Wo àwọn olówó mẹ́rin tí wọ́n ní ìdajì owó ilẹ̀ Africa lọ́wọ́

Aliko Dangote, Johann Rupert,Nicky Oppenheimer ati Nassef Sawiris, awọn olowo nla ilẹ Africa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aliko Dangote, Johann Rupert,Nicky Oppenheimer ati Nassef Sawiris
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Kunkuṣi, owo la fi n ṣe ile aye. Ko sẹni ti yoo sọ pe ti owo bawo.

Nilẹ Africa lonii, awọn eeyan mẹrin kan wa ti aye mọ wọn si olowo nla, koda, idaji ninu ọrọ to wa ni gbogbo Africa ni akọsilẹ sọ pe awọn nikan da ni.

Owo to n bẹ lọwọ awọn mẹrin yii bi awọn oluyẹwo ṣe wo o, to $57.4 billion.

Eyi pọ ju 750 million owo idaji eeyan to wa ni gbogbo Africa lọ

O le ya awọn eeyan mi-in lẹnu pe o ri bẹẹ, ṣugbọn bo ṣe ri gan-an niyẹn, gẹgẹ bo ṣe wa ninu abajade kan ti charity Oxfam gbe jade ninu oṣu Keje ọdun 2025.

Igbagbọ awọn kan lori owo tabua ti eeyan mẹrin ni, to pọju ti miliọnu rẹpẹtẹ eeyan lọ yii, ni pe awọn ilana to n jẹ ki olowo maa lowo si i, to n jẹ ki talaka maa kuṣẹ si i lo fa a ti awọn mẹrin fi là bi eyi.

Ti ẹgbẹlẹgbẹ eeyan si wa ni ipo alaini nilẹ Africa kan naa.

Ṣugbọn ta a ni awọn olowo aye mẹrin yii ti owo wọn ti kuro ni miliọnu, to ti di billion?Bawo ni wọn ṣe ko ọrọ naa jọ?

Aliko Dangote

Aliko Dangote

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aliko Dangote
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aliko Dangote, ọmọ Naijiria ($23.3 billion)

Ẹni akọkọ ninu awọn olowo nla yii ni Aliko Dangote.

Oniṣowo ọmọ Naijiria naa ni wọn bi lọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin ọdun 1957, nipinlẹ Kano.

Aliko Dangote ni oludasilẹ ileeṣẹ Dangote Group, oun si lo ni owo ju ni gbogbo ilẹ Africa.

Awọn okowo bii simẹnti, iyọ, fulawa, ajilẹ, epo rọbi ati afẹfẹ idana ni awọn eeyan mọ Aliko Dangote fun pe o n ṣe, to si n ta.

Latilẹ, idile olowo lo ti wa, ọla to ba nile naa lo ṣiṣẹ kun to fi di olowo, ti okowo naa si ti di ti ẹbi wọn.

Ilu Eko ni Dangote ti bẹrẹ okowo rẹ, ni 1977, nigba to wa ni ẹni ogun ọdun.

Aliko Dangote bẹrẹ okowo naa lẹyin to ya owo lọwọ ẹgbọn rẹ.

O bẹrẹ si i ko irẹsi, ṣuga ati simẹnti wọ Naijiria lati oke okun, o si n ta a lorilẹede yii.

Ko pẹ ti okowo naa fi gberu daadaa latari ajọṣepọ rere to ni pẹlu awọn onibaara, ati òye okowo ṣiṣe to ni pẹlu.

Laaarin 1990 si 2000, Dangote pinnu lati bẹrẹ okowo abẹle, ti ko kan oke okun.

Nigba naa lo da ileeṣẹ ṣuga, iyọ ati fulawa silẹ.

Ileeṣẹ simẹnti rẹ si di akọkọ ni ẹkun Africa.

Lati 2010 ni Dangote ti gba ọna mi-in, nipa yiyi si owo epo rọbi.

Ibudo ifọpo rẹ ni Naijiria bayii jẹ ọkan ninu awọn to tobi ju lagbaaye.

Johann Rupert, South Africa ($14.2 billion)

Johann Rupert

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Johann Rupert

Olowo nla ọmọ ilẹ Africa keji ni Johann Rupert.

Oṣu Kẹfa ọdun 1950 ni wọn bi i ni Stellenbosch, lorilẹede South Africa.

Johann ni alaga ileeṣẹ Richemont Group, ọkan lara awọn ileeṣẹ to lowo julọ lagbaaye.

Baba rẹ, Anton Rupert, naa jẹ oniṣowo nla ni South Africa, oun lo da ileeṣẹ Remgro silẹ.

Sìgá ni wọn kọkọ n ṣe nileeṣẹ naa ki wọn too yi ọna iṣẹ wọn pada.

Johann naa jogun lara ileeṣẹ baba rẹ yii, o si ṣiṣẹ kun un to fi gbooro daadaa.

Ọdun1988 ni Johann Rupert da ileeṣẹ Richemont Group silẹ ni Switzerland.

Awọn nnkan ọṣọ ara to lorukọ daadaa ni wọn n ṣe nibẹ, bii aago, ẹgba ọrun, ọwọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn orukọ ti wọn mọ wọn fun ni Cartier, Van Cleef & Arpels, Montblanc, Piaget, IWC ati Vacheron Constantin.

Gẹgẹ bi akọsilẹ iwe atigbadegba Forbes ti ọdun 2025 ṣe wi, Johann Rupert jẹ ọkan lara awọn olowo ilẹ Africa, owo rẹ bayii sunmọ $15 billion.

Johann Rubert ti figba kan gba ipo ẹni to lowo julọ ni Africa mọ Aliko Dangote lọwọ ri.

Nicky Oppenheimer, South Africa ($10.2 billion)

Nicky Oppenheimer

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Nicky Oppenheimer

Olowo gidi ni Nicky Oppenheimer.

Ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa ọdun 1945 ni wọn bi i ni South Africa.

Ọkan lara awọn gbajumọ oniṣowo goolu tita ni.

Nibi okowo goolu naa ni idile rẹ ti di olowo, ileeṣẹ wọn ni De Beers, to gbajumọ pupọ fun wiwakusa goolu.

Ni 2012, o ta ipin idokowo rẹ to jẹ ida ogoji ninu okowo idile naa, ileeṣẹ ilẹ America kan lo ta a fun un ni $5.1 billion.

Pẹlu bo ṣe fẹyinti ni De Beers, Oppenheimer ṣi jẹ oniṣowo nla titi di asiko yii.

Bakan naa lo si n mojuto okowo idile naa ko ma baa parun. Wọn ti mu iṣẹ ọgbin, irinajo afẹ ati awọn nnkan mi-in mọ ọn pẹlu.

Nassef Sawiris, Egypt ($9.4 billion)

Nassef Sawiris

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Nassef Sawiris

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kin-in-ni ọdun 1961 ni wọn bi Nassef Sawiris, ọmọ ilẹ Egypt ni oniṣowo nla naa, o si jẹ ọkan ninu awọn to lowo ju nilẹẹ Larubawa.

Nassef ni ọmọkunrin abigbẹyin fun Onsi Sawiris, ẹni to da ileeṣẹ Orascom silẹ.

Awọn yoku ninu ẹbi rẹ ni Naguib Sawiris ati Samih Sawiris.

Ileeṣẹ wọn, OCI, ti wọn n pe ni Orascom tẹlẹ, gbajumọ fun ipese ajilẹ ati awọn oogun, bẹẹ ni wọn n pese awọn nnkan eelo pẹlu.

Ni 2023, OCI gbe ẹka ileeṣẹ ajilẹ rẹ gunke pẹlu bo ṣe darapọ mọ ADNOC ni Middle East ati Ariwa Africa .

Nassef Sawiris lo ni ipin idokowo to pọ ju nileeṣẹ Adidas AG to n ṣe nnkan eelo awọn agbabọọlu ni Germany.

Awọn eeyan mọ ọn si ẹni to lowo julọ ni Egypt, ati ọkan lara awọn olowo Africa ati ilẹ Arab lapapọ.

Apapọ owo rẹ to biliọnu mẹjọ si mẹsan-an owo dọla ni 2024/2025.

Nipaṣẹ ileeṣẹ OCI/ADNOC Fertiglobe ati Adidas AG lo ti n ri owo rẹ ju.

Nassef Sawiris fun University of Chicago ni $20 million, (ibẹ lo ti kawe), lati ran awọn akẹkọọ to ku diẹ kaa to fun lọwọ.