Ìlù bàrà tí wọ́n lù mí nílé Keu ló mú mi yí ẹ̀sìn mi padà - Peller

Oríṣun àwòrán, Peller
Gbajugbaja alawa ori Tiktok, Habeeb 'Peller' Hamzat, ti sọ pe oun kii ṣe ẹlẹsin Musulumi bi ko ṣe ẹlẹsin Kristẹni.
O ni lati kekere ni ọkan oun ti ṣi kuro ninu ẹsun Islam si ẹsin Kristẹni lẹyin iṣẹlẹ kan lọpọ ọdun sẹyin.
Peller lo sọ ọrọ yii lasiko to n ba awọn ololufẹ rẹ sọrọ lori ayelujara ti ọkan ninu wọn si pe e ni Musulumi.
Wọn na mi ni pankẹrẹ nile keu
O ni "mi o ki n ṣe Musulumi o, ọmọlẹyin Kristi ni mi."
Lẹyin naa lo ṣalaye eredi ati akoko to kuro ninu ẹsin Islam si ti Kristẹni latari bi olukọ imọ Arabic kan ṣe lu u lọdun naa lọhun, eyii ti ko dun mọ ninu.
O ṣalaye pe bi aafa naa ṣe na oun lọjọ naa lọhun lo ṣokunfa bi oun ṣe fi ẹsin ọhun silẹ.
Ninu ọrọ rẹ, Peller sọ pe "ewo ni ki ẹ maa sọ pe Musulumi ni ọdọkunrin yii.
"Mi o ki n ṣe Musulumi o, Kristẹni ni mi, Kristẹni paraku ni mi, mo si n lọ si ṣọọṣi daadaa.

Oríṣun àwòrán, Peller
"Ẹ jẹ ki n ṣalaye eredi ti mo ṣe fi ẹsin Musulumi silẹ; nigba ti mo ṣi n lọ sile Keu, wọn fi pankẹrẹ na mi.
"Wọn gbe mi lati ibi ti mo wa, wọn gbe mi lọ si ẹyin, wọn wa fi ẹgba dara si idi mi. Mo pariwo pe Jesu, mo n bọ lọdọ rẹ.
"Wọn da seria gidi fun mi, idi ti mi o fi lọ mọ niyẹn."
Peller pari ọrọ rẹ pe lootọ loun fẹran ẹsin Musulumi ati ẹsin Kristẹni amọ oun ko faramọ bulala ti wọn fi na oun nile Keu, oun ko si le farada a.















