Ìdí tí ẹgbẹ́ tó ń rí si ọ̀rọ̀ ilẹ̀ Africa àti àwọn alátìlẹyìn Ibrahim Traore fi kéde ìdìtẹ̀gbàjọba òfegè

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Chiagozie Nwonwu, Mungai Ngige, and Olaronke Alo
- Role, BBC Global Disinformation Unit
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Mafalda Marchioro ji gba atẹjisẹ lati ọdọ awọn ọrẹ rẹ to n gbe loke okun, ti wọn si n bi pe ṣe o wa ni alaafia ni Abidjan, ilu to tobi ju lorilẹede Ivory Coast.
Opo ayelujara lo n gbe iroyin pe iditẹgbajọba waye.
Ọpọ fọnran lo kun ori ayelujara to n ṣafihan awọn ọmọ ologun ti wọn yapa loju titi; ti fọnran ti wọn fi AI sẹda si ni ọpọ milọnu eeyan to wo lori opo ayelujara, Youtube.
"O n kọmi lominu, mo ro pe nnkan sẹlẹ ni," awọn alaṣẹ sọ fun BBC.
Ṣugbọn iroyin nipa iditẹgbajọba lo jẹ irọ to jina si otitọ.
Ọpọ iroyin ofege lo n lọ kiri pe iditẹgbajọba n waye ni iwọ oorun Afrika, ti ọpọ ifoya si n lekun ni agbegbe to ti foju ri ọpọ iditẹgbajọba, ti awọn ologun ti gba ijọba lemọlemọ ri.
Ivory Coast, jẹ orilẹede kan to n sọ ede Faranse, to si ni ajọsepọ pẹlu oke okun, tie to idibo rẹ yoo si waye lọdun yii.
Awọn amoye gbagbọ pe iroyin ofege lo ṣeeṣe ko jẹyọ nitori eto idibo to fẹ waye.
Eyi nitori bi Aarẹ Ivory Coast, Alassane Ouatarra, ṣe n beere fun ṣaa kẹrin, ti ọpọ si n fẹsun kan pe o n siṣẹ papọ pẹlu ijọba oke okun, ti wọn si n jọ ko ohun alumọni orilẹede naa lọ oke okun.
Minisita fun eto ibaraẹnisọrọ Ivory Coast, Amadou Coulibaly sọ fun BBC pe awọn ti ṣawari orison iroyin ofege, to si jẹ orilẹede kan to sumọ ṣugbọn wọn ko ti fi di rẹ mulẹ.
Iroyin ofege yii ni wọn ni o wa lati orilẹede Burkina Faso, ti ọpọ eeyan si gbe iroyin naa larugẹ.
Wọn ni ajọsepọ nla pẹlu Russia ati awọn orilẹede kan ni ilẹ Afrika bi Nigeria, Ghana, Kenya ati South Africa.
Awọn to n ṣe igbelarugẹ yii ni wọn n se igbelarugẹ fun Aarẹ ologun Burkina Fas, Capt Ibrahim Traoré, ẹni to ditẹgbajọba lọdun 2022.
Traoré ṣafihan ara rẹ gẹgẹ bii ajafẹtọ ominira ilẹ Afrika, ti ọpọ ọdọ si n ṣe atilẹyin fun kaakiri ilẹ Afrika, ti wọn si ri gẹgẹ bii olori to n ja fun ilẹ Afrika.

Oríṣun àwòrán, Youtube
Alex Vines, oludari Africa Programme at Chatham House think tank, ni awọn to n ṣe igbelarugẹ iditẹgbajọba yii n ṣe eyi lati fopin si iṣejọba ẹgbẹ oṣelu, ti wọn si n pin iroyin ofege pe iditẹgbajọba waye lati fi igboya si ọkan awọn eeyan.
"Wọn wa awọn eeyan to fẹ ka nipa awọn olori ilẹ Afrika, ti wọn n ja fun alaafia ati ilọsiwaju," o ṣo fun BBC.
Ṣe loootọ ni Burkina Faso lọwọ ninu iroyin iditẹgbajọba ni Ivory Coast?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ko si ẹri kankan to fi idi eyi mulẹ pe orilẹede Burkina Faso lọwọ ninu iroyin iditẹgbajọba Ivory Coast ṣugbọn ọpọ eeyan lo gbe ara le iroyin naa.
Ajọsepọ to wa laaarin Burkina Faso ati Ivory Coast ko dan mọran fun igba diẹ bayii. Eyi waye nigba ti Traoré fẹsun kan Ivory Coast pe wọn n fiya gba awọn agbebọn lati wọle si ilu wọn.
Ninu oṣu kẹrin, minisita fun eto aabo ni Burkina Faso fẹsun kan awọn kan to n gbero iditẹgbajọba ti wọn w ani Ivory Coast pe wọn fẹ gba ijọba lọwọ Traoré.

Ẹka BBC to n koju iroyin ofege ṣawadi lori awọn fọnran ti wọn ri lori opo ayelujara TikTok, Facebook, X ati YouTube – ti wọn si ri fọnran kan ti ọkunrin kan to n jẹ Harouna Sawadogo, ajafẹtọ lati Burkina Faso gbe sita lọjọ kọkandinlogun oṣu Karun un, ti gbogbo fọnran to wa loju opo rẹ si jẹ ti Capt Traoré.
Eeyan miiran to tun gbe iroyin ofege yii ni Ọmọ orilẹede South Africa ti wọn bi si orilẹede Turkey, Mehmet Vefa Dag, ẹni to ṣe olori fun ẹgbẹ Truth and Solidarity Movement - ẹgbẹ kan lorilẹede South Africa.
Ọpọ igba lo n gbe fọnran sita loju opo ayelujara rẹ, to si ṣe ajọyọ lori nnkan to pe ni 'Iditẹgbajọba ara ile'.
Koda arakunrin Dag, ẹni ti ọpọ tib u ẹnu atẹlu lori ọrọ rẹ si awọn ijọ Jews and LGBTQ+, ni o ti n pe fun idiẹgbajọba ni orilẹede Ivory Coast ni ọjọ Kọkanla oṣu Karun un.
Nigba ti BBC kan si pe ko si idiẹgbajọba, o tẹni mọ pe iditẹgbajọba ti waye.
"Ohun iwuri lo jẹ fun wa ati ẹni to gba ijọba lọwọ Quattara. O ti ta ẹmi rẹ fun oyinbo, to si fẹ ba orilẹede Burkina Faso, Mali ati Niger, jẹ" o sọ.
"Gẹgẹ bii ajafẹtọ ilẹ Afrika, a ko le fun wọn ni aye mọ. A ma ja fun orilẹede wa. Ilẹ wa ree."

Oríṣun àwòrán, Tiktok












