Ǹjẹ́ Hamas yóò lè móríbọ́ nínú ogun Gaza?

Awọn ọmọ ogun Al-Qassam, igun Hamas, lọ sibi isinku Olori ogun Hamas, Ghazi Abu Tamaa, loṣu Keji ọdun 2025.

Oríṣun àwòrán, EPA-EFE / REX / Shutterstock

    • Author, Hanan Razek
    • Role, Correspondent, BBC News Arabic
    • Author, Edited by Andrew Webb
    • Role, BBC Global Journalism
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Igbimọ alaabo Israel ti buwọ lu ipinnu Olootu ijọba Benjamin Netanyahu lati gba Gaza. Ṣaaju loun naa si ti kede pe o wu oun lati gba akoso gbogbo Gaza.

Ki ni yoo waa ṣẹlẹ si Hamas, bawo lọjọ iwaju wọn yoo ṣe ri?

Ọjọ diẹ ṣaaju ọrọ Netanyahu ni ikọ ologun Hama tun sọ pe oun ko ni i yee ogun i ja, afi bi orilẹede Palestine ba da duro digbi.

Fun Israel, bi ikọ Hamas ba jawọ nikan lawọn too le gba pe ogun yoo duro.

Nibi ipade agbaye kan ti Saudi Arabia ati France jọ dari ni New York lọsẹ to kọja, orilẹede mẹtadinlogun, igbimọ Europe Union ati Arab, ṣe ikede kan.

Wọn pe Hamas pe ko ṣiwọ ogun, ki wọn si fi idari Gaza silẹ ki ogun le pari.

Egypt ati Qatar ti wọn saba maa n ṣe bii olulaja lori ọrọ Gaza naa fi orukọ wọn si ikede naa. Ṣugbọn Israel ati US ko buwọ luwe naa ni tiwọn.

Awọn eeyan ti ogun ti sọ di alainibugbe ree ti wọn jẹ ọmọ Palestine. Wọn n ja du ounjẹ pẹlu isasun lọwọ. Eyi waye lọjọ kẹrin, oṣu Kẹjọ ọdun 2025 yii ni Gaza.

Oríṣun àwòrán, Mohammed Saber / EPA / Shutterstock

Àkọlé àwòrán, Ebi ọpapanla lo n pa awọn Palestine ni Gaza, wọn n daamu lati ri ounjẹ jẹ lẹyin ikọlu Israel si Gaza, ti wọn ko jẹ ki ounjẹ wọle mọ.

Hamas fẹ́ẹ́ máa bá ogun nìṣó

Olori Hamas kan sọ fun ẹka iroyin Al-Jazeera pe ikọ awọn ko ni i ye ogun i ja, koda awọn ko ni i fi ọta ibọn tawọn ti lo tọrẹ.

Ọrọ rẹ yii tun fidi ẹ mulẹ, pe ikọ ogun Hamas ṣetan lati maa ja lọ, afi ti orilẹede Palestine ba fẹsẹ mulẹ.

Aworan Ghazi Hamad to ba Al Jazeera sọrọ

Oríṣun àwòrán, Amr Alfiky / Reuters

Àkọlé àwòrán, Aworan Ghazi Hamad to ba Al Jazeera sọrọ
Awọn ọmọ ogun Palestine ree ni Gaza, nibi ti wọn ti tẹwọ gba oku awọn ọmọ Isreali mẹrin to wa nigbekun ni Khan Yunis, Guusu Gaza, logunjọ oṣu Keji ọdun 2025.

Oríṣun àwòrán, Haitham Imad / EPA-EFE / REX / Shutterstock

Ìpínlẹ́ Palestine

Orilẹede US, UK ati awọn orilẹede apa Europe mi-in ti ka Hamas si ẹgbẹ agbesunmọmi.

Wọn ni bi Palestine ba da duro bi ipinlẹ kan laaye rẹ, ikọ naa yoo jọwọ nnkan ija rẹ fun awọn alaṣẹ Palestine lọjọ iwaju.

Awọn ọmọ ogun Hamas lasiko ti wọn n fi awọn to wa ni igbekun Israeli silẹ loṣu Keji.

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọ ogun Hamas lasiko ti wọn n fi awọn to wa ni igbekun Israeli silẹ loṣu Keji.

Ṣugbọn awọn awoye sọ pe ikọ yii ko nipa lorii Gaza mọ.

Ṣugbọn ọwọja Hamas ṣi han nibudo ijọba.

Ẹka aabo to ṣẹṣẹ fi lọlẹ to pe ni Sahm, tawọn eeyan tun mọ si Arrow Unit, ṣi n ṣiṣẹ lati ri i pe awọn kan ko maa ko ọrọ̀ ilu sapo ara wọn.

Ṣugbọn inu awọn araalu Palestine ko dun si Hamas, awọn to si n koro oju si ifẹhonuhan naa ti dide.

Iranlọwọ ounjẹ ti ṣoro lati ri gba, bẹẹ ni awọn ajọ alaanu ati ajọ UN n pariwo pe awọn eeyan ti n ku iku ebi.

Ebi o daa lara. Ìyàn alagbara balẹ saarin ilu.Ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Keje ọdun 2025 leyi, nigba ti awọn Palestine n fi omije gba ounjẹ pẹlu idaamu nla.

Oríṣun àwòrán, Khamis Al-Rifi / Reuters

Àkọlé àwòrán, Ebi o daa lara. Ìyàn alagbara balẹ saarin ilu.Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keje ọdun 2025 leyi, nigba ti awọn Palestine n fi omije gba ounjẹ pẹlu idaamu nla.

Loju ọpọ awọn awoye iṣẹlẹ, igbagbọ wọn ni pe nnkan ti de oju ẹ fun awọn ọmọ ogun Hamas. Ati pe wọn ko le ronu pe ohun ti yoo le to bayii ni, nigba ti wọn bẹrẹ ikọlu loṣu Kẹwaa.

O ti rẹ awọn ọmọ ogun Hamas lẹyin oṣu mejilelogun ti ikọ ologun Israel bẹrẹ si i da wọn lohun pada.

Awọn ọmọ ogun Hamas lati ikọ Izz ad-Din al-Qassam , ni Khan Yunis, Guusu Gaza, lọjọ kẹẹdogun oṣu Keji, ọdun 2025.

Oríṣun àwòrán, EPA

Bi iroyin abẹle ṣe wi, awọn ọmọ ogun yii ṣi ni nnkan ija, o kan jẹ pe o ti dinku ni.

Wọn ni awọn nnkan ija to ṣẹku ninu awọn eyi ti Israel ju sọdọ wọn ni wọn n sọ di tuntun pada. Paapaa julọ, awọ ado oloro ti wọn ju ti ko yin nigba yẹn.

Awọn to n ja yii yoo lọọ mu iru ẹ, oun ni wọn n lo lati koju awọn ṣọja Israeli.

Ọpọ ile ati ileeṣẹ lo ti di ilẹẹlẹ ni Gaza, latari awọn ado oloro Israeli.

Oríṣun àwòrán, Mohammed Saber / EPA-EFE / REX / Shutterstock

Àkọlé àwòrán, Ọpọ ile ati ileeṣẹ lo ti di ilẹẹlẹ ni Gaza, latari awọn ado oloro Israeli.

Israel ko jẹ ki ikọ iroyin BBC wọle si Gaza, idi niyẹn ti a ko fi le da fidi eyi mulẹ.

Ni awọn agbegbe ẹlẹkun-jẹkun, ọrẹ diẹ ni ikọ ologun Hamas ni. Lẹyin ọjọ mejila ti Israel ati Iran fi jagun, Tehran ti yọwọ iranwọ rẹ kuro lara Hamas.

Bakan naa ni awọn Hezbollah to tan mọ Iran ni Lebanon naa ko fi bẹẹ ni agbara mọ, latari ikọlu Israel ati bi wọn ṣe pa olori wọn.

Hezbollah ti n koju wahala lati ọdọ ijọba Lebanon, wọn ni ki wọn tu ikọ ologun wọn ka, ki wọn si ma ni anfaani pupọ lati ṣeranwọ sita mọ.

Akọwe ijọba Gẹẹsi lori ọrọ ilẹ okeere, David Lammy, di mọ Olootu ijọba Palestine Mohammad Mustafa, nibi ipade iṣọkan agbaye to waye lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Keje, 2025.

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Akọwe ijọba Gẹẹsi lori ọrọ ilẹ okeere, David Lammy, di mọ Olootu ijọba Palestine Mohammad Mustafa, nibi ipade iṣọkan agbaye to waye lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Keje, 2025.

Igbimọ Arab

Igbimọ Arab ti a mọ si Arab League, kọwọ bọwe adehun to kede pe ki Hamas sinmi ogun, ni New York

Orilẹede mejilelogun lo jẹ ọmọ ẹgbẹ yii, titi kan awọn ti wọn maa n saba ṣe ọrẹ Hamas, awọn bii Qatar.

Ọjọgbọn Yossi Mekelberg, ọga agba nibi ijirororo ni Chatham House, gbagbọ pe Israel ati US ti n gba ipo wọn.

Ṣugbọn o ni ọwọ ti awọn Arab naa gbe ti yatọ. O ni bi awọn Arab naa ṣe n fin Hamas lape le sọ Hamas di ẹni to da wa lai lẹnikan .

Nibi isinku awọn Palestine ti Israeli pa ni Gaza lọjọ keje, oṣu Kẹjọ 2025.

Oríṣun àwòrán, Dawoud Abu Alkas / Reuters

Àkọlé àwòrán, Ileeṣẹ eto ilera Gaza sọ pe eeyan to le lẹgbẹrun lọna ọgọta lo ti ku ninu ikọlu Israeli .

Ìgbèkùn

Hamas si ko awọn ọmọ Israeli ti wọn ko sigbekun lọjọ keje, oṣu Kẹwaa ọdun 2023 sibẹ, wọn ko yọnda wọn.

Eeyan 251 ni wọn ko si igbekun nibi ikọlu to pa eeyan to to 1,200, ẹgbẹrun kan ati igba.

Ninu ogun to n lọ lọwọ naa, o ti le ni eeyan ẹgbẹrun lọna ọgọta ( 60,000) ti wọn ti pa latari ikọlu Israeli si Gaza, gẹgẹ bi ẹka ilera Hamas ṣe sọ.

Igbagbọ US ni pe o kere tan, ogun eeyan (20) ṣi wa ni ahamọ ni Gaza, ati pe wọn ṣi wa laye lẹyin ti awọn kan ti ku ti wọn si ti da awọn kan pada si Israeli.

Hamas fi fidio Evatar David ti wọn mu sigbekun han nibẹrẹ oṣu Kẹjọ yii, nibi to ti ru hangogo to si han pe o ti rẹ ẹ.

Awọn awoye sọ pe ero Hamas ni pe fidio naa yoo mu ki awọn ẹbi ti eeyan wọn wa nigbekun tun fungun mọ Olootu ijọba Israeli,Benjamin Netanyahu, lati jẹ ki ogun pari.

Lẹyin fidio naa, awọn ẹbi naa rọ Netanyahu lati jẹ ki ọrọ awọn to wa nigbekun naa mumu laya rẹ.

Awọn olori Hamas ti wọn ti pa lati ọjọ keje, oṣu Kẹwaa ọdun 2023

Lati oṣu Kẹwaa ọdun 2023, Israel ti pa awọn olori Hamas, titi kan olori wọn pata, Ismail Haniyeh. Ninu ikọlu kan ni wọn ti pa a ni olu ilu Iran.

Israel tun ti pa Yehya Sinwar, ẹni ti igbagbọ wa pe oun lo ṣigun ọjọ keje oṣu Kẹwaa naa.

Gẹgẹ bi Meckelberg ṣe wi, awọn olori Hamas ninu Gaza, ni ero mi-in to yatọ si tawọn to wa nita.

"Yatọ si pe wọn fẹẹ wa laaye, wọn tun n gbiyanju lati lẹnu ninu oṣelu." Meckelberg lo sọ bẹẹ.

Ṣugbọn fun ikọ yii lati ma di igbagbe, awọn olori rẹ to ku gbọdọ ṣe ipinnu to le gan-an.

Bẹẹ lo si jẹ pe latigba ti Netanyahu ti kede l'Ọjọbọ, ọjọ keje, oṣu Kẹjọ ọdun 2025 pe oun fẹẹ gba Gaza koun si le awọn Hamas danu, latigba naa ni ọna ko ti fi bẹẹ si mọ fun Hamas bi ojumọ ṣe n mọ.

Olootu ijọba Israeli, Benjamin Netanyahu

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Olootu ijọba Israeli, Benjamin Netanyahu

Ọjọ́ iwájú Hamas

Too, ṣe Hamas le ye ogun Gaza yii?

Bi wọn ba da orilẹede Palestine silẹ, ti Hamas si ri ohun to n fẹ, wọn yoo sinmi ogun.

Ṣugbọn idasilẹ Palestine ko jọ eyi to dẹrun, afi ti ijọba Israeli to wa lode lọwọ yii

ba yi ero ọkan rẹ pada.

Koda bi iyẹn ba ṣẹlẹ, ko tumọ si pe Hamas yoo di nnkan igbagbe.

Yossie Mekelberg lati Chatham House,ni oun foju sun pe o ṣee ṣe ki Hamas lọọ tunramu, ki wọn si wa ninu itan oṣelu Palestinian.

Eyi le dide lati inu tabi ita Palestinian .

Pupọ ohun ti yoo ṣẹlẹ, wa lọwọ ipinnu ti Israeli ba ṣe nipa idasilẹ orilẹede Palestine, ati bi Hamas ba ṣe gbajumọ to lẹyin akoko inira nla ti awọn eeyan Gaza n la kọja bayii..

Aworan awọn ile ti wọn ti sọ di ilẹẹlẹ ree ni Gaza, ti a ri lati apa ọdọ awọn Israeli nibi ẹnu ibode.

Oríṣun àwòrán, Amir Cohen / Reuters

Àkọlé àwòrán, Aworan awọn ile ti wọn ti sọ di ilẹẹlẹ ree ni Gaza, ti a ri lati apa ọdọ awọn Israeli nibi ẹnu ibode.