"JAMB, ṣe àtúnṣe sí orúkọ mi tó ti bàjẹ́, kó sì jẹ́ ń lọ sìnrú ìlú lẹ́yìn ìdádúró ọdún kan"
Idunu ṣubu l'ayọ fun Akẹkọọjade ni fasiti imọ ẹrọ to wa ni Akure FUTA, Jamiu Banuso bi ajọ JAMB ṣe ṣatunṣe si itakun rẹ lori ẹrọ alatagba, eyi to safihan pe lootọ lo kogo ja lati kẹkọ yege ni fasiti FUTA.
Saaju ni ajọ JAMB ti kọkọ gbegi di itakun Jamiu Banuso, bi wọn ṣe sọ pe ọna aitọ lo gba wọ fasiti FUTA, eyi to mu ki wọn da duro lati lọ ṣe Agunbanirọ lati ọdun to kọja.
Ṣugbọn bayi lẹyin akitiyan ọmọkunrin naa, to si duro lori ẹsẹ rẹ pe ọna to tọ to si bofin mu, ni oun gba lati wọ Fasiti FUTA, ajọ JAMB gbe ẹsẹ kuro lori Itakun rẹ ni ori ẹrọ alatagba wọn ni ọjọ Aiku to kọja.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori isẹlẹ naa, Jamiu ni inu rẹ dun jọjọ, to si salaye pe ọjọ Aiku to kọja yi ni ohun dede wo ori itakun naa, ti ohun si ri pe Ajọ JAMB ti ṣe ohun ti o yẹ.
O ni kete ti ohun ri ohun to sẹlẹ naa, ohun gbe gbogbo igbesẹ to nilo lati le lọ ṣe Agunbanirọ eyi to yẹ ko ti ṣe lati ọdun to kọja.
Ogbeni Basola wa rọ ajọ JAMB lati se awẹmọ orukọ rẹ, o salaye pe bi o ti ẹ jẹ pe wọn ti ṣe ohun ti o yẹ ni kọrọ, wọn nilo lati wẹ orukọ rẹ mọ ni gbangba.

Kí ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú láàrin Banuso àti JAMB?
Ọgbẹni Jamiu Basola kẹkọ yege ni Fasiti FUTA lọdun 2024, pẹlu grade to jẹ 4.41, to si se idanwo JAMB rẹ ni ọdun 2017, ti fasiti FUTA si gba wọle lati kẹkọ nipa imọ Civil Engineering lọdun 2018.
Lẹyin to kẹkọ yege lọdun to kọja, to si n mura lati lọ ṣe Agunbanirọ, wọn sọ fun ni Fasiti naa pe Ajọ JAMB ko fun lanfaani lati lọ ṣe Agunbanirọ nitori ọna eburu lo gba wọ Fasiti naa.
Basola lasiko to n ba BBC YORUBA sọrọ lasiko naa, o ni fasiti FUTA rọ ọ lati lọ sayewo itakun rẹ lori JAMB eyi to safihan rẹ lootọ pe ọna eburu ni ohun gba wọ Fasiti náà, ti ohun ko si le se ohunkohun lori rẹ.
O ni kayefi nla ni ọrọ naa jẹ fun.

Oríṣun àwòrán, Banuso
Basola salaye fun BBC Yoruba pe lati ọdun to kọja ni oun ti kọ lẹta lati salaye fun Ajọ JAMB bi ọrọ ṣe ri gan.
Sugbọn o ni wọn kọ iha ko kan mi si ọrọ naa, ti wọn si fi akoko rẹ sofo fun ọdun kan gbako.
O salaye pe lẹyin gbogbo akitiyan ohun, awọn alasẹ fasiti FUTA satileyin fun un lẹyin iwadii ti wọn ṣe, ti wọn si ri pe ootọ ni pe oun gba ọna to tọ lati wọ Fasiti naa.
Kaka ki ewe agbọn dẹ ṣe lo n pele si, Basola sọ pe, ajọ JAMB gbe ohun lọ ba ajọ DSS ati awọn Ọlọpaa lori ọrọ yi, sugbọn ọrọ oun ko yipa, ti fasiti FUTA si safihan ẹri to daju niwaju wọn.
Akẹkọọ jade naa sọ pe, pẹlu ẹri to wa niwaju JAMB wọn ko gbe igbesẹ kan, eyi lo mu ki oun lọ sori ẹrọ ayelujara lẹyin ọdun kan, ti wahala naa ti bẹrẹ lati le jẹ ki awọn ọmọ orileede yi mọ nipa ohun to n jo oun labẹ aṣọ.
















