ọdun tuntun.
O jẹ ajọdun iṣẹmbaye to maa n waye ni aafin Koso.
Ajọdun ọlọjọ mẹwaa yii ni ṣe pẹlu aṣa, isẹṣe ati ẹsin abalaye niluu Oyo.
Ni iranti Tella Oko, Alaafin Oyo Kẹta ti wọn gbagbọ pe o jẹ atunwa Sango ni wọn fi n ṣe ajọdun yii.
Nigba ti wọn ba bẹrẹ ajọdun yii loṣu Kẹjọ, awọn ẹlẹsin Sango maa n pin iṣu sisun, wọn si maa n fi epo pupa jẹ ẹ.
Ati ọkunrin ati obinrin lo maa n di irun wọn ti wọn si maa n wọ aṣọ pupa pẹlu ilẹkẹ lọrun wọn.
Tilu tifọn ni wọn fi n ṣe ajọdun yii ti o si jẹ anfaani fawọn eeyan ni paapaa julọ awọn ọmọde lati mọ nipa aṣa ati iṣẹṣẹ awọn babanla wọn.
Ki eeyan to le mọ nipa agbara Sango ati ko to le ni iru agabara naa, eeyan bẹẹ gbọdọ kopa ninu idanilẹkọ gẹgẹ bi ọmọlẹhin Sango.
Ọdun to n mu irẹpọ wa laarin awọn eeyan ipinlẹ Oyo ni ayẹyẹ ajọdun Sango jẹ.
Jake jado Naijiria ati lẹyin odi si ni awọn eeyan ti maa n wa kopa ninu ajọdun yii to maa n waye loṣu Kẹjọ ọdọọdun.
Kí lo de ti Alaafin ko fi gbọdọ foju ba ẹni to ba wọ aṣọ Sango lasiko ọdun?

Ọtun baba apẹẹrẹ Sango niluu Oyo, Oloye Sangowale Babalola, ba BBC News Yorùbá sọrọ pe irinajo ẹnikẹni to ba jẹ Alaafin bẹrẹ lati gbongan Sango to wa ni ilu Koso, nibẹ naa lo si ipari si.
Oloye Babalola ni ẹnikẹni ti yoo ba jẹ Alaafin gbọdọ gba Ade Sango niluu Koso, to ba si ti gba a tan, ko gbodo pada si ilu naa mọ titi ti yoo fi jade laye.
O tesiwaju pe eyi lo difa fun Alaafin ti ko ṣe gbọdọ fi oju kan ẹnikẹni to ba wọ aṣọ Sango lasiko ọdun nítorí Ọba meji ko gbọdọ wa ni aafin.
"Baba ní Sango jẹ fun Alaafin, ọba meji ko si gbọdọ wa ni aafin ni o fa tí Alaafin fi maa n fipo silẹ lasiko ti Sango ba n jade.
"Fun asiko ti Sango yoo fi pidan ni aafin, ko gbọdọ foju rí Alaafin.
"Bẹẹ si ni pe Alaafin ko gbọdọ wa si ilu Koso, to jẹ ibi tí a ti n bọ Sango titi yoo fi jade laye,'' Oloye Babalola lo ṣalaye bẹẹ.















