Wo ìdí tí ìjoba ṣe gbẹ́sẹ̀lé ìdásílẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ gíga kankan ní Nàìjíríà fún ọdun méje

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Tinubu
Ijọba apapọ ti fofin de idasilẹ ile ẹkọ giga fun ọdun meje gbako ni Najiria lati asiko yii lọ.
Awọn ile ẹkọ ti ọrọ yii kan ni idasilẹ fasiti, ile ẹkọ gbogboniṣe atawọn ile ẹkọ awọn olukọni.
Ijọba ni eredi igbesẹ yii ko ṣẹyin bo ṣe wi pe ọpọlọpọ ile ẹkọ giga lo wa ni Naijiria amọ ti wọn ko ṣiṣẹ bo ṣe yẹ, awọn ohun elo ikẹkọọ ko to lawọn ile ẹkọ kan, nigba ti ko si ojulowo ẹkọ mọ lawọn ile ẹkọ mii.
Ọjọru ni igbimọ iṣakoso ijọba apapọ Naijiria buwọlu igbesẹ tuntun yii nibi ipade ilu ti Aarẹ Bola Tinubu dari rẹ niluu Abuja.
Amọ ṣa, ijọba buwọlu idasilẹ fasiti mẹsan an mii nibi ipade ọhun.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade naa, minisita fun eto ẹkọ, Tunji Alausa sọ pe ọpọlọpọ ile ẹkọ giga lo wa ni Naijiria amọ ẹkọ ti awọn eeyan n kọ nibẹ ko kunju oṣuwọn, eyii ti ko yẹ ko ri bẹẹ.
O fi kun pe pupọ ninu awọn ile ẹkọ naa ni ko ni awọn akẹkọọ, nigba ti awọn mii ko ni iye olukọ to yẹ.
Alausa sọ pe "ọpọ fasiti ijọba ni ko ṣiṣẹ to oju iwọn wọn, bẹẹni iye awọn akẹkọọ to wa ni fasiti miran din diẹ i ẹgbẹrun meji.
"Ni fasiti kan ni iha ariwa, oṣiṣẹ to wa nibẹ jẹ ẹgbẹrun kan o le igba, bẹẹ gbogbo akẹkọọ to wa ni fasiti naa ko ju ẹgbẹrin lọ."
O fi kun pe awọn fasiti igba o din ẹyọ kan kan wa lorilẹede Naijiria bayii to jẹ wi pe iye awọn akẹkọọ to ṣe idanwo lati wọ ibẹ ninu idanwo ajọ JAMB ko to ọgrun un, koda o ni awọn mẹrinlelọgbọn miran kan tilẹ wa ti akẹkọọ kankan ko ṣe idanwo lati wọ ibẹ.
Minisita naa tẹsiwaju pe ninu ile ẹkọ gbogboniṣẹ marundinlọdunrun, awọn kan wa ti akẹkọọ to ṣe idanwo lati wọ ibẹ kẹkọọ ko ju mokandinlọgọrun lọ.
Ni ti awọn ile ẹkọ ikọṣẹ iṣẹ olukọ okoolelugba o din ẹyọkan, ọpọ akẹkọọ ko tilẹ mu ibẹ fun ẹkọ wọn ninu idanwo JAMB to kọja.
Alausa ni ti ijọba ko ba tete gbe igbesẹ to yẹ lori awọn ile ẹkọ ti ko ba igba mu, eto ẹkọ ni Naijiria yoo dagẹgẹ.
O ni asiko ti wọn fofin de idasilẹ awọn ile ẹkọ yii yo fun ijọba lanfani lati na owo si awọn ile ẹkọ to wa nilẹ bayii ki wọn le ba igba mu dipo ki wọn maa buwọlu idasilẹ awọn mii.















