Àlàyé rèé lórí bí gbajúmọ̀ oníṣòwò ẹja, Fish Magnet, ṣe bọ́ sọ̀wọ̀ ajínigbé nílé rẹ̀, tí wọn sì rí òkú rẹ̀ lẹ́yìn sísan owó ìdáǹdè

Ologbe Fish Magnet

Oríṣun àwòrán, Fish Magnet

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Fish Magnet ṣaaju iku rẹ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra ti bẹrẹ si n tọpinpin awọn agbebọn to ji ọdọkunrin kan, Ifesinachi Onyekere, gbe nilẹ rẹ ki wọn to gbẹmi rẹ lẹyin ti wọn gba owo itusilẹ rẹ tan.

Oloogbe naa, ti ọpọ mọ si "Fish Magnet" ni a gbọ pe o jẹ ọmọ oloṣelu kan lagbegbe naa ṣaaju iku rẹ.

Ọjọ Abamẹta to kọja ni awọn agbebọn naa ya bo ile rẹ to wa ni Okpuno, ni ijọba ibilẹ guusu Akwa.

"Ọkọ Toyota Corola rẹ ni ajinigbe fi gbe e lẹyin ti wọn yinbọn lu u ni ẹṣẹ tan, ọjọ mẹta lo fi wa lakata wọn, wọn gba owo itusilẹ amọ oku rẹ ni a ri lẹba ọna"

A gbọ pe ibẹrubojo ba ọkan awọn eeyan agbegbe ti ọdọkunrin naa n gbe latari bi awọn agbebọn naa ṣe n yinbọn soke nigba ti wọn wa gbe nile rẹ.

Iroyin ni wọn kọkọ yinbọn fun ni ẹsẹ rẹ ki wọn to gbe lọ.

Iroyin ni awọn ara adugbo sọ pe ọkọ ayẹkẹlẹ Lexus RX 350 ni awọn agbebọn naa gbe lọ sile rẹ, ki wọn to fi tipa tikuuku wọ inu ọgba ile ọhun.

Ẹnikan to n gbe ladugbo naa amọ ti wọn ko fi orukọ ara rẹ lede sọ pe "nnkan bii aago mẹwaa abọ alẹ ni wọn ya bo ile naa.

Wọn gbe ọkunrin naa lọ ninu ọkọ Toyota Corola rẹ lẹyin ti wọn yinbọn lu u ni ẹṣẹ tan.

"Inu igbo to wa loju ọna Nawfia ni wọn gba salọ, bi wọn ṣe n lọ ni wọn n yinbọn soke, eyii to da ibẹru sọkan ọpọ eeyan agbegbe ọhun."

O fi kun pe awọn ọdẹ adugbo atawọn ọlọpaa bẹrẹ iṣẹ lẹyin naa lati ṣawari rẹ amọ oku rẹ ni wọn ri lẹyin naa.

O ni "ọjọ mẹta gbako lo fi wa lakata wọn titi ti wọn fi gba owo itusilẹ rẹ, amọ kaka ki wọn tu silẹ lẹyin ti wọn gba owo naa tan, oku rẹ ni a ri lẹba ọna laarọ oni."

Ọkunrin naa juwe oloogbe ọhun gẹgẹ bii ọdọ to mura siṣẹ rẹ, ti ko si ṣe ọlẹ.

A ti gbe iwadii dide - Ọlọpaa

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Tochukwu Ikenga, ti fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ.

O ni kọmiṣọna ọlọpaa ti da awọn ọtẹlẹmuyẹ si igboro lati ṣawari gbogbo awọn to lọwọ ninu iku ọkunrin naa to jẹ oludasilẹ ileeṣẹ Fish Magnet Outlet.

Ọlọpaa ni "aṣẹ yii lo waye lẹyin ti olọpaa ṣawari ọkọ ayẹkẹlẹ Toyota Corolla rẹ alawọ aro loju ọna Ukwulu/Igbariam.

"Iwadii wa fi han pe awọn kọlọrọsi naa ti kọkọ n tọpinpin rẹ ki wọn to kọlu u nibi ti wọn ti yinbọ lu ẹsẹ rẹ ki wọn to gbe lọ.

"Lẹyin naa ni awọn eeyan ṣawari oku rẹ eyii to ti da ibẹrubojo sọkan awọn eeyan agbegbe Akwa bayii."

Alukoro ọhun ṣeleri pe iwadii kikun yoo waye, gbogbo awọn to lọwọ ninu iwa laabi naa yoo si foju wina ofin.

Aworan Very Dark Man

Oríṣun àwòrán, Verydarkblackman

VDM bu sẹkun lori bi ajinigbe se pa gbajumọ onisowo ẹja, o setan lati se iwadi naa Mo maa lọ si Anambra lori orọ yii, idajọ ododo gbọdọ waye – VDM

Ajafẹtọọmọniyan lori ayelujara, Martins Otse, ti ọpọ mọ si VeryDarkMan ti bu sẹkun lori iṣẹlẹ naa eyii to bu ẹnu atẹ lu.

Ninu fidio kan to ṣe loju opo Facebook rẹ, VDM bu ẹnu atẹ lu ipo ti eto Anambra atawọn ipinlẹ mii wa ni Naijiria.

O ni oun yoo lọ sipinlẹ ọhun lati kopa ninu isin iranti abẹla ti awọn ololufẹ oloogbe naa yoo ṣe fun lọjọ kẹrin, oṣu Kejọ.

Bakan naa lo salaye nipa ajọsepọ ti oun ni pẹlu onisowo ẹja ọhun, ẹni to seleri lati fun oun ni ẹja.

Amọ o ni oun ko tii gba ẹja naa, ki awọn ajinigbe to pa a.