Rasheed Ladoja: Akọni olóṣèlú tó fi sùúrù gba adé Sẹ́nátọ̀ àti gómìnà, tó tún fẹ́ gba adé Olubadan kẹrìnlélógójì

Rashidi Adewolu Ladoja, ti ipo Olubadan kan
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Oye ọba jijẹ ilẹ Ibadan ko ruju, ẹni to kan yoo ti mọ ara rẹ ṣaaju akoko ti yoo debẹ.

Idi ree ti gbogbo eeyan fi n ṣe Kabiyesi silẹ bayii fun Oloye Sẹnetọ Rasheed Adewolu Ladoja, gomina Oyo tẹ́lẹ̀ tí yóò di Olúbàdàn kẹrìnlélógójì.

Aridaju yii n waye pe Rasheed Ladoja too di Olubadan tori ipapoda Olubadan Owolabi Olakuleyin, nigba to ku ọjọ diẹ ko pe ọdun kan to jọba ilu Ibadan.

Ọjọ kejila, oṣu Keje ọdun 2024 ni ọba to waja naa di Olubadan kẹtalelogoji labẹ ofin.

Ni bayii, igun ti Ladoja ti wa, ni ipo Olubadan kan, agba oye Rasheed Ladoja naa si ni oloye to ga ju nibẹ bayii, eyi to mu ipo Ọba Ibadan tọ si i.

BBC Yoruba wa se akojọpọ itan igbe aye agba oye Rasheed Adewolu Ladoja eyi to yẹ ki ọpọ araalu mọ.

Ọba Rasheed Adewolu Ladoja

Koko pataki nipa igbe aye Rasheed Adewolu Ladoja

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹsan-an ọdun 1944 ni wọn bi Rasheed Adewolu Ladoja si agbegbe Gambari, lẹba ilu Ibadan.

O lọ sileewe Ibadan Boys High School laarin ọdun 1958 si 1963 ati Olivet Baptist High School laarin ọdun 1964 si1965.

Adewolu tẹsiwaju ninu ẹkọ rẹ, o lọ si University of Liège, lorilẹede Belgium, iyẹn laarin ọdun 1966 si 1972, nileewe naa lo ti gboye nipa imọ ẹrọ (Chemical engineering).

Ọdun 1993 ni wọn dibo yan Rasheed sile igbimọ aṣofin apapọ, nigba to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu United Nigeria Congress Party (UNCP).

Ni ọdun 2000, Rasheed Ladoja di ọga agba nile ifowopamọ Standard Trust Bank Limited.

Oṣu Kẹrin ọdun 2003 ni wọn dibo yan an sipo gomina ipinlẹ Oyo, ẹgbẹ PDP lo si gbe e wọle sipo naa, oṣu Karun-un ọdun naa lo di gomina.

Ṣaaju iyansipo yii, Oloogbe Lamidi Adedibu, agba oṣelu ninu PDP nilẹ Ibadan nigba naa, duro bii igi lẹyin ọgba fun Ladoja.

Asiko yii si ni Oloye Olusegun Obasan wa nipo aarẹ ni Naijiria, ti Adebayo Alao Akala si jẹ igbakeji Ladoja.

Loṣu Kẹjọ ọdun 2004, ija de laaarin Ladoja ati Adedibu lori ọrọ iyansipo ati iṣuna owo.

Àkọlé fídíò, Nàíjíríà tóbi jù fún ìjọba àpapọ̀ láti darí, ẹ jẹ́ kí kálukú darí ẹkùn tiẹ̀ - Ladoja

Wọ́n yọ Ladoja nípo gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo

Aigbọra ẹni ye laarin Adedibu ati gomina Ladoja pada ja si yiyọ ti wọn yọ gomina naa kuro nipo lọjọ kejila, oṣu Kin-in-ni ọdun 2006.

Oloogbe Adebayo Alao Akala to jẹ igbakeji rẹ nigba naa si bọ sipo gomina ipinlẹ Oyo.

Ọjọ akọkọ ninu oṣu Kọkanla ọdun 2006 ni ile ẹjọ Ko-tẹ-mi-lọrun kede pe bi wọn ṣe yọ Ladoja nipo ko ba ofin mu.

Kootu naa gbe amọran kalẹ pe ki wọn duro de idajọ ile ẹjọ to ga julọ.

Nigba to di ọjọ kọkanla oṣu Kọkanla ọdun 2006 kan naa, ile ẹjo to ga julọ tun pasẹ pe ki Ladoja maa ba iṣẹ rẹ lọ nipo gomina.

Ọjọ kejila oṣu Kejila ọdun 2006, Ladoja pada sipo gomina ipinlẹ Oyo.

Ki lo gbe Ladoja de ọdọ EFCC, eyi to mu kawọ sẹyin rojọ nile ẹjọ?

Ọdun 2008, lọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kẹjọ ni ajọ EFCC to n ri si ṣiṣe owo ilu mọkumọku, nawọ gan Adewolu Ladoja.

Ohun ti wọn sọ nigba naa ni pe gomina tẹlẹ naa ko fi N1.9 billion, owo ipin idokowo ijọba to wa nikawọ rẹ lasiko to wa nipo silẹ.

Eyi lo mu ile ẹjọ giga ijọba apapọ paṣẹ, pe ki wọn gbe e ju sẹwọn fungba diẹ.

Wọn gbe si ahamọ naa ni ọgbọnjọ oṣu Kẹjọ, wọn si da a silẹ lọjọ Karun-un, oṣu Kẹsan-an ọdun kan naa.

Ọgọrun-un kan miliọnu naira (N100 million), ni wọn fi gba oniduuro rẹ lọjọ naa, pẹlu ẹlẹrii meji niye kan naa.

Amọ lẹyin o rẹyin, Rasheed Ladoja bori ẹjọ naa, ti adajọ si ni ko jẹbi ẹsun ti EFCC fi kan an.

Ọba Ladoja nigba to gba ọpa aṣẹ ọba ti Kabiyesi Oloogbe Olakulẹyin ati ijọba ipinlẹ Oyo fun un.

Ladoja tún dupò gómìnà nínú ẹgbẹ́ Accord ni 2011 àti 2015

Ninu igbinyanju rẹ lati di gomina ipinlẹ Oyo lẹẹkan si i, Agba oye Rasheed Ladoja du ipo naa ninu ẹgbẹ oṣelu Accord.

Eyi waye ni 2011 ati 2015, ṣugbọn nigba mejeeji ọhun, Oloogbe Abiola Ajimobi ni ipo gomina naa ja mọ lọwọ.

Lẹyin naa ni Olubadan tuntun yii kede pe oun fẹ sinmi diẹ fun oṣelu sise, iyẹn lẹyin to ti wọnu ẹgbẹ ADC ati ZLP ni 2018.

Ladoja pada sile lati mojuto ọrọ ipo Olubadan toun naa lẹtọọ lati jẹ, to si wu lori ẹmi rẹ.

Awọn agba oye to gba ade lọwọ gomina Ajimobi

Ki lo de ti Ladoja se kọ lati gba ‘ade paali’ lọwọ gomina Abiola Ajimobi ati Seyi MAkinde?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba ti gomina Abiola Ajimobi wa nipo gomina, o kede atunse si ilana oye jijẹ nilẹ Ibadan eyi ti ọpọ eeyan tako, to si mu awuyewuye lọwọ nigba naa.

Asiko naa si ni Ajimobi kede pe ki awọn agba oye Olubadan wa tẹri gba ade gẹgẹ bi ọba ni adugbo ti koowa wọn ti wa, eyi ti ọpọ eeyan se apejuwe bii ‘ade paali’

Bi o tilẹ jẹ pe awọn agba oye kan gba ade naa, amọ agba oye Rasheed Ladoja nikan soso lo fi aake kọri lati gba ade naa, eyi to se apejuwe bii ‘ade paali’, laarin awọn agba oye yoku nilẹ Ibadan.

Nigba ti Abiola Ajimobi kuro nipo, ti Seyi Makinde si di gomina, sibẹ oun naa taku pe Ladoja gbọdọ gba ade paali yii, to ba fẹ di Olubadan.

Ṣugbọn lẹyin awuyewuye lori ilana eto oye jijẹ ilẹ Ibadan, ijọba sọ igbesẹ gbigba ade paali naa di ofin, eyi to pọn ni dandan fun Ladoja lati gba ade naa bi yoo ba de ipo Olubadan.

Lẹyin o rẹyin, Adewolu mu suuru, o si gba ade naa, se suuru ni baba iwa.

Bẹẹ lo si ṣe to gba ade naa lọjọ kejila, oṣu Kẹjọ ọdun 2024. Kabiyesi Owolabi Olakulẹyin to waja yii lo gbe ade ọhun le Ladoja lori.

Lati igba naa lo si ti han pe gbogbo eto lo ti to fun Rasheed Adewolu Ladoja lati bọ sori aleefa Olubadan ilẹ Ibadan bi ọjọ ba pe.

Ki ẹṣin ọba o jẹko pẹ pẹlu alaafia ara ladura ti araalu n gba, bi Adewolu yoo ṣe gun ori itẹ awọn baba to bi i lọmọ gẹgẹ bii Olubadan kẹrinlelogoji nilẹ Ibadan.

Kabiyesi o.