Báwo ni ìwọ́pópó ṣe bẹ̀rẹ̀ lásìkò ọdún Osun Osogbo, kí sì ni ìtúmọ̀ àti pàtàkì rẹ̀?

Ni ọjọ Aje, ọjọ Kejindinlọgbọn, oṣu Keje ni ọdun Osun Osogbo ti 2025 gberasọ ni ilu Osogbo, olu ilu ipinlẹ Osun.
Gẹgẹ bi iṣe ni ọdọọdun, Iwọpopo ni wọn fi bẹrẹ, itumọ sise iwọpopo naa si ni lati to lọwọlọwọ yika ilu.
Awọn eeyan yoo fi asọ to dara si ọdun, ti wn yoo si wu oju ri.
Bakan naa, wọn yoo jo yika oju popo lati pe akiyesi gbogbo si ọdun Osun Osogbo to bẹrẹ naa.
Ọdọọdun si ni Iwọpopo maa n waye nibi ti Kabiyesi, Ataoja ti ilu Osogbo yoo ti fi ọjọ naa ṣe iwure fun aṣeyọri ọdun Osun naa ati fun gbogbo eeyan lapapọ.
Lẹyin eyi ni ọdun Osun Osogbo yoo wa bẹrẹ ni pẹrẹu.
Ọdun Osun Osogbo jẹ ọdun to ṣe pataki ninu awọn ọdun to wa nilẹ Yoruba.
O jẹ ọdun ti ọpọlọpọ eeyan fi maa n tọrọ ohun rere, paapaa julọ, awọn n to woju Ọlọrun fun ọmọ.

Ki ni pataki Iwọpopo ati pe bawo lo ṣe bẹrẹ nibi ayẹyẹ ọdun Osun Osogbo?
Gẹgẹ bi alakalẹ ayẹyẹ ọdun Osun Osogbo, Ataoja ti ilu Osogbo, Ọba Jimoh Olanipekun lo maa n ṣaaju eto Iwọpopo ti yoo si ṣe iwure fun ayẹyẹ ọdun naa ati ilu lapapọ.
Ọba Jimoh Olanipekun ni Iwọpopo jẹ ọjọ iwure fun aṣeyọri ọdun Osun Osogbo ati gbígba adura fun ilu, ipinlẹ ati orile-ede lapapọ.
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Baba Orisa ilu Osogbo, Osunyemi Ifabode, salaye idi ti Iwọpopo ṣe maa n saaju ọdun Osun Osogbo.
O ni Iwọpopo jẹ ọjọ ti Ataoja ti ilu Osogbo yoo fi ẹsẹ rin lati aafin lọ si orita ti wọn n pe ni Popo, ti irin naa si to maili kan ati abọ.
Ifabode tesiwaju pe lasiko ti Kabiyesi ba n lọ ni oju ọna ni yoo maa wure fun ilu, bẹẹ naa si ni awọn eeyan yoo wa si iwaju Kabiyesi lati gba ire lẹ́nu rẹ.
Lẹyin ti Kabiyesi ba de orita Popo ni yoo jokoo si oju opopona pẹlu aga rẹ ti gbogbo awọn oloye ati awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ yoo si maa wa lati fori balẹ fun iwure lẹ́nu Kabiyesi.
Ifabode tun fi kun wi pe Iwọpopo jẹ ohun ti awọn ba laye, to si jẹ ohun to ṣe koko ati pataki ninu ọdun Osun Osogbo.

Bakan naa, Oyelola Elebuibon, tii se Iyalorisa ilu Osogbo sọ pe "Kii ṣe Iwọpopo lo kọkọ bẹrẹ ọdun Osun Osogbo, ọdun Osun Osogbo ti bẹrẹ lati inu osu Kiini ọdun.
Igba naa ni gbogbo awọn olorisa yoo ti maa ṣe ibọri fun orisa wọn ati lati maa jo kaakiri ilu,"
Elebuibon salaye pe nigba iwaṣẹ, ọba kii yọju sita niluu Osogbo afi ọjọ ti wọn ba fẹ ṣe ọdun Iwọpopo.
O ni Iwọpopo jẹ ọjọ pataki, o si tun jẹ ọjọ ti Kabiyesi yoo fi lana fun ayẹyẹ ọdun Osun Osogbo lati wure fun gbogbo olorisa ati fun ilu lapapọ.
O sọ pe gẹgẹ bi igbagbọ awọn eeyan pe aṣẹ wa lẹ́nu Ọba lati fi beere ohun to ba n fẹ fun ilu ati awọn to n gbe inu ilu lapapọ, eyi lo maa n mu ki gbogbo eeyan jade lati wa gba ire saaju ọdun.
Ninu ọrọ tirẹ, Osundara Oyawale, Iya Osun ti ilu Osogbo sọ pe, ọdun Osun Osogbo jẹ ọdun ti gbogbo eeyan maa n bere ohun rere.
O ni ọdun naa tun ọdun ti Arugba yoo ru ibi danu, ti Kabiyesi yoo si wure fun gbogbo ilu ati fun gbogbo eeyan to peju pesẹ sibi ayẹyẹ naa.
Osundara tun fi kun ọrọ rẹ wi pe, ọdun Osun Osogbo yatọ si ọdun asa sugbọn to jẹ ọdun adura ati iwure lati ẹnu Kabiyesi si gbogbo eeyan patapata.
Ọpọlọpọ eeyan lo peju pesẹ sibi eto Iwọpopo to jẹ ibẹrẹ ọdun Osun Osogbo ti 2025
















