Wo iye máàkì tí akẹ́kọ̀ọ́ fi ń wọlé sí fásitì ní ọdún márùn-ún sẹ́yìn àti ìdí tí JAMB fi kéde 150, bíi gbèdéke máàkì láti wọlé sí fásítì ní 2025

Aworan awọn akẹkọọ to n ṣe idanwo

Oríṣun àwòrán, JAMB/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ JAMB to n ri si wiwọle awọn akẹkọọ sile ẹkọ giga fasiti atawọn ile ẹkọ giga mii ni Naijiria ti kede ''150'' gẹgẹ bii maaki to kere julọ ti akẹkọọ to ba fẹ wọ fasiti gbodọ gba ninu idanwo JAMB ọdun yii.

Ajọ JAMB fọrọ yii lede loju opo X rẹ lana ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹjọ oṣu Keje yii.

JAMB ṣe ikede naa lẹyin ipade ti wọn ṣe niluu Abuja pẹlu awọn ọga agba awọn ile ẹkọ fasiti atawọn ile ẹkọ giga mii ni Naijiria.

Nibi ipade ọhun ni wọn ti fẹnu ko wi pe maaki ''100'' ni maaki to kere julọ ti akẹkọọ to ba fẹ wọ ile ẹkọ gbogbonṣe ati ile ẹkọ giga fawọn olukọ ni lati gba.

Nibi ipade ọhun naa ni wọn tun ti fẹnu ko wi pe maaki ''140'' lawọn akẹkọọ to ba fẹ wọ ile ẹkọ giga ikẹkọọ nọọsi gbọdọ gba ninu idanwo JAMB ọdun yii.

Eyi tumọ si pe ko si ile ẹkọ giga to gbọdọ gba akẹkọọ ti ko ba gba to maaki 150 si ile ẹkọ fasiti kankan ni Naijiria lọdun yii.

Amọ, awọn ile ẹkọ giga mii si le jẹ ki maaki tawọn akẹkọọ gbọdọ gba lati wọle si fasiti ju 150 ti ajọ JAMB kede lọ.

Idi ti JAMB fi kede 150 gẹgẹ maaki ati wọle si fasiti

Gbogbo awọn ọga agba ile ẹkọ giga fasiti ni Naijiria atawọn ile ẹjọ giga mii ni wọn dibo lori gbedeke maaki ti akẹkọọ gbọdọ gba lati wọle si ile ẹkọ giga nibi ipade ti wọn ṣe pẹlu JAMB niluu Abuja lọjọ Iṣẹgun.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn ọga agba ile ẹkọ giga fasiti dibo lori maaki ti yoo jẹ gbedeke tawọn akẹkọọ gbọdọ gba lati wọle si fasiti lọdun yii.

Awọn ọga agba ile ẹkọ giga gbogbonṣe ni Naijiria naa dibo lori gbedeke maaki tawọn akẹkọọ gbọdọ gba lati wọle sile ẹkọ Poli lọdun yii.

Bakan naa lawọn ọga agba ile ẹkọ giga ẹkọṣẹ iṣẹ olukọ dibo lori gbedeke maaki tawọn akẹkọọ gbọdọ gba lati wọle si ile ẹkọ naa.

Amọ, alakoso agba ajọ JAMB, Ọjọgbọn Ishaq Oloyede ati minisita eto ẹkọ ni Naijiria, Ọmọwe Tunji Alausa, dabaa nibi ipade naa wi pe ki wọn gbe gbedeke maaki ati wọle si fasiti ''160.''

Ṣugbọn ọpọ awọn ọga agba fasiti to wa nibi ipade ọhun tako aba yii.

Ọjọgbọn Ernest Izevbigie to jẹ ọga agba fasiti Michael Lawrence niluu Abuja dabaa maaki 140, nigba ti ọga agba fasiti Lighthouse ni tiẹ dabaa maaki 130.

Ọjọgbọn Ayodeji Agboola ti fasiti Olabisi Onabanjo ni tiẹ dabaa pe ki wọn fi 160 ṣe gbedeke maaki ati wọle si faiti lọdun yii.

Lẹyin ọpọlọpọ atotonu ni gbogbo wọn pada fẹnu ko lori maaki 150 gẹgẹ bii gbedeke maaki ti akẹkọọ to ba fẹ wọle si fasiti lọdun 2025 gbọdọ gba, nigba ti wọn wo bi ọpọ akẹkọọ ṣe fidirẹmi ninu idanwo JAMB ọdun yii.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Gbedeke maaki ti JAMB kede fawọn akẹkọọ to ba fẹ wọ ile ẹkọ fasiti lọdun marun sẹyin

Ọdun 2024 – maaki 140

Ọdun 2023 – maaki 140

Ọdun 2022 – maaki 140

Ọdun 2021 – maaki 160

Ọdun 2020 – maaki 160

''Ọmọ to ba fẹ wọ fasiti gbọdọ pe ọdun mẹrindinlogun bayii''

Ẹwẹ, minisita eto ẹkọ ni Naijiria, Ọmọwe Alausa, ti fidi rẹ mulẹ pe ọmọ to ba fẹ wọ ile ẹkọ giga fasiti gbọdọ to ọmọ ọdun mẹrindinlogun bayii.

Eyi tumọ si pe ijọba ti kuro lori ipinnu rẹ ti o kede lọdun to kọja wi pe ọmọ to ba fẹ wọ ile ẹkọ giga fasiti gbọdọ pe ọdun mejidinlogun ki o to le ṣe bẹẹ.

Ọpọ araalu ni wọn koro oju si igbesẹ yii nigba ti ijọba kede rẹ nigba naa.

Amọ, minisita eto ẹkọ ti wa sọ pe ijọba ti fẹnu ko bayii lori ọrọ naa nigba to kilọ pe ọmọ ti ko ba to ọdun mẹrindinlogun ko ni lanfaani lati wọ ile ẹkọ giga fasiti.

Ọmọwe Alausa tun fikun ọrọ re wi pe ile ẹkọ ti ko ba ni akọsilẹ igbawọle akẹkọọ lori itakun ayelujara CAPS ti lodi sofin.

Ọdun 2017 ni ajọ JAMB ṣe agbekalẹ itakun CAPS lati la maa ṣakoso bawọn akẹkọọ ṣe n wọ ile ẹkọ giga ni Naijiria.

Amọ, JAMB sọ pe ọpọ ile ẹkọ ni ko si akọsilẹ awọn akẹkọọ ti wọn gba wọle lori itakun CAPS.