Oluwaseun Kuforiji rán aṣọ pẹ̀lú òwú àti abẹ́rẹ́ nìkan fún wákàtí mẹ́rìndínláàdọ́fà
Oluwaseun Kuforiji, to jẹ aranṣọ ti ṣe nnkan ti ẹnikan ko ṣe ri, pẹlu bo ṣe fi owu ati abẹrẹ nikan ran aṣọ fun wakati mẹrindinlaadọta (106 hours).
Igbiyanju rẹ ọhun lo waye fun idije ami ẹyẹ Guiness World Record, to si ṣe aṣeyọri.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC News Yoruba, Ọgbẹni Kuforiji sọ pe ẹrọ iranṣọ ni oun kọkọ gbeero lati fi dije fun ami ẹyẹ naa, amọ awọn oludari eto naa sọ pe eyi tako ilana gbigba a.
Eyi lo mu ko fi oṣu mẹfa miran gbaradi, to si kọ bi wọn ṣe n fi abẹrẹ ati owu nikan ran aṣọ lai lo ẹrọ iranṣọ.

Kuforiji to n ṣiṣẹ aranṣọ nipinlẹ Ogun sọ pe ọdọ baba kan ti oun gbe dagba ni oun ti foju si iṣẹ aṣọ riran.
"Ere ni mo fi n ṣe nigba naa, lai mọ pe yoo pada di nnkan t imo fi n jẹun."
O ṣalaye pe oun ti ṣe ọpọlọpọ aṣeyọri nidii iṣẹ aṣọ riran, eyi si lo mu ki oun pinnu lati ṣe nnkan ti yoo polongo orukọ oun ati ibi ti oun ti wa.



