Ẹlẹ́jọ́ ti mọ ẹjọ́ rẹ̀ l'ẹbi! Wasiu Ayinde tọrọ àforíjì lórí ìwà tó hù ní pápákọ̀ òfurufú

Oríṣun àwòrán, Others
Olorin Fuji, Alaaji Wasiu Ayinde, ti tọrọ aforiji lẹyin iṣẹlẹ ọkọ baaluu to di lọna lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii, eyi to jẹ ki iroyin nipa rẹ ṣi maa ja ran-in lori ayelujara.
Ẹ o ranti pe Wasiu duro niwaju ọkọ baaluu Valuejet to fẹẹ gbera lati Abuja lọ si Eko lojọ naa, o ni ọkọ naa ko ni i fo bi wọn ko ba jẹ koun gbe ife imumi oun rin irinajo.
Awọn alaṣẹ baaluu naa sọ pe ọti ni Wasiu rọ sinu nnkan imumi rẹ to gbe dani, ofin ko si faaye gba a iru ẹ.
Eyi lo di wahala, ti wọn ni Wasiu to tun jẹ Mayegun ilẹ Yoruba da ọti ọhun si awọn awakọ baaluu naa lara.
Iyẹn nikan kọ, fidio tun ṣafihan bi Wasiu ṣe duro niwaju baaluu naa lati ma le fo, ṣugbọn awakọ ko wo oju rẹ, ọwọ kan lo ṣina sọkọ to si bẹrẹ si i gbe baaluu naa fo.
Nigba naa ni Wasiu si too mu ere kuro niwaju ọkọ ofurufu naa, ko ma ba a pa a.
''Mo kábàámọ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n ọtí kọ́ ni mo rọ sí ife ìmumi mi''
Lẹyin ti iṣẹlẹ yii ti kari ayelujara, ti ajọ to n ri si irinna ofurufu ni Naijiria si ti fi ofin de olorin Fuji yii pe ko gbọdọ wọ baaluu fun oṣu mẹfa lo gbe igbesẹ aforiji.
Atẹjade ni Wasiu fi sita to fi tọrọ aforiji lọwọ gbogbo awọn ti ọrọ naa kan, bẹẹ lo ni oun kabaamọ rẹ.
Bakan naa lo ni omi lo wa ninu ife imumi toun gbe dani, ọti kọ.
" Ọpọ eeyan ni ko mọ pe ara mi maa n gbẹ gan-an, dokita mi si ti gba mi nimọran lati maa mu omi deede.
"Eyi lo fa a ti mo fi maa n gbe nnkan imumi dani nigba gbogbo.
"Fun awọn ti wọn n sọ ohun ti ko ṣẹlẹ, omi ni mo gbe dani lọjọ yẹn, ọti kọ bi wọn ṣe n gbe irọ kiri.
" Gẹgẹ bi ẹri, ayẹwo awọn ẹṣọ papakọ naa meji ni mo ti la kọja nigba ti ko si nnkan kan ninu ife imumi mi.
"Igba ti mo de abala ibi ti won ti maa n naju ni papakọ naa ni mo rọ omi si i.
"Wọn le fi ẹrọ to n ka aworan silẹ nibẹ wadi eyi. Mi o si ti i wọ baaluu naa, ka ma ti i ṣọ pe wọn wa ja mi bọ silẹ ninu ẹ.
"Ṣugbọn mo gba ẹbi mi ninu ọrọ naa, mo si kabaamọ ohun to ṣẹlẹ. Ko wu mi lati tapa si ofin irin ajo nibi kankan. "
Bẹẹ ni apa kan atẹjade ti Wasiu buwọlu naa wi.
Àwọn tó tọrọ àforíjì lọ́wọ́ wọn ni:
Ileeṣẹ Aarẹ, ileeṣẹ to n ri si irinajo ofurufu,Minisita ileeṣẹ naa,awọn awakọ baaluu naa, FAAN, NCAA, Valuejet lapapọ, gbogbo ọmọ Naijiiria ati awon ololufẹ rẹ pata nile loko ati lẹyin odi.
Wasiu Ayinde sọ pe ọmọluabi to n tẹle ofin loun, o ni oun ko ni i huwa ti yoo ba orukọ toun ti ni lati aadọta ọdun sẹyin jẹ.
Oluaye Fuji sọ pe oun yoo maa gbe Naijiria ga pẹlu iṣẹ́ ati ìṣe oun kaakiri agbaye ni.

Oríṣun àwòrán, King Wasiu Ayinde Marshal/Instagram
Ganu sí i àti àwọn ìgbà mìí tí ayé ti pòkìkí Wasiu Ayinde lórí ayélujára
Oduu ti kii ṣe aimọ fun oloko ni Wasiu Ayinde Marshall, ti ọpọ tun mọ si Kwam 1 tabi K1.
Gbajumọ ti ko ribi fi ara pamọ si ni K1, ko si fẹ ẹ nkankan to ṣẹlẹ ti aye kii gbọ nipa rẹ.
BBC ṣe akojọpọ awọn iṣẹlẹ to ti waye ṣaaju pẹlu K1, to jẹ ki ọpọ gbọ nipa rẹ lori ayelujara.
Ganu si i: Iṣẹlẹ pẹlu awọn Alfa lasiko eto isinku iya rẹ
Ni ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kini ọdun 2025 ni iya Wasiu Ayinde, Alhaja Halimah Anifowoshe jade laye lẹni ọdun marunlelọgọrun-un, ti wọn si ṣe adura Fidau fun iya naa lọjọ kẹrinlelogun oṣu Kini bakan naa.
Ṣaaju eto ayẹyẹ Fidau ọhun ni fidio kan nipa Wasiu gba ori ayelujara to si n fa awuyewuye paapaa laaarin awọn Alaafa.
Ohun to ṣẹlẹ ni pe K1 ninu fidio naa nibi to ti n ba eeyan kan sọrọ pe gbogbo awọn Alfa wa jokoo si ile oun lati igba ti iya oun ti ku dipo ki wọn lọ si ile baba oun.
O ni "awọn Alfa wọn o ribẹ, ile baba mi ni Fidipote, awọn Alfa o lọ sibẹ, ibi ni gbogbo wọn wa ṣe kini, ni wọn wa ganu si.
'Ganu si' ti Wasiu Ayinde sọ yii bi ọpọlọpọ awọn Alfa ninu, ti wọn si ni o sọ ọrọ to tabuku awọn.
Ọpọ eeyan lo tu ọrọ naa si pe niṣe ni Wasiu Ayinde n pe awọn Alfa ni elebi ati pe nitori ijẹkujẹ ni wọn ṣe n lọ si ile rẹ lati igba ti iya rẹ ti ku.
Ọrọ ti K1 ba Aarẹ Tinubu sọ lẹyin ti iya rẹ ku

Oríṣun àwòrán, Others
Kete ti Iya Wasiu Ayinde ku ni fọnran kan lu sita lori ayelujara eyi to ṣafihan asiko ti Aarẹ Bola Tinubu pe Wasiu Ayinde K1 lori iṣẹlẹ iku iya rẹ
Bi K1 ṣe ba Aarẹ sọrọ lori fọnran to lu sita lori ayelujara ni ko dun mọ ọpọ ninu, ti wọn si bu ẹnu atẹ luu K1 lori ayelujara.
"Ko si apọnle kankan lati ọdọ K1 si Asiwaju. Se ki n se ọmọ Yoruba ni? Bawo ni yoo ṣe ma lo 'Iwọ' fun Aarẹ? "
Eyi ni diẹ lara ibeere ti ọpọ beere lori ayelujara nitori fidio naa.
K1 gba gbajumọ agbohunsafẹfẹ kan leti loju agbo.
Ni ọdun 2020, ẹgbẹ awọn oniroyin aladani, FIBAN kede pe awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ko gbọdọ lo orin Wasiu Ayinde kankan mọ lori eto wọn.
Aarẹ ẹgbẹ FIBAN nigba naa, Desmond Nwachukwu lo fi lede ninu atẹjade kan lati fesi si iṣẹlẹ to ṣẹlẹ laarin Wasiu Ayinde ati oniroyin Wole Sorunke ti wọn n pe ni MC Murphy.
Nwachukwu ni iṣẹlẹ naa ko dun mọ awọn ninu nitori pe ki i ṣe igba akọkọ ni yii ti Kwam 1 yoo ma hu iru iwa bayii ni igba de igba.
Nigba ti BBC Yoruba gbọ ọrọ yii, a kan si Murphy, to si fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni ọmọ isẹ gbajumọ olorin Fuji , Wasiu Ayinde, to pe orukọ rẹ ni KC gba oun leti, ti Wasiu Ayinde funra rẹ gan si fi bata tẹ oun ni ori ati ẹnu mọlẹ.
O fikun pe, lẹyin to tẹ oun lori ati ẹnu tan, ni Wasiu to wa sẹsẹ tun n gbe oun lori dide, eyi ti ko bojumu rara.
"Mo kọkọ n wo pe se ẹgbọn n ba aburo rẹ wi ni abi ibo ni mo ti se asise? Abi nnkan kan sẹlẹ ti Alhaji ko ri ni, abi nnkan ti ko yẹ ki wọn sọ fun wọn ni wọn gbọ ni, ko tiẹ ye mi."
Iroyin pe K1 n fẹ iyawo Alaafin ana

Oríṣun àwòrán, Others
Bakan naa ni ọdun 2020, iroyin kan gbode lori ayelujare pe Wasiu Ayinde n fẹ ọkan lara iyawo Alaafin ana to waja, Oba Lamidi Adeyemi.
K1 sọrọ lori ẹsun naa loju opo Instagram rẹ lọdun naa pẹlu agba akọroyin, Dele Momodu, o ṣalaye pe, irọ lasan ni wọn pa mọ oun.
Wasiu Ayinde ni, ikorira pe oun jẹ Mayegun ilẹ Yoruba lo mu ki wọn pa irọ mọ oun, o ni lero awọn eeyan naa, oye ọhun ko tọ si oun.
Oye Mayegun jijẹ niluu Oyo

Oríṣun àwòrán, Others
Lasiko Alaafin to waja, Oba Lamidi Adeyemi fi K1 jẹ Oye Mayegun ilẹ Yoruba, oye ti ọpọ eekan ni ilẹ Yoruba ni ko tọ si rara.
Ọpọlọpọ ariyanjiyan lo tẹle yiyan ti Alaafin yan Maiyegun tuntun, pẹlu alaye pe Wasiu ti ọpọ mọ si KWAM 1 ko ni dọbalẹ f'awọn ọba kan mọ lati igba naa lọ.
Alaafin Adeyemi ni Wasiu gan an lo beere fun oye Mayegun ni bi ọdun mọkanla sẹyin nigba to kan si oun laafin pẹlu awọn ọrẹ rẹ.
Alaafin ni oun kọkọ kọ eti ikun si ọrọ naa, lẹyin igba yii l'oun ṣe iwadii lẹmi ati lara ki oun to gba lati fi Wasiu jẹ oye naa.















