"Ogún ọdún rèé tí mo ti ń ta ẹ̀pà, gúgúrú àti dáńkúà fáwọn olólùfẹ̀ẹ́ bọ́ọ́lù Kwara United, kò sí ìlú tí ń kìí tẹ̀lé wọn lọ"

Àkọlé fídíò, "Ogún ọdún rèé tí mo ti ń ta ẹ̀pà, gúgúrú àti dáńkúà fáwọn olólùfẹ̀ẹ́ bọ́ọ́lù, kò sí ìlú tí ń kìí tẹ̀lé wọn lọ"
"Ogún ọdún rèé tí mo ti ń ta ẹ̀pà, gúgúrú àti dáńkúà fáwọn olólùfẹ̀ẹ́ bọ́ọ́lù Kwara United, kò sí ìlú tí ń kìí tẹ̀lé wọn lọ"

Yoruba ni ohun to ba n wu ni, nii pọ lọrọ ẹni, bi obinrin kan to n ta ẹpa, guguru ati dankua yoo se ri ti aje se lo mumu ni aya rẹ.

Obinrin ọhun, Oluwatoyin Abdullahi si lo n kiri ẹpa ni ibudo ere idaraya to wa nilu Ilorin nibi ti ẹgbẹ agbabọọlu Kwara United ti maa n sere idaraya.

Ẹpa, guguru ati dankua yii si ni awọn ololufẹ ere bọọlu to n se agbelarugẹ ẹgbẹ agbabọọlu Kwara United yii maa n fi panu.

Koda, ẹpa obinrin naa gbadun lẹnu wọn to bẹẹ, ti ko si ilu ti wọn kii mu obinrin naa lẹyin lọ.

Lasiko ti Kwara United wa gba bọọlu nilu Eko, Oluwatoyin tẹle wọn wa, nibi ti BBC Yoruba ti se alabapade rẹ.

Oluwatoyin Abdullahi to n ta ẹpa fun awọn ololufẹ Kwara United

"Awọn ọkunrin agbabọọlu kan lo pade mi, ti wọn si ni se mo le wa maa ta ẹpa fun awọn ni Stadium, bi mo se bẹrẹ niyẹn"

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Iya ẹlẹpa naa ni orukọ ti gbogbo eeyan mọ oun si ni iya ẹpa 1.

"Awọn ọkunrin agbabọọlu kan lo pade mi, ti wọn si ni se mo le wa maa ta ẹpa fun awọn, mo si ni bẹẹ ni.

Wọn ni to ba di ọjọ Satide, ki n gbe ẹpa wa si stadium, mo si gbe lọ.

Lati igba naa si ni mo ti maa n ta ẹpa fun wọn ni stadium, koda, ẹni to ba si ra ẹpa to pọ ju ni yoo ra ẹpa ati guguru ogun Naira.

Mo ti di nnkan kan naa pẹlu awọn agbabọọlu ati awọn elere idaraya miran to wa ni papa isere idaraya naa, ko si si ibi ti n kii tẹle wọn lọ.

Iya ẹlẹpaa

"Mo ti tẹle Kwara United lọ si Ibadan, Eko, Osogbo ati Akure, mo si ta ẹpa ati guguru daadaa"

Iya ẹlẹpaa naa tun tẹsiwaju pe oun maa n tẹlẹ ikọ agbabọọlu Kwara United kaakiri ilẹ Yoruba, lati se koriya fun wọn, ki n si tun ta ẹpa ati guguru.

"Mo ti tẹle wọn lọ si Ibadan, Eko, Osogbo ati Akure.

Mo gbọ pe wọn fẹ gba asekagba idije Federation Cup ni Eko, mo si bẹbẹ lati tẹle wọn lọ.

Inu mi dun nigba ti mo de Eko, mo ta ẹpa ati guguru daadaa, koda, ko to wọn jẹ, ti wọn si tun n beere si.

Mo jo, mo yọ nigba ti Kwara United yege ninu idije naa, inu mi dun pupọ."

Iya ẹlẹpaa

"Ọjọ ti inu mi dun julọ ni ọjọ ti gomina ati Yahaya Seriki fun mi lowo pe mo jẹ obinrin to ni akinkanju, mo si n sisẹ ati ololufẹ Kwara United"

Oluwatoyin Abdullahi wa gba awọn obinrin ẹgbẹ rẹ ni imọran, ati kekere ati agba, lati mura si isẹ, ki wọn ma ba a di obinrin olobinrin tabi wo oju oloju.

"Isẹ ni emi naa n se, mo mura si isẹ mi tori n ko fẹ ki awọn ọmọ mi di ọmọ ọlọmọ.

Mo si ti fi isẹ yii kọ awọn ọmọ mi nile ẹkọ, mo tun fi wọn sibi ẹkọsẹ, wọn kọ isẹ.

Ọjọ ti inu mi dun julọ ni ọjọ ti gomina ati Yahaya Seriki fun mi lowo pe mo jẹ obinrin to ni akinkanju, mo si n sisẹ ati ololufẹ Kwara United"