Àwọn wo ló ń dúnkokò mọ́ Iyabo Ojo tó ṣe ń lọgun pé inú ewu ni òun àti ìdílé òun wà, wọ́n fẹ́ gbẹ̀mí òun ?

Iyabo Ojo ati awọn to n dunkoko mọ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà Iyabo Ojo ti ké gbàjarè síta pé àwọn kan ń dúnkokò mọ́ ẹ̀mí òun nítorí ìgbìyànjú òun láti bèèrè fún ìwádìí sí ikú òjijì tó pa akọrin tàkasúfèé nnì, Ilerioluwa Aloba tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Mohbad.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Iyabo Ojo fi sí ìkànnì Instagram rẹ̀ lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Keje, ọdún 2025 ló ti ṣàlàyé àwọn nǹkan tó ti ń là kójá lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta báyìí, tó sì ní pé àwọn kan ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ìkọlù sí òun.

Ó ṣàlàyé pé ní àìpẹ́ yìí ni ẹ̀ka tó ń rí sí ìwà ọ̀daràn ní iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tó wà ní ìlú Abuja ránṣẹ́ pe òun lórí ẹ̀sùn tí èèyàn kan fi kan òun lórí fídíò kan tí òun ṣe nígbà tí ikú Mohbad ń jà rànìnrànìn.

Ó ní ohun tí wọ́n pe òun fún nígbà náà dá lórí àwọn nǹkan tí òun sọ nínú fídíò náà.

"Mo ṣe fídíò láti fọ ara mọ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni, n kò sọ pé àwọn èèyàn kan ló ṣokùnfà ikú Mohbad"

"Kìí ṣe ohun tuntun mọ́ pé ẹ̀ka tó ń rí sí ìwà ọ̀daràn lórí ayélujára ní iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìlú Abuja ránṣẹ́ pè mí láìpẹ́ lórí ẹ̀sùn tó níṣe pẹ̀lú ṣíṣe ìbàjẹ́ èèyàn lórí ayélujára nínú fídíò kan tí mo ṣe lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn.

"Nínú fídíò náà ni mo ti sọ pé káwọn èèyàn lọ fi ara wọn kalẹ̀ fún ìwádìí láti ṣe àfọ̀mọ́ ara wọn lórí ikú òjijì tó pa Mohbad."

Iyabo Ojo sọ pé òun ṣe fídíò náà láti sọ fún àwọn èèyàn náà láti fọ ara mọ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni àti pé òun kò sọ pé àwọn èèyàn náà ló ṣokùnfà ikú Mohbad.

Ó fi kun pé nítorí náà ni òun ṣe lo àjọ ẹlẹ́yinjú àánú òun ìyẹn Pinkies Foundation láti fi kọ̀wé ránṣẹ́ sí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, àtàwọn àjọ tí ọ̀rọ̀ kàn láti ṣèwádìí tó lòòrìn sí ohun tó ṣokùnfà ikú Mohbad.

"Gbogbo ìgbésẹ̀ tí mo gbé yìí jẹ́ àfihàn pé mi ò nàka pé èèyàn kan ní pàtó ló pa Mohbad, bí bẹ́ẹ̀kọ́, mi ò ní gbé ìgbésẹ̀ òfin tí mo gbé."

Gbajúmọ̀ òṣèré náà kọminú pé pẹ̀lú gbogbo bí òun ṣe làkàkà láti ri pé ìgbésẹ̀ òun wà lábẹ́ òfin, ó sọ pé àwọn èèyàn kan ń pè fún ikú òun, bá nǹkan tí òun fi ń ṣe ọrọ̀ ajé jẹ́, tí wọ́n sì ń dúnkokò mọ́ ẹ̀mí òun àti ti àwọn ọmọ òun.

Ó tẹ̀síwájú pé ṣáájú ìgbéyàwò ọmọ òun ní orílẹ̀ èdè Tanzania ni wọ́n fi lẹ́tà ìdúnkokò kan ránṣẹ́ sí òun pé kí òun múra sílẹ̀ fún àwọn nǹkan aburú tó máa ṣẹlẹ̀ sí òun láàárín oṣù mẹ́ta.

Ó ní èyí kò jẹ́ kó ya òun lẹ́nu nígbà tí òun rí àwọn èèyàn kan tí wọ́n ń gbé pósí kiri lórí ayélujára pẹ̀lú orúkọ òun lára rẹ̀ tí wọ́n sì ń dúnkokò mọ́ ẹ̀mí àti àwọn ohun ìní òun léyìí tó ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé inú ewu ni òun wà.

Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Iyabo Ojo/Instagram

"Mo gbàgbọ́ pé Ọlọ́run máa gbé mi borí gbogbo ìṣòro yìí"

Iyabo Ojo tún sọ pé òun mọ̀ dájú pé ṣíṣe àtìlẹyìn fún ẹgbẹ́ òṣèlú kan lásìkò ètò ìdìbò tó kọjá ti mú káwọn èèyàn kan máa ṣe ìkọlù sí òun.

Ó ní pẹ̀lú gbogbo ìlàkàkà yìí, òun gbàgbọ́ pé Ọlọ́run máa gbé òun borí gbogbo ìṣòro yìí àti pé òun mọ̀ pé bí òun ṣe máa ń pè fún ìdájọ́ òdodo lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ ti jẹ́ kí òun ní ọ̀tá tó pọ̀.

Ó fi kun pé òun ṣetán láti tún jẹ́ àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n bá tún ránṣẹ́ pé òun lórí ìwádìí tó ń lọ lọ́wọ́ láì sí ìbẹ̀rù kankan.

Bákan náà ló rọ àwọn èèyàn láti fún òun láàyè láti ṣọ̀fọ̀ ilé ìtajà òun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jóná, kí òun tọ́jú ara òun pẹ̀lú gbogbo nǹkan tí wọ́n ń gbé jáde lórí ayélujára.

Àwòrán lẹ́tà tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Priscilla Ojo/Instagram

Àwọn ọ̀nà wo ni wọ́n fi ń dúnkokò mọ́ Iyabo Ojo?

Nínú fídíò kan tí Iyabo Ojo fi sórí ìkànnì Instagram rẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun ló ti kéde pé ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Keje, ọdún 2025 ni ìjàmbá iná ṣọṣẹ́ ní ilé òun.

Iyabo Ojo sọ pé òun dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò mú ẹ̀mí èèyàn kankan lọ.

Lẹ́yìn náà ni ọmọ rẹ̀ Priscilla Ojo gbé lẹ́tà ìdúnkokò kan jáde, tó ní wọ́n fi ránṣẹ́ sí ilé ìtajà tó jóná náà ṣáájú ìgbéyàwó òun.

Ó ní àwọn fi lẹ́tà náà pamọ́ kí ìyá òun má ri títí tí ìgbéyàwó náà fi parí.

Yàtọ̀ sí èyí, ní àná ni fídíò kan gba orí ayélujára níbi tí àwọn kan ti gbé àwòrán Iyabo Ojo, ìyàwó Mohbad àti Mohbad dání tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ òdì sí Iyabo Ojo.

Ohun táwọn èèyàn náà ń sọ ni pé wọ́n kò jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo wáyé lórí ikú Mohbad.

Awọn ti wọn fura si pe o n dun ikoko mọ Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àwọn akẹgbẹ́ Iyabo Ojo kan sáárá si

Ọ̀pọ̀ àwọn akẹgbẹ́ Iyabo Ojo ló ti ń ba kẹ́dùn lórí àwọn ìlàkàkà tó là kọjá tí ọ̀pọ̀ wọn sì ń sọ pé ìdí táwọn gbajúmọ̀ kìí ṣe fẹ́ dá sí ọ̀rọ̀ tó bá ń lọ ní àwùjọ rèé.

Chioma sọ pé òun ní ìgbàgbọ́ pé Iyabo Ojo kò ṣe ohun tó burú nípa jíjà fún ìdájọ́ òdodo àti bó ṣe sọ̀rọ̀ sí ọ̀pọ̀ fídíò tó gba orí ayélujára nígbà náà.

Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ní ikú Mohbad ká lára, tí ọ̀pọ̀ sì sọ̀rọ̀ lórí rẹ̀, tí òun kò sì mọ ìdí tí wọ́n fi da Iyabo Ojo yọ láti máa dúnkokò mọ.

Ó fi kun pé àwọn wà lẹ́yìn Iyabo Ojo, táwọn yóò sì dúró tìí títí gbogbo ìpèníjà yìí fi máa kọjá.

Òṣèré Biodun Okeowo ní tirẹ̀ ní àwọn èèyàn kan máa ń ṣẹnu lásán nip é òun gbàgbọ́ pé Ọlọ́run tó le gbe ìjà ẹ̀dá máa gbe ìjà Iyabo Ojo jà.

Àkọlé fídíò, "Ogún ọdún rèé tí mo ti ń ta ẹ̀pà, gúgúrú àti dáńkúà fáwọn olólùfẹ̀ẹ́ bọ́ọ́lù, kò sí ìlú tí ń kìí tẹ̀lé wọn lọ"

Ìjàmbá iná ṣọṣẹ́ ní ilé ìtajà Iyabo Ojo, ọ̀pọ̀ èèyàn ń bá a kẹ́dùn

Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Keje, ọdún 2025 ni ìjàmbá iná ṣọṣẹ́ ní ilé ìtajà gbajúmọ̀ òṣèré tíátà nnì, Iyabo Ojo.

Nínú fídíò kan tí òṣèré náà fi sórí ìkànnì Insatgram rẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun ló ti kéde ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Iyabo Ojo nínú ìròyìn náà sọ pé òun dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò mú ẹ̀mí èèyàn kankan lọ.

Nínú fídíò náà ló ti ṣàfihàn àwọn nǹkan tó jóná bíi àga, ògiri dúdú, àwọn gíláàsì ojú fèrèsé tó fọ́ kù níbi ìjàmbá náà.

"Ní òní ni èyí ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bíi aago méje ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Keje, ọdún 2025. Ọ́fíìsì mi jóná," ó kọ sójú òpó Instagram rẹ̀.

Aga to jona

Oríṣun àwòrán, iyaboojofespris/nstagram

"Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ iléeṣẹ́ panápaná Nàìjíríà àtàwọn òṣìṣẹ́ mi fún dídá ààbò bo àwọn nǹkan tó ṣẹ́kù"

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwòrán ọkọ̀ iléeṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Eko ló wà nínú fídíò tí Iyabo Ojo fi léde náà, ó kan sáárá sí iléeṣẹ́ panápaná Nàìjíríà fún bí wọ́n tètè jí gììrì sí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.

Ó ní ipa àwọn panápaná náà jẹ́ kí àwọn rí àwọn nǹkan díẹ̀díẹ̀ rí mú níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Bákan náà ló fi kun pé ẹ̀mí kankan kò bá ìjámbà náà lọ.

"Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ iléeṣẹ́ panápaná Nàìjíríà àtàwọn òṣìṣẹ́ mi fún dídá ààbò bo àwọn nǹkan tó ṣẹ́kù.

Mo dúpẹ́ pé kò sí ẹnikẹ́ni tó kú nínú ìjàmbá náà."

Nígbà tó ń júwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí àdánwò ìgbàgbọ́ rẹ̀, ó kọ pé "Èṣù gbìyànjú láti dán ìgbàgbọ́ waw ò lónìí àmọ́ Ọlọ́run sọ pé rárá. Mo gbàgbọ́ pé pẹ̀lú Ọlọ́run, mo máa padà sípò lọ́nà tó tóbi tó sì dára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ."

Àgbà òṣèré náà kò sọ ohun tó ṣokùnfà ìjàmbá iná náà àti irú ọṣẹ́ tí ìjàmbá iná náà ṣe sí ilé ìtajà rẹ̀.

Ẹ ó rántí pé nínú oṣù Kejìlá ọdún tó kójá ni òṣèré Mercy Aigbe náà kojú ìjàmbá iná nígbà tí ilé ìgbé rẹ̀ jóná.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Aga to jona

Oríṣun àwòrán, iyaboojofespris/nstagram

Àwọn èèyàn ń bá Iyabo Ojo kẹ́dùn

Lẹ́yìn tí Iyabo Ojo gbé fídíò náà jáde ni àwọn èèyàn pàápàá àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ lágbo eré tíátà ti ń ba kẹ́dùn lórí àdánù náà.

Òṣèré Liz da Silva kọ sábẹ́ fídíò náà pé òun kò mọ nǹkan tí òun le sọ àmọ́ ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ààbò ẹ̀mí.

Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ pé ilé ọba tó jó, ẹwà ló máa fi bù kun ni ọ̀rọ̀ náà máa já sí fún Iyabo Ojo.

Yinka Quadri ni tirẹ̀ sọ pé ọwọ́ Ọlọ́run ni gbogbo ògo wà àti pé kí Iyabo Ojo ṣe ọkàn gírí.

"Jesuuuu! Pẹ̀lẹ́, Ọlọ́run ọba á dúró tì ọ́ ní orúkọ Jésù," òṣèré Toyin Adewale kọ.

Kunle Afod ní ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run àti pé gbogbo ipò tí èèyàn bá ti bá ara rẹ̀, ọpẹ́ ló yẹ.

Àwọn òṣèré míì tó tún bá Iyabo Ojo kẹ́dùn ni Mercy Aigbe, Tawa Ajisefini, Wunmi Ajiboye, Funke Etti, Funmi Awelewa àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Iyabo Ojo/Instagram

Ta ni Iyabo Ojo?

Gbajúmọ̀ lágbo eré tíátà Yorùbá ni Iyabo Ojo tó máa ń kópa òṣèré, adarí eré àti olùgbé eré jáde.

Ní ọdún 1998 ló darapọ̀ mọ́ eré sinimá pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àgbà òṣèré Bimbo Akintola.

Ọmọ ìlú Abeokuta ní ìpínlẹ̀ Ogun ni Iyabo Ojo àmọ́ ìpínlẹ̀ Eko ló gbé ní gbogbo ayé rẹ̀.

Ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kejìlá ọdún 1977 ni wọ́n bí Iyabo Ojo tó sì ti pé ẹni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta báyìí.

Iyabo Ojo ní àsìkò tí wọ́n gba òun sí ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Unilag láti kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ òfin ni òun ri pé òun ti lóyún àkọ́bi.

Ó ní èyí mú kí òun sinmi fún eré sinimá lọ́dún 1999 kó tó padà sí agbo eré lọ́dún 2002.

Ó ti kópa nínú sinimá tó ti lé ní àádọ́jọ tó sì ti gba àmì ẹ̀yẹ lọ́kan-ò-jọ̀kan fún àwọn ipa rẹ̀ nínú eré.

Lára àwọn sinimá tó ti kópa ni Satanic, Baba Darijinwon, Silence, Labake Olododo àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Iyabo Ojo bí ọmọ méjì – Priscilla Ojo àti Festus Ojo.