"Ṣe ni wọ́n da gbogbo aláìsàn síta, mo ń sunkún fáwọn Nọ́ọ̀sì láti fún mi ní abẹ́rẹ́ láì rí dókítà"

Àwọn aláìsàn ní ilé ìwòsàn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

"Ọ̀sẹ̀ ọ̀sẹ̀ ni mo ní abẹ́rẹ́ tí mo máa ń gbà nítorí àìlera mi láti ìgbà tí mo ti wà nínú oyún, ṣùgbọ́n àwọn dókítà kọ̀ láti dá mi lóhùn nítorí ìyanṣẹ́lódì tó ń lọ lọ́wọ́.

,

Èyí ni ọ̀rọ̀ tó jáde lẹ́nu aláboyún Mariam Ajisefini tó ń lo ilé ìwòsàn Harvey Road General Hospital, Yaba.

Mariam gbéra láti lọ sí ilé ìwòsàn gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ Ajé láti lọ gba abẹ́rẹ́ tó máa ń gbà láti ìgbà tó ti lóyún.

Oyún àkọ́kọ́ tí Mariam máa ní nìyí, tó sì ń kojú àwọn ìpèníjà kan tàbí òmíràn èyí tó mu kó nílò láti máa gba abẹ́rẹ́ ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko yọ owó kòtọ́ kan nínú owó oṣù keje, ìjọba tún kọ̀ láti san owó oṣù méjìlá tí wọ́n jẹ wá la fi da iṣẹ́ sílẹ̀ - Ẹgbẹ́ Dókìtà Eko

Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kejìdinlọ́gbọ̀n, oṣù Keje ni àwọn dókítà lábẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Eko bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì oníkìlọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́ta.

Àwọn dókítà náà lábẹ́ ẹgbẹ́ Medical Guild ní ọ̀rọ̀ tó dá lórí owó oṣù wọn ni ìyanṣẹ́lódì náà dá lé lórí.

Ẹgbẹ́ náà fẹ̀sùn kan ìjọba ìpínlẹ̀ Eko pé wọ́n yọ àwọn owó kan nínú owó oṣù Keje tí wọ́n san fún àwọn àti pé ìjọba kọ̀ láti san owó oṣù méjìlá tí wọ́n jẹ àwọn lábẹ́ ètò Consolidated Medical Salary Structure (CONMESS).

Àtẹ̀jáde kan tí égbẹ́ náà fi sórí ìkànnì X wọn darí gbogbo àwọn ọmọ wọn láti da iṣẹ́ sílẹ̀, tí wọ́n sì ṣèkìlọ̀ pé dókítà tí kò bá tẹ̀lé ìdarí yìí máa fojú winá òfin.

Ní ilé ìwòsàn olùkọ́ni Lagos State University Teaching Hospital (LASUTH) níṣe ni wọ́n da àwọn aláìsàn tó wà ní wọ́ọ̀dù síta nítorí ìyànṣẹ́lódì náà.

Ṣáájú ni ilé iṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Eko ti fi àtẹ̀jáde kan síta pé àwọn ti gbọ́ nípa ìyanṣẹ́lódì táwọn dókìtà náà gùnlé, tí àwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ lórí rẹ̀.

Iléeṣẹ́ náà ní àwọn mọ pàtàkì àwọn òṣìṣẹ́ ìlera, tí àwọn sì ní ìfarajìn láti parí gbogbo nǹkan tó ń fa aáwọ̀ láàárín àwọn òṣìṣẹ́ náà àti ìjọba.

Wọ́n wá rọ ẹgbẹ́ àwọn dókítà náà láti tẹ̀síwájú ìjíròrò pẹ̀lú ìjọba nítorí àti mú àdínkù bá ìnira tí ìyanṣẹ́lódì náà ń kó bá àwọn èèyàn.

Awọn Nọọsi n sisẹ nile iwosan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

'Àwọn nọ́ọ̀sì ti ń dá wa lóhùn, tí wọ́n ti ń ṣe àyẹ̀wò ìfúnpá àti ara wa nítorí àwọn kò yanṣẹ́ lódì ṣùgbọ́n kò sí dókítà tí a máa rí láti sọ bí ìlera ṣe rí fún wa'

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹlòmíràn tó tún bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀ ni Rukayat Ajishafe, tí òun náà jẹ́ aláboyún tó ń gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn Harvey Road General Hospital, Yaba.

Ajishafe ní òun kò mọ̀ pé àwọn dókítà ń yan iṣẹ́ lódì kí òun tó gbéra kúrò nílé láti lọ sí ilé ìwòsàn.

"Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi nígbà tí mo dé ilé ìwòsàn tí wọ́n ní àwọn dókítà ń yan iṣẹ́ lódì pé wọn kò ní dáwa lóhùn.

"Kódà àwọn nọ́ọ̀sì ti ń dáwa lóhùn, tí wọ́n ti ń ṣe àyẹ̀wò ìfúnpá àti ara wa nítorí àwọn ò yanṣẹ́ lódì ṣùgbọ́n kò sí dókítà tí a máa rí láti sọ bí ìlera ṣe rí fún wọn.

"Kìí ṣe ọjọ́ òní gangan lọ yẹ kí n wá fún àyẹ̀wò àmọ́ ó ní ohun tí mo torí rẹ̀ wá sílé ìwòsàn lónìí. Èyí túmọ̀ sí pé mà á gbé ohun tó ń bámi fínra padà sílé láì rí ìtọ́jú nítorí àìgbọ́raẹniyé tó ń wáyé láàárín àwọn dókítà àti ìjọba.

"Ara ìdí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kìí fẹ́ lo ilé ìwòsàn ìjọba nìyí bẹ́ẹ̀, owó tí àwọn ilé ìwòsàn aládàni máa ń bèèrè kò kéré rárá.

Ajishafe fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn ni wọ́n ti lé jáde nínú wọ́ọ̀dù tí wọ́n wà nítorí ìyanṣẹ́lódì náà.

Ó ní òun rí aláìsàn kan tó jẹ́ pé èémí ìgbàlódé ló ń lò láti fi mí, tí òun sì ń bá a kẹ́dùn pé níbo ló fẹ́ lọ láti lọ tọ́jú ara rẹ̀ báyìí.

Ìyanṣẹ́lódì àwọn dókítà ní Nàìjíríà

Ìyanṣẹ́lódì àwọn dókítà kìí ṣe ohun tuntun ní Nàìjíríà àmọ́ tó jẹ́ pé láàárín ìjọba àpapọ̀ àti àwọn ẹgbẹ́ dókítà ilẹ̀ Nàìjíríà ìyẹn Nigerian Medical Assciation, NMA ló ti sábà máa ń wáyé.

Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni NMA ti fi ìkéde síta pé àwọn máa gùnlé ìyanṣẹ́lódì ní ọ̀sẹ̀ yìí kí wọ́n tó ṣẹ́wẹ́lé èròńgbà náà.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Keje ni NMA ti fún ìjọba àpapọ̀ ní gbèdéke ọjọ́ mọ́kànlélógún láti dáhùn sí gbogbo àwọn ìbéèrè tí wọ́n ń bí wọn tàbí kí àwọn da iṣẹ́ sílẹ̀.

Àmọ́ nígbà tó yá ni akọ̀wé ẹgbẹ́ náà fi ìkéde síta lọ́jọ́ Àìkú pé àwọn ti ṣe ìpàdé pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀, tí àwọn sì ti fún wọn ní gbèdéke ọjọ́ mọ́kànlélógún míì.

Ọ̀rọ̀ owó osù àti ṣíṣe àmúṣẹ àwọn àjẹmọ́nú míì jẹ́ ohun gbòógì tó máa ń ṣokùnfà bí àwọn dọkítà ṣe máa ń lọ fún ìyanṣẹ́lọdì ní gbogbo ìgbà ní Nàìjíríà.