Ilé aṣòfin àgbà l'Abuja dábàá òfin tí yóò mu ni dandan fáwọn òṣìṣẹ́ ìjọba láti máa lo ilé ìwòsàn àti ilé ẹ̀kọ́ ìjọba

Oríṣun àwòrán, Tajudeen Abbas/X
Ile aṣoju-ṣofin agba l'Abuja ti ṣe agbekalẹ aba ofin kan ti yoo fi ofin de awọn oṣiṣẹ ijọba ati awọn to wa nipo ijọba lati ma le lo ile iwosan ati ile ẹkọ aladaani mọ ni Naijiria.
Ọjọ Iṣẹgun ọjọ kejilelogun, oṣu Keje, ni ile aṣofin naa ṣe agbekalẹ aba ofin ọhun ti wọn pe ni HB 2487.
Aṣofin Amobi Godwin Ogah to ṣagbatẹru aba naa sọ fun awọn akọroyin wi pe, aba ofin yii yoo mu ni dandan fun awọn to wa nipo ijọba lati maa lo ile ẹkọ ati ile iwosan ijọba to ba di ofin tan.
Ogah ni aba ofin naa yoo ṣe iranwọ fun igbedide awọn ile ẹkọ ati ile iwosan ijọba lati ri amojuto ti wọn nilo.
Aṣofin naa ṣalaye pe ti awọn to wa nipo ijọba atawọn oṣiṣẹ ijọba ṣe n lo ile iwosan aladaani ni Naijiria ati loke okun wa lara idi ti eto ẹkọ ati eto ilera ko fi fẹsẹ mulẹ daadaa.
O ni aba ofin yii yoo jẹ ki araalu fọkan tan awọn to wa ni ijọba, ati pe yoo tun jẹ ki awọn eeyan ni igbagbọ ninu lilo ile iwosan ati ile ẹkọ ijọba ni Naijiria.
Bakan naa ni Ogah fikun ọrọ rẹ wi pe, ile ẹkọ ijọba lawọn adari to ja fun ominira orilẹede Naijiria bii Sir Ahmadu Bello, Oloye Obafemi Awolowo, Ọmọwe Nnamdi Azikwe ati Tafawa Balewa lọ lasiko wọn.
O ni eyi yatọ si nnkan ti ọpọ awọn to wa nipo ijọba lonii n ṣe ti wọn ko lọ ile ẹkọ ijọba tabi lo ile iwosan ijọba mọ.
''$29.29bn lawọn ọmọ Naijiria na nile iwosan ilẹ okeere lasiko ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari''
Ọgbẹni Ogah bu ẹnu atẹ lu obitibiti owo ti awọn ọmọ Naijiria n na lori eto ẹkọ ati eto ilera loke okun.
O ni owo to le ni $29.29bn lawọn ọmọ Naijiria na lori itọju ara wọn lawọn ile iwosan ilẹ okeere lasiko ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari.
Bakan naa ni o tun sọ pe ko din ni $218.87m tawọn ọmọ Naijiria na lori eto ẹkọ nilẹ okeere lọdun 2023 nikan.
Aṣofin Ogah ṣalaye siwaju sii pe N1.336tr ni owo ti ijọba ya sọtọ fun eto ilera nikan ninu eto iṣuna ọdun 2024, nigba tawọn ọmọ Naijiria n na owo ti ko din ni N1.6 tr lọdọọdun lori eto ilera nilẹ okeere.
''Ohun to ba mu wa yọ owo iranwọ ori epo bẹntiroolu kuro, a gbọdọ ṣofin ti ko ni jẹ kawọn oṣiṣẹ ijọba atawọn to wa nipo ijọba ma dẹyẹ si ile ẹko ati ile iwosan ijọba naa,'' Ogah lo sọ bẹẹ.
O ni nitori pe ọpọ eeyan to wa ni ijọba n lo soke okun fun itọju ara wọn ati fun eto ẹkọ ni ko jẹ ki awọn ile ẹkọ ẹkọṣẹ iṣegun duro daadaa mọ ni Naijiria.
Aṣofin naa sọ pe ofin yii yoo mu adinku ba bi awọn ọmọ Naijiria ṣe n ku sile iwosan loke okun, ati pe yoo tun jẹ ki araalu ni igbagbọ ninu ile iwosan ijọba ni Naijiria.
O wa rọ awọn ọmọ Naijiria atawọn akọroyin lati ṣe atilẹyin fun abadofin naa ko le di ofin.















