Má ṣẹ́ òògùn ibà oníhóró sí wẹ́wẹ́ fún ọmọ rẹ̀ mọ́, wo oògùn ìtọ́jú àìsàn ibà fáwọn ọmọ ọwọ́ tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ fòǹtẹ̀ lù

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Dominic Hughes
- Role, Global Health Correspondent
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Oògùn tó wà fún ìtọ́jú àìsàn ibà fáwọn ọmọdé, tó fi mọ́ àwọn ọmọ ọwọ́ ti rí ìbuwọ́lù fún lílò.
Láàárín ọ̀sẹ̀ díẹ́ sí àsìkò yìí, ni wọ́n máa pín àwọn oògùn náà sí ilẹ̀ Africa.
Títí di àsìkò yìí, kò sí oògùn fún ìtọ́jú àìsàn ibà fáwọn ọmọ ọwọ́, tó sì jẹ́ pe àwọn òògùn ibà tó wà fún àwọn ọmọ tó ti dàgbà díẹ̀, ni wọ́n máa ń lò fún wọn èyí tó lè fa àṣìlò oògùn.
'Àwọn èèyàn tó lé ní ìdají mílíọ̀nù ni àìsàn ibà ṣekúpa lọ́dún 2023'
Lọ́dún 2023 - ọdún tó súnmọ́ tí àkọ́ọ́lẹ̀ rẹ̀ wà báyìí – àìsàn ibà ni wọ́n ló ṣekúpa èèyàn tó tó 597,000.
Ní ilẹ̀ Africa ni ikú náà ti wáyé jùlọ tí ìwádìí sì tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìdá mẹ́ta nínú ìdá mẹ́rin àwọn èèyàn náà tó jẹ́ ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn wà lábẹ́ ọdún márùn-ún.
Ṣáájú àsìkò yìí, oògùn ìtọ́jú àìsàn ibà wà fáwọn ọmọdé àmọ́ kò sí fún àwọn ọmọ ọwọ́ tí ìwọ̀n wọn kò ì tíì ju kílógíráàmù mẹ́rin àbọ̀ (4.5kg) lọ.
Oògùn tó wà fún àwọn ọmọ tó ti dàgbà díẹ̀ ni wọ́n máa ń lò fún wọn
Èyí léwu díẹ̀ fáwọn ọmọdé náà nítorí ẹ̀dọ̀ wọn kò ì tíì lágbára láti gba àwọn oògùn náà dúró tó sì le ṣàkóbá fún wọn.
Àwọn onímọ̀ sọ pé èyí ti ṣokùnfà ohun tí wọ́n ń pè ní "àlàfo ìtọ́jú".
Ní báyìí, iléeṣẹ́ tó ń poògùn kan, Novartis ti ṣe àgbékalẹ̀ oògùn kan èyí tí ìjọba ilẹ̀ Swiss ti buwọ́lù, tí wọ́n sì máa bẹ̀rẹ̀ sí ní pin káàkiri àwọn ẹkùn àti orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti ń ní àkọ́ọ́lẹ̀ àìsàn ibà jùlọ.
Novartis ń gbèrò láti pèsè oògùn náà lọ́pọ̀ yanturu láì ní ìrètí láti jèrè kankan nídìí rẹ̀.
Àwọn tó kéré tí kò sì lágbára
Adarí iléeṣẹ́ náà, Vas Narasimhan sọ pé àsìkò tó ṣe pàtàkì ni àkókò yìí.
"Láti bíi ọgbọ̀n ọdún ni a ti ń jìjà láti gbógun ti àìsàn ibà, tí à ń ṣiṣẹ́ lọ́sàn-án lóru láti wá ọ̀nà àbáyọ níbi tí wọ́n ti nílò rẹ̀ jùlọ.
"Inú wa dùn púpọ̀ pẹ̀lú àwọn alábàáṣiṣẹ́ wa pé a ti ṣe àgbákalẹ̀ oògùn àkọ́kọ́ fáwọn ọmọ ọwọ́ láti fi kojú ibà pẹ̀lú àrídájú pé àwọn tó kéré àtàwọn tí kò lágbára ni ó le lo oògùn náà.
Oògùn náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Coartem Baby tàbí Riamet Baby láwọn orílẹ̀ èdè kan jẹ́ ṣíṣe látọwọ́ iléeṣẹ́ Novartis pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Medicines for Malaria Venture (MMV) iléeṣẹ́ tí kò wà fún jíjẹ èrè ní Swiss èyí tí ìjọba ilẹ̀ Britain, Swiss àti Dutch, tó fi mọ́ ilé ìfowópamọ́ àgbáyé àti àjọ Rockefeller Foundation ń ṣe àtìlẹyìn fún.
Orílẹ̀ èdè Africa mẹ́jọ wà lára àwọn tí wọ́n jọ ṣe àyẹ̀wò oògùn náà tí ìrètí sì wà pé wọ́n wa lára àwọn tó máa kọ́kọ́ gba oògùn ọ̀hún.
Martin Fitchet, Adarí iléeṣẹ́ MMV sọ pé ìgbésẹ̀ kan pàtàkì láti fòpin sí àìsàn ibà ni èyí jẹ́.
"Àìsàn kan tó lágbára káàkiri àgbáyé ni ibà jẹ́ pàápàá fáwọn ọmọdé. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ohun èlò tó yẹ àti àfojúsùn, ó ṣe é kojú.
"Ìbuwọ́lu Coartem Baby jẹ́ ohun ìnílò láti pèsè iye oògùn tó yẹ láti fi tọ́jú àwọn ọmọ ọwọ́ jẹ́ ojúnà láti pọnkún àwọn oògùn láti dènà àìsàn ibà."
Dókìtà Marvelle Brown, onímọ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Hertfordshire School of Health, Medicine and Life Sciences ní a gbọ́dọ̀ rí ìgbésẹ̀ yìí bí ọ̀nà kan gbòógì láti dá ààbò bo ẹ̀mí àwọn ọmọ ọwọ́ àti ọmọdé lápapọ̀.
"Ikú tí àìsàn ibà ń fà pàápàá ní ẹkùn Sub-Saharan Africa pọ̀ púpọ̀ – ó lé ní ìdá mẹ́rìndínlọ́gọ́rin (76%) ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn wà lábẹ́ ọdún márùn-ún tó ń jáde láyé.
"Bí Novartis ṣe ṣe àgbékalẹ̀ oògùn yìí láì ní èròńgbà láti jèrè níbẹ̀ yóò ṣe ìrànwọ́ fáwọn tí kò ní àǹfàní sí ètò ìlera tó péye."















