Gómìnà Seyi Makinde ṣàbẹ̀wò sí ẹbí Olubadan, ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ oyè Ibadan yóò ṣe rí láàrín àádọ́ta ọdún

Gómìnà Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti ṣàlàyé pé ìlànà ọba jójẹ ní ìlú Ibadan yóò túnbọ̀ dúró ire si pẹ̀lú àwọn ìgbésẹ̀ tí ìṣèjọba rẹ̀ gbé lọ́dún 2019 láti kojú àwọn kùdìẹ̀kudiẹ tó wáyé nígbà náà.

Makinde wòye pé òun lo àsìkò náà láti mú ìṣọ̀kan wà nínú ìlànà oyè jíjẹ náà tóun sì ìgbòòrò bá ìlànà àwọn lọ́balọ́ba.

Lásìkò tí gómìnà Makinde ṣe àbẹ̀wò ìbánikẹ́dùn sí ilé Olubadan ilẹ̀ Ibadan tó wájà, Ọba Owolabi Olakulehin lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kejìlélógún, oṣù Keje, ọdún 2025 ló sọ̀rọ̀ náà.

Ó sọ pé kò sí iyè méjì tàbí ẹjọ́ wẹ́wẹ́ kankan lórí ìṣọ̀kan ipò ọba jíjẹ ní ìlú Ibadan.

Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọmọ Ibadan fún àtìlẹyìn àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọn lásìkò táwọn àyípadà náà wáyé.

"Nígbà tí mo gba ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo lọ́dún 2019, mo kojú àwọn ìṣòro kan lórí oyè ọba jíjẹ ní Ibadan, mo sì pe gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn pé kò ní pẹ́ ti mà á fi yanjú rẹ̀.

"Mo pàdé Kabiyesi ní ilé ìjọsìn ní Aremo, mo sì sọ fún wọn pé gbogbo nǹkan tí mò ń ṣe ni àbọ̀ rẹ̀ máa da.

"Mo fi kun pé mi ò ní yẹ́bàá láti kojú àwọn ìpèníjà wa, pé a máa mú kí ìlànà ọ̀rọ̀ oyè dára ju bí a ṣe bá a lọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Mo lè fi gbogbo ẹnu sọ pé ní àádọ́ta ọdún sí àsìkò yìí, ìlànà oyè jíjẹ ní Ibada ṣì máa dúró digbí nítorí gbogbo wa ti wà ní ìṣọ̀kan báyìí."

Gómìnà náà fi kun pé òun máa ṣe ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún Ọba Olakulehin, tí òun sì máa ṣe gbogbo ohun tó yẹ lórí ètò ìsìnkú ọba náà.

Balogun ilẹ̀ Ibadan, Ọba Tajudeen Ajibola nígbà tó ń gbẹnu àwọn olóyè ìlú Ibadan sọ̀rọ̀ dúpẹ́ lọ́wọ́ gómìnà Makinde fún àtìlẹyìn rẹ̀ fún Ọba Olakulehin nígbà ayé rẹ̀ àti lẹ́yìn tó wàjà.

Ó fi kun pé àwọn ohun mèremère ni wọ́n mọ́ Seyi Makinde fún láti ìgbà tó ti wà nípò gómìnà Oyo pàápàá ní ìlànà oyè jíjẹ àti bó ṣe máa ń mú ọ̀rọ̀ àwọn lọ́balọ́ba.

Ní ọjọ́ Keje, oṣù Keje, ọdún 2025 ni Oba Olakulehin wàjà lọ́ni àádọ́rùn-ún ọdún, tó sì lo ọdún kan ní ipò ọba Olubadan.

Ṣáájú ìyànsípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olubadan ni àwọn awuyewuye kan wáyé lórí ìlera rẹ̀.

Bákan náà ni àwọn awuyewuye kan ti ṣáájú wáyé lórí ìlànà oyè Olubadan jíjẹ lẹ́yìn tí gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Oyo Abiola Ajimobi gbé àwọn òfin kan dìde nígbà tó wà nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà.