Moji Afolayan: Ọ̀pọ̀ àwọn alágbàtà fíìmù ló máa ń bèèrè ìbálòpọ̀ lọ́wọ́ obìnrin, kí wọ́n tó lò wọ́n nínú eré láti di olókìkí

Moji Afolayan

Oríṣun àwòrán, Moji Afolayan/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gbájumọ̀ òṣeré tíátà, Mojirola Afolayan tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Moji Afolayan Olayiwola ti sọ̀rọ̀ lórí ìdí tí kò fi sábà kópa nínú eré mọ́.

Moji Afolayan, nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan ṣe tó ṣe lórí ètò Oyinmomo tí Kazeem Aderounmu ṣe atọ́kùn rẹ̀, sọ pé kìí ṣe ọkọ òun ni kò jẹ́ kí òun kópa nínú eré mọ́ bíkòṣe pé òun kọ̀ láti hu àwọn ìwà kò tọ́.

Láti bíi ọdún díẹ̀ sẹ́yìn ni Moji Afolayan kó ti sábà kópa nínú eré mọ́ kó tó di pé ó kópa nínú Anikulapo tí Kunle Afolayan ṣe.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì máa ń wádìí ìdí tí wọn kò fi ri lójú àwòrán mọ́.

Ó sọ pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní dẹ́yẹ sí òun nítorí pé òun kọ̀ láti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn kan lágbo eré tíátà.

"Nítorí pé mi ò ṣe é, wọ́n máa pe ìpàdé láàárín ara wọn, wọn kò ní pè mí si."

Nítorí mo kọ̀ láti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbàtà eré ni wọ́n ṣe dẹ́yẹ sí mi - Moji Afolayan

Moji Afolayan, tó jẹ́ ìyàwó àgbà òṣeré míì, Rasaq Olayiwola tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Ojopagogo, sọ pé pẹ̀lú bí ọkọ òun ṣe jẹ́ onítíátà, wọ́n ṣì máa ń fi ìbálòpọ̀ lọ òun láì bìkítà ipò rẹ̀.

Ó fẹ̀sùn kàn pé ọ̀pọ̀ àwọn alágbàtà fíìmù ló máa ń bèèrè ìbálòpọ̀ lọ́wọ́ àwọn onìnrin kí wọ́n lè máa lò wọ́n nínú eré àti pé kí wọ́n lè ba à sọ wọ́n di olókìkí.

Ó ní òun dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún bí òun ṣe kó ara òun ní ìjánu nígbà náà nítorí pé òun jèrè rẹ̀ báyìí.

Ó wòye pé ọ̀pọ̀ ló ní jìn sí ọ̀fin nígbà náà nítorí èròńgbà láti di ìlúmọ̀ọ́ká tó sì jẹ́ pé gbogbo àwọn ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé nígbà náà ló padà ń dùn wọ́n báyìí.

"Wọ́n ń gbé wọn nígbà náà, tí wọ́n ń fi ojú wọn hàn nínú àwọn àwòrán eré àmọ́ níṣe ni wọ́n ń ka gbogbo àwọn tí wọ́n ti bá sùn fún àwọn ọmọ tó ń bọ̀ lẹ́yìn."

Moji Afolayan

Oríṣun àwòrán, Moji Afolayan/Instagram

Báwo ni Moji Afolayan ṣe bẹ̀rẹ̀ eré tíátà?

Moji Afolayan ṣàlàyé pé ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ iṣẹ́ tíátà kìí ṣe iṣẹ́ tó wu òun lọ́kàn rárá tó sì jẹ́ pé iṣẹ́ akọ̀ròyìn àti akàròyìn ló wu òun.

Ó ní kódà bàbá òun mọ̀ pé iṣẹ́ náà kò wu òun rárá àmọ́ ohun tí Ọlọ́run ba ti kọ mọ́ èèyàn dandan kó wá sí ìmúṣẹ.

Ó fi kun pé tipátipá ni bàbá òun fi ti òun bọ eré sinimá kó tó di pé òun wá bẹ̀rẹ̀ sí ní ní ìfẹ́ eré sinimá.

Ó sọ pé ọdún 1985 ni òun kọ́kọ́ kópa nínú eré sinimá èyí tí bàbá òun ṣe, ti wọ́n gbé lọ sílé sinimá nígbà náà àti pé ọ̀dọ̀ bàbá òun ni òun ti kọ́ nípa eré ṣíṣe.

Àgbà òṣèré náà sọ pé lẹ́yìn náà ni òun wá ń kópa nínú àwọn eré èyí tí wọ́n tà fún àwọn alágbàtà eré.

"Lẹ́yìn ìgbà náà ni mo ba Jide Kosoko ṣeṣé ní 1999, mo bá Fali Werepe ṣe Igbese, láti ibẹ̀ lọ ni Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbémi sókè."

Ipa bàbá rẹ̀, Ade-Love nínú ìgbé ayé rẹ̀

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa bàbá rẹ̀, Adeyemi Afolayan, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Ade-Love, Moji Afolayan tó jẹ́ àkọ́bí bàbá rẹ̀ sọ pé, bàbá dada ni fún àwọn nígbà ayé rẹ̀.

O ni ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń pọn àwọn lé, tí wọ́n sì máa ń ṣe dada sí àwọn nítorí bàbá àwọn, títí di àsìkò yìí.

Lórí ikú bàbá rẹ̀z, Adeyemi Afolayan ó ṣàlàyé pé ìlú Agbamu ní ìpínlẹ̀ Kwara tó jẹ́ ìlú abínibí àwọn, ni àwọn wà gẹ́gẹ́ bí ìṣe ní ọdọọdún láti ṣayẹyẹ Kérésìmesì àti ọdún tuntun, kí bábá òun tó bẹ̀rẹ̀ àárẹ̀.

Ó ní àárẹ̀ yẹn ló mú àwọn gbé bàbá òun wá sí Eko fún ìtọ́jú ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé ikú wọn ni àwọn gbọ́ ní ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù Kejìlá, ọdún 1996.

Ó sọ pé inú ọ̀fọ̀ gidi ni gbogbo ìdílé àwọn wà lọ́dún 1997 nítorí ikú bàbá òun.

Ojopagogo ati aya rẹ, Moji Afolayan

Oríṣun àwòrán, Ojopagogo/Instagram

Ìgbéyàwó òun àti Ojopagogo

Moji Afolayan sọ pé oko eré sinimá ni òun àti ọkọ̀ òun ti pàdé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò ní èrò láti fẹ́ òṣèré.

Ó ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ ogun ló dìde sáwọn níbẹ̀rẹ̀ nítorí ẹ̀sìn àwọn tó yàtọ̀ àmọ́ tí àwọn fi sùúrù àti ìfaradà to ìdílé àwọn.

Ó ní ó máa ń ba òun lọ́kàn jẹ́ tí òun bá ń wo bí ìgbéyàwó ṣe ń túká lóde òní tó sì gba àwọn tọkọtaya lámọ̀ràn láti máa ní ìfaradà, ìfẹ́ àti àmúmọ́ra láti to ìdílé wọn.

Ó fi kun pé ìgbéyàwó kìí ṣe ohun tó rọrùn ní tòótọ́ àmọ́ tó gba ẹ̀kọ́, tó sì gba èro.

Ta ni Moji Afolayan?

Moji Afolayan

Oríṣun àwòrán, Moji Afolayan/Instagram

Ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kejì, ọdún 1968 ni wọ́n bí Moji Afolayan sínú ìdílé Adeyemi Afolayan tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Ade-Love.

Òun ni àkọ́bí bàbá rẹ̀ tó sì gbajúmọ̀ fún ẹwà rẹ̀ lágbo eré sinimá.

Ọmọ bíbí ìlú Agbamu ní ìpínlẹ̀ Kwara ni àmọ́ ìpínlẹ̀ Eko ló gbé dàgbà.

Moji Afolayan lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, Coker Primary School, ní ìpínlẹ̀, tó sì tẹ̀síwájú lọ sí ilé ẹ̀kọ́ girama Esie Iludun Aglican Grammar School.

Lẹ́yìn náà ló lọ sí ilé ẹ̀kọ́ olùkọ́ni ti ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo.

Moji Afolayan bẹ̀rẹ̀ eré sinimá lọ́dún 1985 tó sì ti kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré.

Òun ni ẹ̀gbọ́n Kunle Afolayan, Aremu Afolayan àti Gabriel Afolayan.

Ó ṣe ìgbeyàwó pẹ̀lú akẹgbẹ́ rẹ̀ míì, Rasaq Olayiwola tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Ojopagogo.