Ayédèrú bèbí Labubu gbòde, bí o ṣe lè dá a mọ̀ rèé

Àkọlé fídíò, Ayédèrú bèbí Labubu gbòde, bí o ṣe lè dá a mọ̀ rèé
Ayédèrú bèbí Labubu gbòde, bí o ṣe lè dá a mọ̀ rèé

Ere ọmọlangidi igbalode ti ọpọ mọ si Labubu jẹ ọkan lara awọn ohun iṣere ọmọde to n gbajumọ julọ lagbaye lasiko yii.

Amọṣa awọn iroyin to n jade n sọ pe iwadii ti n fidi rẹ mulẹ pe ayederu ere ọmọlangidi yii lo tu lu ọja pa.

Ọpọ awọn eeyan ni wọn maa n to fun ọpọlọpọ wakati ki wọn le ri iṣere ọmọde naa ra.

Ileeṣẹ to n ṣe nnkan iṣere ọmọde Pop Mart lorilẹede China lo ṣe ọmọlangidi igbalode Labubu.

Ọpọ awọn ayederu to jade bayii gan ni ohun elo ti wọn fi ṣe e ko kun oju iwọ, ti awọn kan ti lẹ n da pe ni 'Lafufus', oniruru ewu lo si so rọ mọ ọ.