Mọ̀ nípa àwọn akọni obìnrin ọmọ Yorùbá tí òkìkí wọn kàn káàkiri àgbáyé

Aworan Folorunso Alakija,Ibukun Awosika,Angelie Kidjo ati Tems

Oríṣun àwòrán, Instagram/Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Bi ọmọ ẹni ba daa ka wi, a o kuku ni i fi ṣe aya.

Ati pe bi ara ode ba n ṣe ọmọ ẹni gẹgẹ, ọlọmọ funra ẹ gbọdọ ṣe apọnle ọmọ ọhun ju bẹẹ lọ.

Lagbaaye lonii, bi awọn ọkunrin to lorukọ ati okiki ṣe n gbayi nipasẹ ohun ti wọn n ṣe to n kun aye loju, bẹẹ ni awọn obinrin naa wa bẹẹ.

Fun ti àyọkà yii, awọn obinrin Naijiria ti wọn jẹ ọmọ Yoruba atata, ti orukọ wọn n ja ranin-in lode agbaye ni a fẹẹ gbe yẹwo.

Paapaa lati ṣe ayajọ ọjọ awọn obinrin ọmọ ilẹ Africa ti a mọ si 'Women and Girls of African Descent.'

Bo si tilẹ jẹ pe wọn pọ diẹ ni onka, wọnyi ni mẹrin lara wọn ti wọn jẹ Yoruba:

Folorunso Alakija

Folorunso Alakija

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keje ọdun 1951 ni wọn bi Folorunso Alakija, ni ilu Ikorodu, ipinlẹ Eko.

Olowo nla, oniṣowo pataki ati ẹlẹyinju aanu to maa n fowo ṣaanu ni.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọga ileeṣẹ elepo rọbi nla ni Foloruso Alakija pẹlu.

Baba rẹ, Oloye L.A. Ogbara, ni iyawo mẹjọ ati ọmọ mejilelaadọta (52).

Iya to bi Folorunso ni akọkọ ninu awọn iyawo baba naa.

Ọmọ ọdun mẹwaa pere ni Folorunso wa to fi tẹkọ leti lọ si orilẹede United Kingdom, bo tilẹ jẹ pe o pada wa sile lati lọ sileewe girama Muslim High School, ni Sagamu, ipinlẹ Ogun.

Folorunso Alakija tun pada soke okun lati kẹkọọ nipa iṣẹ akọwe, eyi to ṣe ni Pitman Central College, London.

Alakija ṣiṣẹ nile ifowopamọ fun ọpọ ọdun, o di ọga nibẹ.

Akinkanju ọmọ Yoruba naa tun bọ si ẹka awọn aranṣọ, o kẹkọọ naa ni American College ati Central School of Fashion, ni London

Alakija bẹrẹ ileeṣẹ telọ rẹ to pe ni Supreme Stitches, o yi orukọ naa pada si The Rose of Sharon House of Fashion ni 1996. Ero rẹ si ni lati maa fi ran awọn opo ati ọmọ orukan lọwọ.

Oun si ni aarẹ ẹgbẹ Fashion Designers Association of Nigeria (FADAN).

Ọdun 1993 ni iya yii beere fun aṣẹ ati maa ta epo rọbi, o si bẹrẹ iṣẹ naa pẹrẹwu.

Foloruso Alakija ti wa lara awọn ọgọrun obinrin to peregede julọ lagbaaye, ajọ agbaye Forbes to n ri si iru ẹ lo fi orukọ rẹ si i.

Bakan naa ni wọn kede Folorunso Alakija bi obinrin to lowo julọ nilẹ Africa ni 2021.

Ọpọlọpọ ami ẹyẹ ni Alakija ti gba nilẹ yii ati kaakiri agbaye.

Ibukunoluwa Abiodun Awosika

Ibukun Awosika

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ibukun Awosika

Ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kejila ọdun 1962 ni wọn bi Ibukunoluwa Abiodun Motunrayo Omobolanle Adekola to pada di aya Awosika.

Ilu Ibadan, nipinlẹ Oyo ni wọn ti bi Ibukun Awosika. Oniṣowo nla ni, oun si ni obinrin akọkọ to di alaga nile ifowopamọ First Bank.

Oṣu Kẹsan-an ọdun 2022 ni wọn yan an bi ọmọ ẹgbẹ Binance Global Advisory Board.

O si tun jẹ ọmọ ẹgbẹ Women in Management, Business and Public Service.

Ipo kẹta ni Ibukun wa ninu ọmọ meje ti awọn obi rẹ bi.

O lọ sileewe alakọọbẹrẹ St. Paul's African Church Primary School, l'Ekoo, ati Methodist Girl's High School, Yaba l'Ekoo kan naa.

Yunifasiti Ile Ife ti i ṣe Obafemi Awolowo Yunifasiti bayii ni Ibukun Awosika ti kẹkọọ gboye ninu imọ nipa Chemistry.

Awosika ṣiṣẹ bi agunbanirọ ni ẹka ayẹwo owo ileeṣẹ Akintola Williams & Co, eyi to pada di Deloitte.

O pada wale o si darapọ mọ Alibert Nigeria Ltd, ileeṣẹ to n ṣe aga ijokoo, nibi to ti ṣiṣẹ bii alabojuto ibudo ikeru si wọn.

Ibukun Awosika jẹ sọrọsọrọ ati olugbani-nimọran.

O wa lara ọmọ Naijiria marun-un to farahan ninu eto Dragon's Den.

O tun jẹ atọkun eto ori tẹliṣan kan to pe ni Business His Way. Lẹyin naa lo tun kopa ninu 2020 Citation pẹlu Temi Otedola ti Kunle Afolayan ṣe.

Awọn iwe to ti kọ ni:

The "Girl" Entrepreneurs

*Business His Way

Bakan naa ni Ibukun Awosika ti gba ami ẹyẹ ọlọkan o jọka bii Africa Forbes Woman Awards 2020, THISDAY Newspaper Annual Merit Award, FATE Model Entrepreneur Award of the Year, Golden Heart Award ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Angélique Kpasseloko Kidjo

Angélique Kpasseloko Kidjo

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àkọlé àwòrán, Angélique Kpasseloko Kidjo

Obinrin yii ni orirun Yoruba nipasẹ bo ṣe wa lati Benin mọ Faransẹ.

Olorin ni, oṣere ni, o si tun jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan to lorukọ nla kaakiri agbaye.

Kidjo ti gba ami ẹyẹ Grammy Awards marun-un, ọdun 2023 lo si gba ti gbajugbaja ami ẹyẹ Polar Music Laureate.

Ọpọlọpọ orin lo ti gbe jade to kari agbaye, o si maa n ba awọn olorin miran kọrin pọ daadaa.

Ọjọ kẹrinla, oṣu Keje ọdun 1960 ni wọn bi i.

Temilade Openiyi (Tems)

Temilade Openiyi (Tems)

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Temilade Openiyi (Tems)

Tems ni orukọ ti ọpọ eeyan mọ ọmọbinrin Yoruba yii si, olorin ni, o maa n kọ orin ta, o si tun maa n to orin pọ lati gbe jade.

Ọdun 2020 ni okiki Tems buyọ, lẹyin to ba olorin taka sufe nni, Wizkid, ṣe "Essence", eyi to wa nipo kẹsan-an lori atẹ ọgọrun-un.

Ọjọ kọkanla, oṣu Kẹfa ọdun 1995 ni wọn bi Tems niluu Eko, ọmọ Yoruba ni.

Lara ami ẹyẹ ti Tems ti gba ni: Grammy Award for Best Melodic Rap Performance .

Olorin taka sufee ọmọ Yoruba naa ti di gbajugbaja kaakiri agbaye.