Kí ló dé tí Egúngún Oloolu tí obìnrin kì í rí fi fẹ́ dé ilé ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo?

Oríṣun àwòrán, Screen shot
Lati ayebaye ni o ti jẹ eewọ fun obinrin lati foju kan eegun kan ti a mọ si Oloolu, niluu Ibadan. Obinrin ki i ri rara, oun naa ki i si i ri obinrin ni gbogbo ibi to ba lọ.
Ṣugbọn ni bayii ti ọdun eegun fẹẹ bẹrẹ n'Ibadan lọjọ Aje, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keje 2025, eegun Oloolu yoo jade. Koda, yoo de ile ijọba ipinlẹ Oyo, nibi ti tọkunrin-tobinrin ti n ṣiṣẹ ọba.
Atẹjade kan ti Akọwe iroyin Olubadan, Oloye Ayoade Solomon Olugbemiga, buwọlu to si fi sita lọjọ Ẹti lo kede pe Oloolu yoo de ọfiisi ijọba Oyo.
Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe wi, bi ọdun eegun ba bẹrẹ lọjọ Aje, yoo pari l'Ọjọbọ, ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Keje, ọdun 2025 .
Laarin asiko ọdun naa ni Oloolu yoo si ṣabẹwo si ile ijọba ipinlẹ Oyo to n bẹ ni Agodi.
Yoo de Aafin Olubadan l'Oke Aremo pẹlu.
Wọn fi kun un pe Oloolu yoo de ile Olubadan ti wọn ṣẹṣẹ yan, Ọba Rasidi Adewolu Ladoja ati awọn aaye mi-in to ni apẹẹrẹ n'Ibadan.
Ẹ o ranti pe ọdọọdun ni Oloolu maa n jade n'Ibadan, wọn n lo ijade rẹ naa lati tu awọn alalẹ ilẹ Ibadan loju bi wọn ṣe wi.
Ṣugbọn ibeere ti ọpọ eeyan n beere bayii ni pe:
Báwo ni yóò ti rí nílé ìjọba?
Lati igba ti atẹjade yii jade sita ni ọpọ eeyan ti n beere, pe ki gan-an ni Eegun Oloolu n lọọ ṣe nile ijọba ipinlẹ Oyo. Bawo ni nnkan yoo si ti ri nigba ti eegun naa ba de.
Awọn mi-in n beere pe bawo ni wọn yoo ti ṣe e lọtẹ yii ti awọn oṣiṣẹ ijọba to jẹ obinrin ko ni i foju kan eegun naa nigba to ba wọ ọfiisi.
Bakan naa ni awọn kan n sọ pe ijade Oloolu sile ijọba ko ni itumọ kan.
Awọn mi-in si n kilọ pe ki egungun funra rẹ gan-an ni ko ṣọra nibi to n lọ naa.
Wọn ni ibi iṣẹ ti obinrin lẹtọọ si lati ṣẹ labẹ ofin ni eegun ti n lọọ ba wọn.
Ṣaa, atẹjade to kede irin ajo Oloolu, kilọ pe kawọn obinrin ri i daju pe wọn ko rin pade eegun alagbara naa, nitori ọ̀san ati oru ko jọra wọn.
Wọn pe fun awọn ẹṣọ alaabo lati mu aabo ẹmi ati dukia ni koko, lasiko ti Oloolu ba gbode nigboro Ibadan.
Arọwa yii waye latari bi awọn kan ṣe maa n sọ asiko ọdun eegun naa di ti jagidijagan.














