NYSC sọ ìdí tó fi kọ̀ láti fún àgùnbánirọ̀ ní ìwé ẹ̀rí, tún fi oṣù méjì fún ọdún rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Other
Ajọ to n risi agunabnirọ lorilẹede Naijiria, NYSC ti ṣalaye idi ti wọn fi kọ lati fun ọkan ninu agunbanirọ wọn, Ushie Rita Uguamaye ni iwe ẹri pe o kopa ninu sisin orilẹede Naijiria, ti wọn si tun fi oṣu meji kun akoko to yẹ ko fi sin ilu.
Ninu atẹjade ti wọn fi lede lọjọ Aiku, NYSC ni, Arabinrin Uguamaye pẹlu nomba idanimọ LA/24B/8325, ẹni ti ọpọ mọ si Raye n koju ijiya pe o kuna lati fara rẹ han fun ayẹwo NYSC ti oṣu Kẹrin ọdun 2025.
NYSC tun wọgile iroyin to ni pe wọn gbe igbesẹ yii nitori ọrọ kobakungbe ti agunbanirọ yii sọ si iṣejọba Aarẹ Bola Tinubu.
"Lati tan imolẹ si iroyin ofege to n lọ kiri pe a ko fun agunbanirọ ni iwe ẹri nitori o sọ ọrọ kobakungbe si ijọba, eyi lo jẹ iro to jina si otitọ ," atẹjade naa ṣalaye.
"Rita jẹ ọkan lara awọn agunbanirọ 131 ti a kọ lati fun ni iwe ẹri leyin ti wọn sẹ si ofin NYSC. Ni ti ọrọ Rita, a fi oṣu meji kun ọjọ to yẹ ko lo nitori o kuna lati lọ fun ayẹwo NYSC oṣu Kẹrin, eyi to lodi si ofin NYSC.
"O ṣe koko ki a jẹ ki ilu mọ pe eyi kii ṣe pe a gbe igbesẹ nitori iwa to hu ṣaaju ."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju laaarin agunbanirọ naa ati NYSC?
Agunbanirọ yii, Ushie Rita Uguamaye, ṣe fidio lati bu ẹnu atẹ lu aarẹ Bola Ahmed Tinubu lori ipo ti eto ọrọ aje Naijiria wa, to si tun sọrọ kobakungbe si ipinlẹ Eko, pe ilu naa n run pupọ.
Bo tilẹ jẹ pe Uguamaye tọrọ aforijii lọwọ awọn olugbe ipínlẹ Eko fun ọrọ to sọ pe ìpínlẹ Eko n run, o sọ ninu fidio kan to ṣe pe gbogbo nnkan ti gbowo lori ati pe ko rọrun fun araalu lati ra ẹyin atawọn ounjẹ mii mọ.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, Aarẹ Bola Tinubu ko ṣe daadaa to nibi to ba eto ọrọ aje Naijiria de, gbankọgbi iya lo si n jẹ araalu
Agunbanirọ naa ni "Aarẹ Bola Tinubu, ijọba yin ko san araalu rara, aarẹ buruku ni yin, Tinubu, aarẹ buruku ni ọ.
"Ilu Eko n run gidi, ko si ibi ti eeyaan lọ niluu Eko ti kii run, ojo ni wa bi a ṣe kọ lati sọrọ soke lori awọn ohun ti ijọba n ṣe ti ko tẹ awa araalu lọrun."
"NYSC n ko dun koko mọ mi"
Lẹyin to ṣe fidio naa tan ni ọpọ araalu bẹrẹ si n fi erongba wọn han lori rẹ.
Bi awọn kan ṣe n kan sara si ọdọbinrin ọhun ni ọpọ awọn mii n bu ẹnu atẹ lu u pe ko lẹtọọ lati maa sọrọ kobakungbe si ijọba to wa lode latari pe o ṣi sin ilu lọwọ gẹgẹ bii agunbanirọ.
Ọjọ keji ti fidio naa jade lori ayelujara tan lo kede pe awọn alaṣẹ NYSC ipinlẹ Eko n dunkoko mọ oun ati pe wọn paṣẹ fun oun pe ki oun lọ yọ fidio naa kuro loju opo oun.
O ni "Ẹyin ọmọ Naijiria, ajọ NYSC ti n dunkoko mọ mi pe ki n má mẹnuba ọrọ naa mọ, laarin wakati mẹrinlelogun pere, ijọba ti n halẹ mọ mi bẹrẹ lati ọdọ awọn alaṣẹ NYSC.
"Ẹyin ọmọ Naijiria, wọn mọ orukọ mi o, wọn si mọ ibi ti mo n gbe, ẹ jọọ ti ẹ ko ba gburo mi mọ, ẹ mọ awọn ti ẹ maa di ẹbi ọrọ naa le lori, mi o ṣe ohun ti buru o!"
Agunbanirọ naa fi ohun obinrin kan lede ti obinrin naa si n pariwo mọ lori foonu pe ko lọ yọ fidio naa.
Yatọ si obinrin ọhun, awọn akẹgbẹ rẹ mii tun jabọ fun pe awọn alasẹ NYSC n wa latari fidio to ṣe nitori o lodi si ofin ki agunbanirọ maa sọrọ lodi si ijọba.
Amọ ṣa, ọdọbinrin naa sọ pe ohun ti ajọ NYSC sọ ni pe ki awọn ma darapọ mọ oṣelu, wọn ko sọ pe oun ko lẹtọ lati sọ ohun to n dun oun lọkan.















