Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa irúgbìn GMO àti òtítọ̀ nípa àwọn àhesọ tó n lọ nípa rẹ̀

Oríṣun àwòrán, James Nielsen/Houston Chronicle via Getty Images
- Author, Olaronke Alo & Chiamaka Enendu
- Role, BBC Global Disinformation Unit
- Author, Busayo James-Olufade
- Role, Additional Reporting and Translation
- Reporting from, BBC Yoruba, Lagos
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8
Itakurọsọ lori awọn ounjẹ ti wọn ti paarọ iṣẹda wọn ni Naijiria, ti n tan kaakiri ori ayelujara, lẹyin ti oluponlogo ilera kan, ṣe fidio kan to tan kiri ori ayelujara.
Fidio naa ti Dokita Chinonso Egemba, onimọ isẹgun oyinbo, fi sita, lo ti ṣalaye nipa imọ sayẹnsi to wa nidii awọn ounjẹ ọhun ti wọn n pe ni Genetically Modified Organisms (GMOs)
Oriṣiriṣi ariyanjiyan lo tẹle fidio naa, ti ọpọ si n sọ oriṣiriṣi ewu to wa fun ilera ẹda lati ara ounjẹ GMO.
Dokita Egemba sọ fun BBC pe, awọn ahesọ ọrọ to ti wa nilẹ tipẹ ni oun gbagbọ pe o fa bi awọn eeyan ṣe n bu oun nitori fidio naa.
Awọn kan fi ẹsun kan an pe, o ti gba owo iṣẹ lati polongo ounjẹ GMO tabi ko jẹ pe o n ṣiṣẹ fun awọn orilẹede ilẹ okeere paapaa Bill Gates, to jẹ ọkan pataki lara awọn to n polongo GMO.
Ki ni awọn irugbin GMO?
Ounjẹ GMO ni igbesẹ ti tun awọn irugbin da a lọna to yatọ si bi Ọlọrun ṣe da wọn.
Bi wọn ṣe ma n ṣe e ni pe, wọn yoo mu eroja ti a mọ si 'gene' lati ara irugbin kan, wọn o si fi si ara irugbin mii to yatọ patapata.
Ọgbọn yii ni wọn lo jẹ ọna lati ran awọn agbẹ lọwọ nipa ṣiṣẹda horo irugbin ti kokoro tabi ọda ojo ko le bajẹ.
Awọn onimọ sayẹnsi sọ pe wọn yoo mu irugbin to ni awọn eroja ti wọn n fẹ ninu - bi lile koju ọda ojo - ti wọn o si fi sinu iṣẹda irugbin tuntun.
Awọn ounjẹ GMO to wa ni Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lọdun 2016 ni Naijiria fi ontẹ lu tita irugbin GMO akọkọ - eyi jẹ horo irugbin owu ti wọn pe ni BT Cotton.
Lẹyin rẹ ni wọn tun buwọlu ẹwa ti wọn pe ni PBR ati agbado TELA MAize, lẹyin ọdun diẹ.
Alaye ti ijọba ṣe ni pe igbesẹ ọhun yoo dena ọwọngogo ounjẹ. Amọ ni ọja agbaye, ni nnkan bi ọdun 1990 ni GMO ti wa lori igba.
Oludari ajọ National Biosafety Management Agency (NBMA), ajọ to n ṣe amojuto awọn nnkan ọgbin ati ounjẹ imọ ijinlẹ tuntun, Dokita Agnes Asagbra lori eto amohunmaworan kan, ṣe alaye awọn irugbin GMO to ti wa ni Naijiria, ti ijọba si fi ọwọ si.
Awọn irugbin naa ni:
- Owu (BT Cotton)
- Ẹwa (BT cowpea)
- Agbado (Tela maize)
O ṣalaye nipa ti ẹwa pe, o pọn dandan nitori ki wọn le pa awọn kokoro to ma n ba ẹwa jẹ, run.
Bakan naa ni Dokita Asagbra tun sọ pe ọda ojo tabi apọju rẹ kii da koro GMO naa laamu, eyi to fi ṣe pataki lati ni i ni Naijiria.
Yatọ si eyi, Ọga ajọ NBMA ọhun tun sọ pe eyi ko tumọ si pe GMO ko ti i wọ agbo ẹranko ni Naijiria, ṣugbọn kii ṣe ẹran ti wọn n jẹ.
Ninu oṣu Karun un ọdun 2024 ni ikede jade pe awọn ẹfọn GMO ti wọ Naijiria, lati le fi opin si iru ẹfọn to n fa aisan iba.
Wọn tu awọn akọ ẹfọn ọhun ti kii jẹ eeyan, Anopheles stephensi, silẹ lati ni ibalopọ pẹlu awọn abo ẹfọn to ma n pin aisan iba.
Afojusun ijọba ni pe ti wọn ba ti ni ibalopọ pẹlu awọn abo, eroja iku aitọjọ to wa lara awọn akọ naa yoo ran ọmọ ti abo ẹfọn ba bi, eyi ti wọn o fi ni pẹ laye.
Idi ti Naijiria fi n gbin awọn irugbin GMO

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Naijiria fi ọwọ si tita ati jijẹ awọn irugbin GMO bii ẹ̀dà awọn agbado akn ati ẹwa funfun, nitori pe kokoro kii jẹ ẹ, ati lati le dena ọwọn ounjẹ to ma n jẹyọ nitori oju ọjọ ti ko dara to ma n ba ikore jẹ - gẹgẹ bi alaye ti Dokita Yemisi Asagbra, oludari agba fun ajọ National Biosafety Management Agency (NBMA), ṣe fun BBC.
"Wọn n yọ awọn iṣẹda lara awọn irugbin ilẹ, wọn o si fi wọn sinu awọn horo yii ki wọn o le l'agbara tako kokoro ati okun fun ọda ojo."
O ni ajọ naa pa a ni dandan fun awọn ile itaja lati ma a lẹ akọle atọna mọ ounjẹ GMO lara, ki awọn onibaara le mọ nipa nnkan ti wọn fẹ ra.
Awọn ajọ eto ilera bii World Health Organisation (WHO), sọ pe awọn ẹri to wa nilẹ fihan pe ko daju pe awọn ounjẹ GMO le ṣe ijamba fun ilera ati pe "ko ti i si ilera eniyan kankan to dẹnukọlẹ nitori pe o jẹ iru ounjẹ bẹẹ ni awọn orilẹede ti wọn ti fi ontẹ lu u".
Ṣugbọn ṣa, ko si aridaju tabi ẹri to nitumọ nipa imọ ijinl to wa nidii lilo GMO, eyi ti awọn to n sọ ahesọ nipa rẹ n di mu.
Ni Naijiria, lara iroyin to n lọ ni pe ounjẹ GMO n fa aisan jẹjẹrẹ.
Gẹgẹ bi abọ iwadii ti ajọ imọ ijinlẹ Cancer Research UK, gbe sita, ko si ẹri pe jijẹ ounjẹ GMO le fa jẹjẹrẹ.
Ajọ naa sọ lri itakunagbaye rẹ pe: "Lati aimọye ọdun lati n yi iṣẹda awọn nnkan ẹlẹmi pada nipa yiyan irugbin ati ẹranko kan lati fun wa ni nnkan ti a n fẹ. Artificial selection ni wọn n pe eyi, eyi to tumọ si iṣẹda atọwọda.
"Ilana iṣẹda ode oni, iyẹn GMO, kan jẹ ọna to ya lati ṣẹda ni. Awọn onimọ sayẹsni fọwọ si i pe ko sewu ninu jijẹ ounjẹ GMO gẹgẹ bi awọn ti kii ṣe GMO."
Ki ni awọn onimọ sọ nipa GMO ni Naijiria?
Onimọ kan nipa imọ ẹrọ ayika, Yekini Oluwafemi, sọ pe titi di oni, ko ti i si arigbamu imọ sayẹnsi to so irugbin GMO mọ aarun tabi iku eniyan kankan.
"Ọpọ ajọ ilera bii WHO ati Food and Agriculture Organisation (FAO), fẹnuko pe awọn ounjẹ GMO to wa lọja ko lewu rara.
Oludari ajọ NBMA nigba kan, Rufus Ebegba, ṣalaye fun BBC pe ọrọ GMO dabi pe "ki eeyan fẹ mu ki ewuro ni adun, ko wa a ṣawari nnkan to n mu ki ireke ni adun, ko si mu awọn eroja naa sinu ewuro, ki ewuro naa o wa a ni adun".
Bakan naa lo tun fi kun un pe, titi di ọdun 2024, awọn ounjẹ GMO ko ti i wa ni ọja lọpọ yanturu nitori pe o ṣi wa lọwọ awọn agbẹ to fẹ ẹ gbin-in lọpọ yanturu.
Ẹwẹ, onimọ nipa iṣẹda nnkan ọgbin nileeṣẹ African Agricultural Technology Foundation (AATF) , Dokita Bernard Ehirim, sọ fun BBC pe, oun gẹgẹ bi ẹnikan ti n jẹ ẹwa GMO fun igba pipẹ, ti ohunkohun ko si ṣe oun. O ni awọn ounjẹ GMO ti ijọba fọwọsi fun tita l'ọja ma n la ayẹwo kọja lati mọ boya wọn ko lewu fun ilera ẹda.
"Ọdun 2021 ni mo ti n gbin ẹwa GMO si oko mi, gbogbo ara ile mi si lo n jẹ ẹ. Ọdun 2019 ni wọn gbe koro ẹwa naa jade."
Lori ifoya pe awọn koro GMO ko ṣe e gbin lẹmeeji, Dokita Ehirim ṣalaye pe, igba kan ni awọn koro naa ni eroja kan ti wọn n pe ni 'terminator', eyi to tumọ si pe koro kan ko le so irugbin ju ẹẹkan lọ.
Dokita Ehirim sọ pe iru awọn koro GMO yii ko si mọ, nitori iṣẹlẹ kan to waye ni Brazil, eyi to mu ki awọn alamojuto rẹ fi opin si lilo eroja terminator ninu awọn ounjẹ GMO.
"Eroja terminator naa ma n ṣiṣẹ pe ti o ba ti kore irugbin, o ko ni le lo eso rẹ lati gbin irugbin miran - ko ni i dagba.
Lori bi awọn eeyan kan ṣe gbagbọ pe o ma n pa kadara ẹda da, Olukọ kan nipa nnkan ajogunba lara ẹda ni Fasiti ilu Eko, Ọmọwe Olumide Adebesin, sọ pe ninu gbogbo iwadii ijinlẹ ti oun ti ṣe, ko ti i si ẹri pe GMO ma n pa kadara agọ ara da, ti eeyan ba ti jẹ ẹ.
Bakan naa ni Ọjọgbọn Cathie Martin, onimọ nipa igbeaye irugbin lorilẹede United Kingdom, naa sọ pe, ko si nnkan to jọ ọ pe irugbin GMO n di awọn irugbin ti kii ṣe GMO lọwọ lati hu tabi dagba.
"Mi o ri iru rẹ ri gẹgẹ bi agbẹ to n gbin ireke GMO ati eyi ti kii ṣe GMO sori ilẹ kan naa.
Awọn ofin ijọba wo lo de GMO ni Naijiria?
Ajọ NBMA sọ pe, ilana mẹta lo de pipin ati tita awọn ounjẹ GMO ni Naijiria.
Awọn ilana naa si ni orisun wọn ninu ofin ajọ National Biosafety Management Agency, ti ọdun2015, Plants Quarantine Act 2017, ati ofin ileeṣẹ aṣọbode, Customs and Excise Management Act 2004.
Bi awọn kan lara ilana yii ṣe n ṣamojuto lilo imọ ijinlẹ biotechnology (lara eyi ti GMO wa), ni awọn yooku n mojuto kiko koro ati ounjẹ GMO wọle si Naijiria.
Ni awọn orilẹede bii Russia, ofin to l'agbara lo de lilo irugbin GMO, ṣugbọn wọn ko fi ofin de e patapata, tako iroyin to n lọ ni Naijiria.
Ṣe lootọ ni pe Bill Gates fẹ ẹ fi GMO gbakoso eto ọgbin ni Naijiria ni?

Lara awọn itakurọsọ to tun n lọ lori ayelujara nipa irugbin GMO ni pe, awọn ileeṣẹ nla l'agbaye, paapaa Bill Gates, olokowo kan nilẹ America, fẹ gba iṣakoso iṣẹ ọgbin ni Naijiria, lo ṣe n ṣagbatẹru GMO lorilẹede naa.
Ajọ Bill and Melinda Gates Foundation ti n ṣe iranlọwọ ninu iṣẹ iwadii ijinlẹ nipa iṣẹ agbẹ ni Naijiria lati ọjọ pipẹ, to fi mọ atunṣe to ba ọgbin agbado pẹlu irugbin TELA Maize, ti wọn ṣe agbekalẹ rẹ ni Fasiti Ahmadu Bello niluu Zaria.
Kabir Ibrahim, aarẹ ẹgbẹ awọn agbẹ ni Naijiria (AFAN), sọ pe oun ṣe atilẹyin fun awọn koro irugbin ti atunṣe ti de ba, pẹlu afikun pe ayederu iroyin to n jade nipa rẹ ko ṣẹyin aini imọ to o.
Bakan naa lo sọ pe ko si ẹni to n fi ipa mu agbẹ kankan lati gbin irugbin GMO, tako nnkan ti awọn eeyan kan n sọ.
Ẹwẹ, Ọgbẹni Ibrahim ṣalaye pe awọn ileeṣẹ labẹle lo n pin irugbin naa, eyi to tako iroyin pe awọn ileeṣẹ ilẹ okeere nikan lo n pin, to n ta a.
"Koda, awọn agbẹ to n fẹ ẹ ti pọ si."












