Kí ló dé tí àwọn orílẹ́èdè kan kò ka Palestine sí orílẹ̀èdè tó lè dá dúró?

Asia Palestine.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Asia orilẹede Palestine.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

To ba di oṣu Kẹsan-an, orilẹede France yoo gba Palestine gẹgẹ bii orilẹede to le da duro, gẹgẹ bi Aarẹ Emmanuel Macron ṣe kede, eyi yoo si sọ ọ di akọkọ ninu awọn orilẹede G7 to ṣe bẹẹ.

Ninu atẹjade kan to fi si oju opo X rẹ, Aarẹ Macron sọ pe oun yoo ṣe ikede yii taara lasiko ipade apapọ ajọ UN ti yoo waye ni New York.

"Ohun to ṣe pataki loni yii ni pe ki ogun to n lọ ni Gaza pari, ki awọn araalu si ri aabo. Alaafia le jọba, a nilo ki ogun pari kiakia, ki wọn fi gbogbo awọn to wa nigbekun silẹ, ki wọn si ko awọn nnkan iranwọ gbogbo tọ awọn eeyan Gaza lọ."

Bẹẹ ni Macron kọ ọ soju opo rẹ.

Awọn alaṣẹ Palestine gba ipinnu Macron wọle, nigba ti Olootu ijọba ilẹ Israeli; Benjamin Netanyahu, sọ pe igbesẹ naa jẹ ẹsan fun igbesunmọmi, lẹyin ikọlu Hamas to waye lọjọ keje, oṣu Kẹwaa ọdun 2023 ni Israel.

''Orilẹede United States fi gbogbo ara lodi si ikede Macron.'' Akọwe Ijọba, Marco Rubio lo sọ bẹẹ, o si ṣapejuwe ipinnu Macron bii eyi ti wọn ko ro ki wọn too ṣe e.

Awọn orilẹede ti a mọ si G7, jẹ akojọpọ awọn orilẹede ti ileeṣẹ to ti goke agba pọ nibẹ daadaa, awọn bii France, US, UK, Italy, Germany, Canada, ati Japan.

Israel ko ka Palestine si orilẹede to le da duro, ijọba Israeli to si wa lori aleefa bayii, lodi si dida ipinlẹ Palestine kankan silẹ ni agbegbe West Bank ati Gaza.

Awijare wọn ni pe iru ilu bẹẹ yoo maa dunkooko mọ iwalaaye Isreali ni.

Ninu ọrọ kan to kọ si oju opo X rẹ, Olootu ijọba, Netanyahu, sọ pe "Dida ipinlẹ Palestine kankan silẹ niru ipo ti a wa yii yoo jẹ ọna kan lati fopin si Israel — ki i ṣe lati gbe lẹgbẹẹ rẹ pẹlu alaafia. Ẹ jẹ ko ye wa yeke : awọn eeyan Palestine ko sọ pe awọn n fẹ ipinlẹ bii Israel; kaka bẹẹ, idaduro ipinlẹ ara wọn ni wọn n beere fun, ki i ṣe Israel."

Aarẹ Palestine; Mahmoud Abbas lapa osi, Aarẹ France, Emmanuel Macron lapa ọtun.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Aarẹ Palestine; Mahmoud Abbas lapa osi, Aarẹ France, Emmanuel Macron, lasiko ipade kan ni Paris loṣu Keje ọdun 2022.

Àwọ wo ni wọ́n gba Palestine bíi ìlú?

Lọwọlọwọ, ogoje (140) ninu awọn ọmọ ẹgbẹ UN ti apapọ wọn jẹ 193 ni wọn gba Palestine bii orilẹede laaye ara rẹ. Lara wọn ni awọn ọmọ ẹgbẹ Arab, Organisation of Islamic Cooperation ati Non-Aligned Movement.

Awọn orilẹede ilẹ Europe kan naa wa lara wọn, awọn bii Spain, Ireland ati Norway to gba Palestine bii orilẹede loṣu Karun-un ọdun 2024.

Ṣaaju igba naa, perete ni awọn orilẹede Europe to gba bẹẹ — pupọ wọn ni 1988, nigba ti wọn ṣi wa lara ajọ Soviet bloc.

Ṣugbọn ṣaa, alatilẹyin Israel pataki, America ati awọn ọrẹ rẹ bii United Kingdom ati Australia, ko ti i gba Palestine ni orilẹede to le da duro.

Australia ti fi han ni tiẹ pe oun le ṣe bẹẹ ni toun, lati bẹrẹ ajọṣepọ pẹlu Israel.

Ni oṣu Kẹrin, US dabaa lati fun Palestine lagbara ati jẹ ọmọ ẹgbẹ UN kikun.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ni oṣu Kẹrin, US dabaa lati fun Palestine lagbara ati jẹ ọmọ ẹgbẹ UN kikun.

Kí ló dé tí àwọn orílẹ́èdè kan kò ka Palestine sí ìlu tó lè dá dúró?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn orilẹede ti ko ti i gba Palestine bii ilu to le da duro n ṣe bẹẹ nitori ko ti i si adehun ajọsọ pẹlu Israel.

"Bo tilẹ jẹ pe o n ṣe oju aye pe o ṣe pataki lati da orilẹede Palestine silẹ, orilẹede America fi dandan le e pe ajọsọ gbọdọ waye laaarin Israel ati Palestine, eyi to tumọ si fifun Israel lagbara lori Palestine."

Fawaz Gerges, Ọjọgbọn onimọ nipa ajọṣepọ awọn orilẹede ni London School of Economics lo ṣalaye bẹẹ.

Ọdun 1990 sisalẹ ni wọn bẹrẹ ajọsọ alaafia, wọn si fẹnuko si adehun orilẹede meji, nibi ti Israeli ati Palestine ti le gbe lẹgbẹẹ ara wọn ni orilẹede ọtọọtọ.

Ṣugbọn igbesẹ alaafia naa bẹrẹ si i yingin nibẹrẹ ọdun 2000, koda ṣiwaju 2014, nigba ti ẹnu Israeli ati Palestine ko tun ko ni Washington.

Gbogbo ọrọ to lagbara to yẹ ki wọn yanju ni ko ṣee yanju, titi kan ọrọ ẹnu ibode ati bi aye yoo ṣe ri fun Palestine to ba da duro lọjọ iwaju.

Awọn ọrọ nipa Jerusalem ati awọn atipo ọmọ Palestine lati igba ogun 1948-49 to tẹle e ti wọn fi da Israel silẹ ko yanju.

Niṣe ni Israel taku delẹ pe Palestine ko ni i di ọmọ ẹgbẹ UN .

Aṣoju ajọ UN fun Israel, Gilad Erdan, ni iroyin AFP kede pe o sọ loṣu Kẹrin ọdun 2024, pe ijiroro to n waye ti tumọ si iṣẹgun ati ipaniyan, lati ọwọ awọn agbesunmọmi.

Ohun ti awọn ilu to ba fẹ ki ajọṣepọ wọn pẹlu Israel dara gbọdọ mọ ni pe, bi wọn ba fara mọ ki Palestine da duro bii orilẹede, inu yoo bi Israel.

Awọn kan lara awọn to tẹle Israel n sọ pe Palestine ko kunju oṣuwọn lati da duro bii orilẹede, wọn ni wọn ko ni ohun ti ipade Montevideo Convention ọdun 1933, gbe kalẹ — awọn nnkan bii onka eeyan ti ko yipada, aaye ibugbe to jẹ tiwọn gangan, ijọba ati agbara lati le ba awọn orilẹede mi-in ṣe.

Ṣugbọn awọn mi-in sọ pe bi wọn ba ti le ni agbara lati ba awọn orilẹede mi-in ṣe, abuṣe buṣe.

O kere tan, orilẹede ogoje lo gba Palestine bii eyi to le da duro laaye ara rẹ.

Oríṣun àwòrán, SHAHZAIB AKBER/EPA-EFE/REX/Shutterstock

Àkọlé àwòrán, O kere tan, orilẹede ogoje lo gba Palestine bii eyi to le da duro laaye ara rẹ.

Ojú wo ni àjọ UN fi ń wo àwọn ẹkùn Palestine?

Ni 2011, Palestine fiwe ranṣẹ lati jẹ ọmọ ẹgbẹ kikun ninu ajọ UN, ṣugbọn igbesẹ naa ko bọ si i nitori ai si atilẹyin lati ọdọ igbimọ akọwe UN.

Ilu ti ki i ṣe ara ajọ UN ni wọn ka Palestine si.

Ṣugbọn ni 2012, igbimọ apapọ UN ṣeto ibo ti yoo gbe awọn Palestine naa ga si ilu ti ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ kikun ṣugbọn to ni anfaani si awọn ẹtọ kan ("non-member observer state") eyi ti yoo fun wọn ni anfaani lati kopa ninu ijiroro ẹgbẹ, bo tilẹ jẹ pe wọn ko le le dibo ti wọn yoo fi fẹnuko si ipinnu kan.

Ipinnu ọdun 2012 ti wọn tẹwọgba ni West Bank ati Gaza Strip, ṣugbọn ti US ati Israel bu ẹnu atẹ lu, naa fi aaye gba awọn Palestine lati darapọ mọ awọn ajọ agbaye miran, titi kan ile ẹjọ giga UN ti i ṣe International Criminal Court, eyi ti wọn ṣe ni 2015.

Ni oṣu Karun-un ọdun 2024, ipade apapọ UN gbe ẹtọ Palestine soke laaarin ẹgbẹ naa, o si rọ wọn lati gba a wọlẹ bii ọmọ ẹgbẹ, eyi waye lẹyin ariyanjiyan rẹpẹtẹ to ṣẹlẹ lori ọrọ naa.

Ifẹnuko ọjọ naa lo faaye gba Palestine lati maa kopa kikun ninu ijiroro, da aba, kawọn naa si le fa eeyan kalẹ bii aṣoju ninu igbimọ, ṣugbọn ko fun wọn laye lati le dibo.

Igbimọ akọwe UN nikan lo lẹtọọ lati sọ eeyan di ọmọ ẹgbẹ.

Loṣu Kẹrin ọdun naa, ilẹ America, gẹgẹ bii ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ marun-un ti wọn yoo maa jẹ ọmọ ẹgbẹ titi lae, lodi si aba Algeria lati gba Palestine wọle bii ilu, wọn ni aba naa ti ya ju.

Ohun ti a gbọdọ mọ ni pe ifẹnuko awọn igbimọ ki i yi pada, ofin si de e, nigba ti eyi to ba ti ọdọ igbimọ apapọ wa ko ri bẹẹ.

"Didi ọmọ ẹgbẹ pata yoo fun Palestine ni igbega si i, titi kan pe awọn naa yoo le da si ọrọ lai si pe wọn fi iṣẹ wọn ran ẹlomi-in."

Khaled Elgindy, Adari eto to jẹ mọ Palestine -Israeli ni Middle East Institute, lo sọ bẹẹ.

O ni ṣugbọn eyi ko tumọ si pe ilu meji yoo wa.

Gilbert Achcar, Ọjọgbọn nipa ibaṣepọ awọn orilẹede ni School of Oriental and African Studies, London, ni tiẹ, gbagbọ pe ko si nnkan gidi kan ti Palestine le mu bọ bi wọn ba di ọmọ ẹgbẹ UN ni kikun.

"Yoo kan jẹ aṣeyọri to lapẹẹrẹ ni: bii ohun ti a kan fori ro lasan, Palestine to wa ṣugbọn ti ko lagbara. Apa kan ninu aaye ti wọn wa lori ẹ ni 1967, Palestine ti ko le da nnkan ṣe afi ti wọn ba da ara de Israel."

O ni o ku diẹ ti ti Palestinian yoo fi di ilu olominira to le da duro lori ẹsẹ rẹ".