"Iye èèyàn tí àwọn agbébọn pa tàbí jí gbé, lóṣù mẹ́fà àkọ́kọ́ ọdún 2025 pọ ju ti 2024 lọ"

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ kan to n ri si ẹtọ ọmọniyan ni Naijiria ti fidi ẹ mulẹ pe eeyan to ti padanu ẹmi wọn loṣu mẹfa akọkọ ọdun yii pọ ju ti esin lọ.
Eeyan 2, 266 lo ti ku ninu ikọlu awọn agbebọn ni abala akọkọ ọdun 2025 yii, gẹgẹ bi ajọ ajafẹtọọ ẹni (The Nigerian Human Rights Commission) ṣe sọ.
Bẹẹ ni iwoyi ọdun 2024, eeyan 2,194 ni wọn pa.
Bi eyi ṣe n waye ni awọn ologun Naijiria naa n gbiyanju lati ṣẹgun awọn Boko Haram to n ṣọṣẹ ni Ariwa-Iwọ-Oorun Naijiria.
Bakan naa ni wọn n koju ija awọn agbẹ ati awọn darandaran ni Aarin Gbungbun Ariwa, ati awọn to n pe fun iyapa Naijiria lapa Ila-Oorun orilẹede yii.
Akọsilẹ sọ pe eeyan ẹgbẹta le mẹfa (606) ni wọn pa laaarin oṣu to kọja, paapaa ni abule Yelwata ati Dauda, nipinlẹ Benue.
Alaga Nigerian Human Rights Commission, Tony Ojukwu, pe fun amojuto to yẹ lori ikọlu to n mu onka iku pọ si i yii.
"Obi awọn kan lo padanu ẹmi yii, ọmọ awọn kan ni wọn. Olori ẹbi ẹlomi-in ninu wọn si ti ba ogun lọ bayii.
"Ọna atijẹ awọn kan ti di patapata, ọjọ iwaju awọn ẹlomi-in ti bajẹ lori ikọlu, awọn kan si wa ti wọn o ri ẹbi wọn mọ rara."
Ojukwu lo ṣalaye bẹẹ.
'Èèyàn 857 ni wọ́n jí gbé lóṣù mẹ́fa àkọ́kọ́ òdún 2025'
Nipa ijinigbe to waye loṣu mẹfa akọkọ ọdun 2025, ajọ naa ṣalaye pe eeyan 857 ni wọn bọ soko ajinigbe ni Naijiria.
Wọn ni eyi dinku si 1, 461 ti wọn ji gbe loṣu mẹfa akọkọ ọdun 2024.
Atẹjade The Nigerian Human Rights Commission tun sọ pe awọn agbebọn naa n kọlu awọn ṣọja Naijiria.
Wọn fi kun un pe o le ni ṣọja mẹtadinlogun to ba ikọlu awọn agbesunmọmi lọ ni Kaduna ati ipinlẹ Niger.
Ogoji ẹṣọ alaabo ni wọn kede pe o padanu ẹmi nipinlẹ Zamfara, lapa Ariwa-Iwọ-Oorun.
Ìṣòro tó ń kojú àwón ológun Naijiria
Ọmọwe Kabiru Adamu, onimọ nipa aabo, ṣalaye awọn ohun to n dena aṣeyọri awọn ṣọja Naijiria.
O ni o han pe iṣoro wa fun awọn ṣọja yii, wọn si gbọdọ yanju rẹ bi wọn ba fẹẹ bori awọn apaayan naa.
Wọnyi ni awọn iṣoro ti Ọmọwe Adamu sọ pe o n koju awọn ṣọja Naijiria
Aito ṣọja: Ọkan lara awọn iṣoro naa bo ṣe wi ni aito ṣọja.
Ọmọwe Adamu sọ pe iṣoro aabo Naijiria ti fẹju toto, ṣugbọn apapọ ṣọja Naijiria ko to 230,000.
Aito nnkan ija: Awọn irinṣẹ to kaju ẹ ati nnkan ija igbalode ni Ọmọwe Adamu sọ pe wọn fi n koju ogun awọn agbesunmọmi, alakatakiti ati awọn to n beere fun iyapa kuro ni Naijiria.
Aito tabi aisi awọn nnkan ija naa n ṣakoba.
Ai si iwuri fun awọn ologun: Bi ko ṣe si abojuto to peye fun igbaye-gbadun awọn ologun, jẹ iṣoro nla.
Ọmọwe Adamu sọ pe, "iru owo oṣu ti wọn n san fun wọn, ile ti wọn n gbe ati awọn nnkan bayii nilo agbeyẹwo gidi"
Ai si ifọwọsowọpọ araalu: Ọna tawọn ologun maa n gbe iwadii wọn gba, eyi to maa n ko inira ba araalu, ti mu wọn padanu ifọwọsowọpọ awọn eeyan.
Ọmọwe Adamu sọ pe eyi ri bẹẹ pẹlu bi awọn ologun ṣe maa n ti ọja pa nigba mi-in ti wọn ba fẹẹ ṣe iṣẹ iwadii.
O ni ọna to n di araalu lọwọ ti wọn n gba ṣiṣẹ wọn ki I jẹ ki araalu ti wọn lẹyin, ifasẹyin si ni eyi jẹ fun wọn.
Ai kuro loju kan: Ofin iṣẹ ṣọja ni pe ọmọ ogun kan ko le wa nibi kan titi, wọn gbọdọ ṣi I nipo pada ni awọn asiko kan, ṣugbọn ti Naijiria yii ko ri bẹẹ.
O ni ṣọja kan le wa nibudo kan fun ọdun gbọọrọ ni Naijiria.
Iwa ibajẹ, kiko owo ijọba mi
Ọmọwe Adamu sọ pe aimọye ẹsun ṣiṣe owo mọkumọku laaarin awọn ṣọja ilẹ wa. "Awọn ajọ bii CISLAC ati Transparency International, ti ṣe iwadii awọn ologun Naijiria.
" Àbọ̀ iwadii naa ni pe awọn ọga ṣọja kan ti kowo ileeṣẹ ologun Naijiria mi.
Ọmọwe Adamu sọ pe paapaa labala nnkan ija ti wọn maa n sọ pe awọn ra, eyi ti wọn fi n kowo si apo ara wọn bo ṣe sọ.














