ìdí tí àwọn onílù fi ka ẹsẹ̀ mẹ́ta sẹ́yìn tí wọ́n sì kọ ẹ̀yìn sílé Olubadan tó wàjà

Aworan awọn onilu ni aafin Olubadan

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn onilu ati kakaaki Ọba ko ṣee fi ọwọ rọ sẹyin ninu iṣẹdalẹ aṣa ati iṣe ile Yoruba nitori pe awọn gan an ni a a ba maa pe ni eti ọba nile, eti ọba l'oko.

Ni ọpọlọpọ ilu sini awọn onilu to n bẹ l'aafin ti maa n ba gbogbo ọba to ba jẹ ṣiṣẹ pọ. Apẹrẹ iru ẹ ni awọn onilu Olubadan ilẹ Ibadan.

Gbogbo aye lo mọ wi pe ọkan lara awọn oriki ọmọ bibi ilẹ Ibadan ni "Ọmọ Agbọtikuyọ", nitori pe ki Olubadan kan to waja ni awọn eeyan ti n mọ ẹni ti oye naa kan. Nigba ti ọlọjọ ba si de, bi idile ọba to waja ba ṣe n ṣọfọ ni mọlẹbi ẹni ti oye Olubadan kan yoo gba ilu ti wọn o si maa kọ orin "o yi biribiri kan wa".

Bo ti wu ki awọn onilu Olubadan fẹran ọba to waja to, laipẹ laijina, awọn naa o ko ilu wọn lọ si ọdọ ọba tuntun.

Ni nnkan bii ọjọ meji sẹyin ni fọrankan kan de ori itakun ayelujara to n ṣe afihan bi awọn onilu Olubadan to waja, Ọba Owolabi Ọlakulẹhin ṣe lu ilu ti wọn si tun fọn fere ikẹyin nilẹ Oloogbe naa, ti o tumọ si wi pe iṣẹ wọn ti pari nile Olubadan ana.

Nnkan iyalẹnu mii ti wọn tun ṣe ni bi wọn ṣe ka ẹsẹ mẹta sẹyin ti wọn si yi oju pada ki wọn to kuro nile naa. Ibeere to n bẹ lọkan awọn eeyan lori igbesẹ yii lo mu ki BBC Yoruba kan si gbajugbaju onilu nilẹ Ibadan, Atokowagbowonle Ayanyẹmi pe ki wọn ba wa tan imọlẹ si nnkan ara ti awọn onilu Olubadan ṣe.

Ayanyẹmi ni gbogbo Olubdan to ba jẹ ni awọn onilu naa yoo ba ṣiṣẹ nitori pe titi lailai ni iṣẹ awọn onilu ni aafin Olubaan.

O tẹsiwaju wi pe ẹsẹ mẹta ti wọn ka sẹyin ati bi wọn ṣe yi oju pada tumọ si wi pe iṣẹ wọn ti pari nile Olubadan ana, ibi ti wọn si n lọ bayii ni ọdọ Olubadan tuntun, Ọba Raṣidi Ladọja.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O ni, "Iṣẹ titilae ni wọn n ṣe. Ẹ mọ pe ẹjẹ ti wọn ilu ẹjẹ. Wọn yi ara wọn kuro lara baba nuu. Ẹ mọ pe wọn ni esu o jẹ tan, esu o lọ, ki Ọlọrun ma jẹ ki awa naa tii ku bayii."

Ayanyẹmi fi kun ọrọ rẹ wi pe awọn onilu naa ko ni nnkan kan ṣe mọ nile Olubadan ana, ayafi ti wọn ba tun pade awọn ọmọ ọba naa ni ode.

Bakan naa ni a kan si Kakaaki Olubadan to n le iwaju awọn onilu, Taiwo Ademọla Peter to ṣe alaye fun akọroyin wa wi pe o ni bi awọn ṣe maa n ki Olubadan laarọ, ṣugbọn nigba ti ipapoda ti de, o ni bi awọn ṣe gbudọ fọn fere.

Peter ni, "Gbogbo ọba ti o ba ti jẹ nilẹ Ibadan ni mo n ba ṣiṣẹ. Lẹyin igba ti a ba ṣe gbogbo ayẹyẹ oku yii tan ti wọn ba wọlẹ tan, lẹyin ọjọ kẹta a a wa dagbere ninu ẹbi wọn, a a fọn fere, a a lu ilu, a a wa ko ilu kuro nibẹ, a a jọ wa ko o lọ si ile ẹni ti ọba ba kan."

O ni ko si bi arugbo eeyan ṣe le dagba to ti a a sọ pe ki o ma lọ, nitori pe asiko tiwọn lo to.

Peter ṣe apejuwe Ọba Owolabi gẹgẹ bii eeyan daadaa ti kii fẹ iyanjẹ, t ko si fi ebi pa awọn oṣiṣẹ rẹ titi ti ọlọjọ fi de.

O fi kun ọrọ rẹ wi pe ki Olubadan ana to gun ori itẹ ni o ti n ṣe daadaa.