Kí ló fa gbas-gbos láàrín Pásítọ̀ Fatoyinbo ìjọ COZA, ìjọ CAC àti ẹbí, Apostle Ayo Babalola?

Pasitọ ijọ COZA, Biodun Fatoyinbo ati Wolii Ayo Babalola

Oríṣun àwòrán, Biodun Fatoyinbo/Facebook/ CAC World News

Àkọlé àwòrán, Aworan Pasitọ Biodun Fatoyinbo ati Oloogbe Aposteeli Ayo Babalola
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Pasitọ ti awọn eeyan ki i deede gbọ orukọ rẹ ni Biodun Fatoyinbo, ti ijọ Commonwealth of Zion Assembly (COZA), ṣugbọn bi orukọ naa yoo ba jade, o maa n saaba mu awuyewuye dani.

Lasiko yii, aforiji ni Pasitọ Fatoyinbo n tọrọ lẹyin ọrọ to sọ si Oloogbe Ẹni ọwọ Ayo Babalola, Oludasilẹ ati Alufaa agba ijọ Christ Apostolic Church (CAC) lagbaaye.

Latigba ti Biodun ti sọrọ naa ni ọpọ eeyan ti n koro oju si i, paapaa ijọ CAC ati awọn ọmọ Ẹni ọwọ Ayo Babalola.

Kí ni Pásítọ́ Fatoyinbo sọ sí Apostle Ayo Babalola?

Ninu fidio kan to gba ori ayelujara kan ni Pasitọ Biodun Fatoyinbo ti ni loootọ ni Apostle Babalola jẹ ẹni ami ororo, ṣugbọn gbogbo oore ọfẹ to ni lo ti parẹ, nitori Alufaa naa ko lowo lọwọ.

Bakan naa ni pasitọ ijọ COZA yii tun beere, pe ta lo gburoo awọn ọmọ Wolii Babalola paapaa mọ, ko sẹni to mọ ibi ti wọn sọlẹ si.

Ṣugbọn ni bayii, Fatoyinbo ti sọ pe oun ko sọrọ naa lati tabuku Oloogbe Babalola ati awọn ọmọ rẹ, bi ko ṣe lati ni imọ kikun nipa Bibeli, ihinrere ati owo nini.

Koda, pasitọ ijọ COZA naa ti tọrọ aforiji loju opo Facebook rẹ l'Ọjọbọ ana ti i ṣe ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹjọ ọdun 2025.

Fatoyinbo ni oun ko jẹ sọrọ abuku si Aposteeli agba; Ayo Babalola, bẹẹ ni oun ko mẹnuba awọn ọmọ rẹ nibi kankan.

Ṣugbọn ọrọ naa ti bi wahala lori ayelujara, ọpọ eeyan koro oju si pẹlu bi wọn ṣe ni ọrọ to ju ẹnu rẹ lọ lo sọ nipa Ẹni ọwọ Ayo Babalola.

Bakan naa ni ijọ CAC fesi pada fun Fatoyinbo, awọn ọmọ Baba naa to si ni nibo ni wọn wa ti jade tan fun un pẹlu.

Aworan Pasitọ Biodun Fatoyinbo nigba to n waasu pẹlu ẹrọ gbohun-gbohun, awọn eeyan wa leyin rẹ ninu aworan naa

Oríṣun àwòrán, Pastor Biodun Fatoyinbo/ Instagram

Àkọlé àwòrán, igba akọkọ ti Pasitọ Fatoyinbo yoo maa luwẹ ninu agbami awuyewuye kọ niyi

CAC fèsì padà fún Fatoyinbo

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lati fi han Pasitọ Fatoyinbo pe ohun to sọ si Ẹni ọwọ Babalola naa ko le lọ bẹẹ, Oludari ikẹdẹ fun ijọ CAC, Ade Adewole, fesi pada ninu atẹjade to fi sita pe:

" Lati maa fi aṣeyọri ẹmi we ọrọ̀ aye, lodi si ẹkọ ti Bibeli kọ wa. Ọrọ Jesu ko ruju, o ni:

" Kiyesi ki e si sora fun ojukokoro nitori wipe oju eniyan kii duro nipa opo oun ti o ni-Luke 12:15."

" Bi a ba fi oju inu wo o, Apostle Babalola bimọ. Arojinlẹ ranpẹ si yẹ ko fi ye ọ pe awọn ọmọ rẹ yoo ti di ogbo lasiko yii, koda, o ṣee ṣe ki wọn jẹ ẹgbẹ awọn obi rẹ agba.

"Ki lo fẹẹ gba ninu ibeere apẹgan ti o beere pe nibo ni awọn ọmọ Babalola wa?''

Atẹjade CAC naa sọ pe ọrọ ti Fatoyinbo sọ ti ṣafihan iru awọn eeyan to n ba rin, wọn ni nibo lo ti kọ Bibeli tirẹ to fi jẹ pe ọrọ aye lo fi n ṣakawe oriire ijọba ọrun.

Bakan naa ni ijọ CAC sọ pe ṣe bi Bibeli lo yẹ ko ṣe atọna ọrọ ti yoo maa ti ẹnu pasitọ wa, ati pe ṣe ki i ṣe ọkanjua, ijẹkujẹ ati aibẹru Oluwa ni ẹkọ ti Biodun Fatoyinbo n kọ awọn eeyan bayii, paaapaa ni Naijiri ti ohun to tọ ko fi bẹẹ si mọ, to jẹ bo ti gba ni aye n ba kiri.

Ijọ CAC ni oun ko ba ma da Fatoyinbo loun, ṣugbọn iwe mimọ Bibeli sọ pe ki eeyan da omugọ loun, ko ma baa fi agọ rẹ ṣi ọpọ eeyan lọna.

Wọn ni eyi lo fa a tawọn fi fẹ ko ye Pasitọ ijọ COZA, pe kekere kọ ni baba fi ju ọmọ lọ, Ayo Babalola ki I ṣe ẹni a n yajuu si.

''Awa ọmọ Ayo Babalola ree, baba wa ki i ṣe oloṣi nigba aye rẹ, ẹlẹyinju aanu ni''

Akọbi Aposteeli Ayo Babalola lobinrin, Mama Eunice Wuraola Ogini

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àkọlé àwòrán, Akọbi Aposteeli Ayo Babalola lobinrin, Mama Eunice Wuraola Ogini ni oṣi kò si ni iran wọn, ifaraẹnijin fun iṣẹ aanu ni baba awọn atawọn paapaa yan laayo.

Ni itẹsiwaju esi ọrọ fun Biodun Fatoyinbo, ọkan lara awọn ọmọbinrin meji ti wọn jẹ ọmọ bibi inu Wolii Ayo Babalola, Mama Eunice Wuraola Ogini, ṣe fidio to fi ṣalaye iwa baba rẹ, ati iru eeyan to jẹ gan-an nigba aye rẹ.

"Orukọ mi ni Eunice Wuraola Ogini, akọbi lobinrin fun Apostle Joseph Ayo Babalola, mo si fẹẹ sọ ọ gedegbe pe awa ọmọ rẹ tẹle ilana rẹ. Emi ati aburo mi obinrin n sin Oluwa, a fẹran Oluwa.

"Dikinẹẹsi obinrin ni mi ni ni ṣọọṣi mi, afadurajagun ni mi, mo si tun jẹ olukọ ileewe ọjọ isinmi.

''Aburo mi; Deborah Apeke Adeniyi naa jẹ afaradurajagun ati Efanjẹliisi, a si n gbe igbesi aye irọrun laaye wa.

''Eyi ri bẹẹ nitori baba mi ti furugbin aanu, ati itọrẹ aanu silẹ fun wa.

''Mo ranti daadaa, nigba ti mo wa ni kekere, ile wa maa n kun fọfọ fun oriṣiiriṣii awọn eeyan ti wọn ba aanu wa ni.

''Baba wa maa n fi awọn mi-in sileewe, wọn a fi awọn mi-in sile ẹkọṣẹ.

" O fun wón nigbesi aye irọrun, aanu Olorun lori aye rẹ si leyi''

Dikinẹẹsi Ogini ṣalaye pe igbesi aye irẹlẹ ti baba oun gbe ni awọn ọmọ rẹ naa n gbe, aanu ṣiṣẹ ati ifẹ Ọlọrun si ni akọmọna aye awọn.

O ni eyi ko tumọ si pe awọn parẹ mọ aye lara rara.

Pasito Biodun Fatoyinbo atawọn awuyewuye to rọ mọọ ṣaaju akoko yii

Ọjọ akọkọ ninu oṣu Kin-in-ni ọdun 1975 ni wọn bi Pasitọ agba ijọ Commonwealth of Zion Assembly (COZA), Biodun Fatoyinbo.

Ọmọ mẹrin ni awọn obi rẹ bi.

Yunifasiti ilu Ilorin ni Biodun Fatoyinbo ti kawe, ilu naa lo si fi ori ijọ rẹ sọlẹ si ni 1999, ko too maa lọọ gbe niluu Abuja to wa bayii.

Modele Fatoyinbo ni iyawo Biodun.

Wọn fẹsun ifipanilopọ kan Pasitọ Biodun Fatoyinbo

Aworan Pasito Biodun Fatoyinbo ati Abilekọ Busola Dakolo

Oríṣun àwòrán, @Pastor Biodun Fatoyinbo/@Busola Dakolo

Àkọlé àwòrán, Aworan Pasito Biodun Fatoyinbo ati Abilekọ Busola Dakolo

Ni 2019 ni obinrin kan, Busola Dakolo, ti ọkọ rẹ jẹ olorin taka-sufee, Timi Dakolo, fi ẹsun ifipabanilopọ kan Biodun Fatoyinbo.

Ọrọ naa di ariwo to bẹẹ ti awọn eeyan ṣe iwọde tako Fatoyinbo, ẹgbẹ ajafẹtọọ ọlọkan-o-jọkan si da si i .

Bakan naa ni ẹjọ naa de kootu pẹlu.

Alaye ti Busola ṣe nigba naa ni pe ẹẹmeji ni Fatoyinbo fipa ba oun lo pọ ni ilu Ilorin, iṣẹlẹ naa si ti pe ogun ọdun koun too sọ ọ jade.

Ọrọ naa le de bi pe Fatoyinbo yẹba ni ṣọọṣi.

O sọ nigba naa pe ki i ṣe nitori oun jẹbi ẹsun naa, ṣugbọn ohun to yẹ lati ṣe loun ṣe yẹn.

Lẹyin ti ariwo naa lọ silẹ pata lo si too ṣẹṣẹ pada.

Ni 2023 ni Biodun Fatoyinbo kede pe oun n koju ailera nla kan, eyi to mu ko ru hangogo, ti ko si jẹ ko le maa yọju si awọn ode awujọ.

O gboriyin fun Bishop David Oyedepo nigba to pada sori itage, o ni baba naa gba adura foun gan-an.

Onkọwe ni Biodun Fatoyinbo, bakan naa ni awọn eeyan si mọ oun ati iyawo rẹ bii ẹlẹyinju aanu to maa n fi owo, ounjẹ ati aṣọ ta awọn alaini lọrẹ.

Ninu aforiji to beere lori ọrọ wolii Ayo Babalola yii, Biodun Fatoyinbo sọ pe oun paapaa ti jẹ anfaani ijọ CAC, oun ti mu omi ọgbọn ijọ naa bii awọn ijọ yoku naa ṣe ti jere lara CAC.

Fun idi eyi, o loun ko gbero lati tabuku Alufaa agba Ayo Babalola, bẹẹ loun ko rin awọn ọmọ baba naa fin, ki wọn dakun fori jin oun.