Kí ló mú kí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo wó ìlúmọ̀ọ́ká Ilé ìtura De-Castle Inn ní Ibadan?

Ọkan lara awọn ile itura to lorukọ to si ti pẹ gan-an niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo, iyẹn De-Castle-Inn Hotel, ni ijọba ipinlẹ naa ti wo lulẹ bayii.
Opopona Queen Elizabeth, Agodi, niluu Ibadan ni otẹẹli naa wa.
Ọjọ Abamẹta, ọjọ kọkandinlogun oṣu Keje ọdun 2025 yii ni ijọba ipinlẹ Oyo gbe awọn katakata ti wọn fi n wole lọ si ile igbafẹ yii.
Bakan naa ni wọn tun ko awọn ẹṣọ alaabo ati awọn oṣiṣẹ ajọ Operation Burst lọ sibẹ lati pese aabo fun awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Oyo to n wo o lulẹ.
Bi ile igbafẹ De-Castle ṣe tobi to, ọdún kẹwaa ree to ti di ahoro.
Àlàyé ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo lórí ìgbésẹ̀ náà

Kọmiṣanna fun ọrọ Ilẹ ati idagbasoke nipinlẹ Oyo, Williams Akin Funmilayo, ṣalaye pe ijọba ko fẹ ki iru iṣẹlẹ to waye ni Bodija, nibi ti ọpọ eeyan ti padanu ẹmi ninu ibugbamu ọdun 2023 tun waye mọ.
O ni eyi lo fa a ti ijọba fi tete da otẹẹli to ti di ahoro l'Agodi yii lulẹ.
Kọmiṣanna tẹsiwaju pe ọjọ kẹsan-an, oṣu Keji ọdun 2024 ni ijọba ipinlẹ Oyo ti kọkọ kọwe si ẹni to ni ile igbafẹ yii, Adeyemo Omole, lati tete ṣe amulo rẹ bi ile igbafẹ to kọ ọ fun lati ibẹrẹ pẹpẹ.
O ni ikilọ naa waye nitori awọn janduku ati awọn adigunjale n lọ ile igbafẹ ọhun lati ṣiṣẹ ibi, nigba ti ẹni to ni i ko ya si i mọ, ti ibẹ si ti di aharo.
Awọn ole ati awọn to n da araalu lọna lo sọ ile itura naa di ibuba ati ibugbe latari ai si abojuto.

O ni wọn n gbabẹ ja awọn eeyan agbegbe naa lole, ati awọn to ba n re kọja lọ.
Akin Funmilayo fi kun un pe ẹni to ni otẹẹli De-Castle ko fesi si lẹta tijọba kọ si i fun odidi ọdun kan.
Ọjọ mẹrinla si ni ijọba fun un nigba naa lati ṣe atunṣe rẹ.
Bakan naa ni Kọmiṣanna sọ pe ijọba ipinlẹ Oyo kede ninu iwe iroyin kan to gbajumọ lorileede yii, lọjọ karundinlogun, oṣu Karun-un ọdun yii, pe oun ti gbẹsẹ le ile igbafẹ De-Castle, nitori aabo ilu.
Sibẹ, Adeyemi Omole to ni ile igbafẹ naa ko tun fesi, eyi lo ni o fa a ti ijọba fi pada wo o lulẹ ni Satide to kọja.
'Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyọ ń gbèrò láti kọ̀ iléeṣẹ́ Amotekun síbẹ̀'
Ni itẹsiwaju alaye rẹ, Akin Funmilayo sọ pe ero ijọba ipinlẹ Oyo lori ile itura ti wọn wo naa ni lati kọ aaye ipagọ ati ọfiisi awọn ikọ Amotekun ipinlẹ naa sibẹ.
O ni eyi yoo tun mu adinku ba iwa janduku nipinlẹ Oyo.
Fun awọn ti idi ti ijọba fi wo De-Castle ko ye, aṣoju ijọba ṣalaye pe ijọba ko gbẹsẹ le ibẹ lati ta a, tabi lati fi tọrẹ fun ẹnikéni.
O ni ibẹ yoo wa fun kikọ ile ipago ati ọfiisi fun ikọ Amọtẹkun ipinlẹ Oyo ni.
Lakootan, Kọmiṣanna sọ pe bi ẹni to ni otẹẹli De-Castle ba pada yọju si ijọba Oyo, o ṣee ṣe ki wọn fun un ni owo gba-ma-binu.
O ni sugbọn ni bayii, o ti di ti ijọba patapata.














