Ìdí tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Fásítì àti Pólì Ibadan kò ṣe tí ì bẹ́rẹ̀ ìyanṣẹ́lòdì

Pẹlu bi awọn ile ẹkọ giga kan ṣe ti bẹrẹ iyanṣẹlodi, apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ile ẹkọ giga Faṣiti Ibadan ati ti Gbogboniṣe (Polytechnic Ibadan) ko ti i bẹrẹ ni tiwọn.
Ẹ o ranti pe Aarẹ Academic Staff Union of Universities (ASUU), Ọjọgbọn Chris Piwuna, ti kede ṣaaju pe awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ giga Fasiti ijọba kaakiri Naijiria yoo daṣẹ silẹ, bi ijọba ko ba sanwo oṣu Kẹfa fun wọn lẹyin ọjọ kẹta oṣu tuntun.
Aṣẹ naa ni awọn ile ẹkọ giga kan ti tẹle, ti wọn si ti bẹrẹ iyanṣẹlodi naa.
Bakan naa ni Aarẹ Academic Staff Union of Polytechnics (ASUP), Kọmureedi Shammah Kpanja, naa ti kede pe awọn olukọ Poli paapaa yoo gunle iyansẹlodi laipẹ, bi ijọba apapọ ko ba tete maa sanwo oṣu awọn bi oṣu ba ṣe n pari.
Lati mọ idi ti Fasiti ati Poli Ibadan ko ṣe darapọ mọ iyanṣelodi yii, BBC Yoruba ṣabẹwo silẹ ẹkọ mejeeji.
Ọpọ yara ikawe ni ko si awọn akẹkọọ nibẹ ni Yunifasiti Ibadan, eyi ri bẹẹ nitori idanwo to n lọ lọwọ.
Awọn to wa si wa ni yara ikawe kọọkan n lo ibẹ lati fi gbaradi fun idanwo ni.
''Ó ṣeé ṣe ká darapọ̀ mọ́ ìyanṣẹ́lódì''

Ninu ọrọ Ọjọgbọn Kola Lawal, Alaga ASUP Poli Ibadan, o ni loootọ ni ẹgbẹ oṣiṣẹ olukọ ile ẹkọ Gbogbonisẹ pe fun iyansẹlodi, ṣugbọn o digba ti awọn ọga ẹgbẹ oṣiṣẹ ASUP ba too ṣepade apapọ lọsẹ to n bọ ki iyansẹlodi naa too waye.
Ọjọgbọn Lawal ni bo tilẹ jẹ pe Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, ko jẹ àwọn oṣiṣẹ ni ajẹsilẹ gbese owo oṣu kankan, ṣugbọn lati ja ija naa papọ, o ṣee ṣe ki Poly Ibadan naa gunle iyanṣẹlodi.
Ni ti Yunifasiti Ibadan, akọroyin wa gbiyanju lati ba ọga agba ẹgbẹ ASUU ibẹ sọrọ, iyẹn Ọjọgbon Adefemi Afolabi, sugbọn o kọ lati sọrọ lori iyanṣẹlodi naa.














