"Sodeke lá àlá pé wọ́n bímọ̀ tó rìn lóòjọ́, Ifá ní ẹ̀sìn àjèjì tí yòó sọ ilẹ̀ Ẹgba di ọ̀làjú ń bọ̀, ló fi gba ẹ̀sìn Krìsítẹ́nì"

Àkọlé fídíò, "Sodeke lá àlá pé wọ́n bímọ̀ tó rìn lóòjọ́, Ifá ní ẹ̀sìn àjèjì tí yòó sọ ilẹ̀ Ẹgba di ọ̀làjú ń bọ̀, ló fi gba ẹ̀sìn Krìsítẹ́nì"
"Sodeke lá àlá pé wọ́n bímọ̀ tó rìn lóòjọ́, Ifá ní ẹ̀sìn àjèjì tí yòó sọ ilẹ̀ Ẹgba di ọ̀làjú ń bọ̀, ló fi gba ẹ̀sìn Krìsítẹ́nì"
    • Author, Adedayo Owolabi
    • Role, SJ
    • Author, Afolabi Akinlabi
    • Role, BJ

Yoruba ni bi ọmọ ko ba ba itan, yoo ba arọba tii se baba itan.

Ni ọpọ igba si ni awọn ọmọbibi ilẹ Ẹgba to wa nilu Abeokuta ati agbegbe rẹ maa n yangan pe ilu naa ni ọlaju ti bẹrẹ.

Awọn Ẹgba maa n ni awọn ni awọn kọkọ gba ẹsin Krisitẹni to mu ọlaju wa saaju awọn ilu yoku nilẹ Yoruba ati ni orilẹede wa Naijiria lapapọ.

Koda, sọọsi akọkọ nilẹ Naijiria ni awọn oyinbo ajihinrere kọ silu Abeokuta eyi to fidi rẹ mulẹ lootọ pe ilu naa ni ẹsin Kirisitẹni ati ọlaju ti bẹrẹ lootọ.

Idi ree ti BBC News Yoruba se morile ilu Abeokuta lati mọ nipa sọọsi akọkọ nilẹ Naijiria ati bi ẹsin Kirisitẹni se wọ ilu naa.

Amọ iyalẹnu nla lo jẹ fun wa pe jagunjagun kan nilu naa, Olubiyi Akinrinlewo Sodeke,to jẹ ẹlẹsin ibilẹ, lo se atọkun bi ẹsin igbagbọ se jẹ itẹwọgba, to si gbinlẹ nibẹ.

Olubiyi Akinrinlewo Sodeke

"Jagunjagun to gbona ni Sodeke, bi o si se tẹ ilẹ Ẹgba do, naa lo gba ẹsin Kirisitẹni laaye nigba ti wọn de"

Ọna lati fi idi okodoro ọrọ yii mulẹ lo mu ki BBC Yoruba lorile agboole Sodeke to wa nilu Abeokuta lati gbọ bi itan itankalẹ Kirisitẹni se lọ nilu naa.

BBC Yoruba bawọn arọmọdọmọ Sodeke meji, Adesina Adisa Sodeke ati Moruf Oloyede Sodeke sọrọ nipa bi ẹsin Krisitẹni se di itẹwọgba nilẹ Ẹgba.

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Moruf Oloyede Sodeke ni baba nla oun naa lo ko awọn Ẹgba wa silu Abeokuta lati wa tẹdo si.

"Ifa ni wọn fi rin lati inu Igbo Ẹgba ti wọn ti n bọ, ti wọn si n beere lọwọ Ifa pe se awọn ti de ibi ti awọn maa tẹdo si.

Wọn rin rin rin de ibi ti wọn fi de oke kan gagara, tii se oke Olumọ ti Ifa ni ki wọn tẹdo si.

Jagunjagun to gbona ni Sodeke, bi o si se tẹ ilẹ Ẹgba do, naa lo gba ẹsin Kirisitẹni laaye nigba ti wọn de."

Aworan Sodeke

"Onifa to rọ ala fun Sodeke sọ pe ẹsin ajeji to n bọ yoo mu ki ilu Ẹgba roju, ko goke, ti wọn yoo si maa mọ awọn ọmọ Ẹgba nibi gbogbo"

Nigba to n salaye bi Olubiyi Akinrinlewo Sodeke se tẹwọgba ẹsin Kirisitẹni, awọn ọmọ rẹ naa ni kawọn oyinbo ajihinrere to de si Abeokuta, ni Sodeke ti mọ pe wọn n bọ.

"Ki awọn oyinbo to mu ẹsin Kiristẹni wọlu, ni Sodeke ti la ala kan.

Ninu ala naa lo ti ri pe wọn bi ọmọde jojolo kan ni oojọ, ti ọmọ naa si rin ni oojọ.

Ọrọ naa toju ru Sodeke loju, to si bi Ifa leere pe ki ni itumọ ala naa.

Babalawo wa sọ fun pe odu to yọ si oun ni Odu Ofun ati Osa, ti wọn n pe ni Ofunsa.

Wọn ki Ifa naa pe wọn n mu ẹsin kan bọ wa, tii se ẹsin alaafia ti yoo mu ọlaju ba ilu.

Onifa naa sọ fun Sodeke pe ẹsin ajeji yii yoo mu ki ilu Ẹgba roju, ko goke, ti wọn yoo si maa mọ awọn ọmọ Ẹgba nibi gbogbo.

Nigba to si jẹ pe ẹni to fẹ alaafia ati idagbasoke ilu rẹ ni Sodeke, lo ba fara mọ asọtẹlẹ Ifa naa."

Arọmọdọmọ Sodeke meji, Adesina Adisa Sodeke ati Moruf Oloyede Sodeke

"Ifa ni ki Sodeke ri asia funfun yika ilẹ Ẹgba, Henry Townsend se ri asia naa, inu rẹ dun, gbogbo awọn to kọkọ ri oyinbo naa n pe ni Iwin, wọn si sa lọ"

Ninu alaye wọn naa, awọn ọmọ Sodeke tẹsiwaju nipa alaye ohun ti Ifa ni ki Sodeke se lọjọ naa, ki ala ọhun le tuba tusẹ.

"Onifa wa sọ fun Sodeke pe ki wọn ta asia funfun si gbogbo igun to wọ ilu Abeokuta.

Asọ funfun yii tumọ si Alaafia ni gbogbo ede.

Bi oyinbo alawọ funfun to mu ẹsin igbagbọ wọ ilẹ Ẹgba, Henry Townsend se ri asia alawọ funfun naa, inu rẹ dun.

Gbogbo awọn eeyan to kọkọ ri oyinbo naa, fi ere ge, wọn sa lọ, wọn n pe ni Iwin tori wọn ko ri oyinbo ri.

Wọn n pariwo pe eyi bo, eyi ko bo, ibi ti oyinbo ti jẹ jade niyẹn.

Bi Henry Townsend si se wọle, ni wọn mu lọ sile Sodeke, ala yẹn si wa si ọkan Sodeke, bo se pe oyinbo naa niyẹ, to si gbe sori ẹsẹ rẹ.

Agboole wa ni Sodeke ati Henry Townsent pẹlu awọn eeyan to tẹle lẹyin ti kọkọ bẹrẹ isin akọkọ.

Lati igba naa si ni ẹsin igbagbọ ti bẹrẹ si ni fidi mulẹ ni ilẹ Ẹgba, to si tan yika gbogbo ilẹ Yoruba ati Naijiria lapapọ"

Oju orori Sodeke