Ṣé lóòótọ́ ni Olórí ìjọba Iran ti yọjú síta lẹ́yin ogun Israel àti Iran? Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, EPA
Olori ijọba Iran, Ayatollah Ali Khamenei, ti fara han fun igba akọkọ lati igba ti ogun to bẹ silẹ laarin Israel ati Iran ti bẹrẹ.
Ileeṣẹ tẹlifisan Iran ṣafihan bi Khamenei ṣe n kawọn olujọsin ni mọṣalaaṣi kan lanaa ọjọ Abamẹta ṣaaju ajọdun Shia Ashura.
Ọjọ kẹtala oṣu Kefa to kọja ni olori ijọba Iran foju han nita gbangba nigba kẹyin nigba to sọrọ ninu fọnran kan lori ogun Israel ati Iran.
Awọn ogbontarigi ọgagun atawọn onimọ sayẹnsi Iran lo padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ naa.
Israel lo kọkọ ju ado oloro si ibudo iko nnkan ija oloro Iran si, Iran naa si gbẹsan lẹyin ti ileeṣẹ ologun Iran naa ju oriṣiiriṣii ado oloro pada si Israel.
Igba mẹta ọtọọtọ ni Khamenei sọrọ lori ẹrọ amohunmaworan laarin ogun to waye fun ọjọ mejila laarin Israel ati Iran.
Lẹyin naa ni iroyin kan sọ pe olori ijọba Iran ti sa pamọ sinu iho ilẹ kan.
Amọ, ileeṣẹ tẹlifisan Iran ṣafihan Khamenei lọjọ Abamẹta nibi to ti n ki ọpọ eeyan ti inu awọn eeyan to ri i si n dun.
Awọn eeyan wo Khamenei lori tẹlifisan Iran bi o ti kọju si onimọ nipa ẹsin Islam, Mahmoud Karimi, ti o si sọ fun pe ki o kọrin ilẹ Iran - ''O iran.''
Orin yii di gbajugbaja orin ti ọpọ eeyan n kọ lasiko ogun ọjọ mejila to waye laarin Iran ati Israel.
Ileeṣẹ tẹlifisan Iran sọ pe ni mọṣalaaṣi Imam Khomeini ni Tehran lawọn ti ri Khamenei
Ileeṣẹ tẹlifisan Iran sọ pe ni mọṣalaaṣi Imam Khomeini ni Tehran ni awọn ti ṣe fidio olori ijọba Iran naa.
Ẹwẹ, ileeṣẹ tẹlifisan Iran ti kepe araalu lati bẹrẹ sii fi fidio ranṣẹ lori bi Khamenei ti yọju sita pada lẹyin ogun to waye pẹlu Israel.
Khamenei fara han lasiko yii ti Iran to jẹ ẹlẹsin Islam Shia n kẹdun lọwọ ninu oṣu Muharram eyi ti olori ijọba orilẹede naa maa n kopa ninu rẹ.
Ọjọ kẹwaa oṣu Muharram to bọ si oni ọjọ kẹfa oṣu Keje ni ọdun Ashura maa n waye.
Lasiko ọdun yii lawọn musulumi Shiíte maa n ṣe iranti iku Hossein to jẹ ọmọ-ọmọ Anabi Muhammad.
Ṣaaju lọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹfa to kọja ni Khamenei leri ninu fọnran kan ti ileeṣẹ tẹlifisan Iran gbe jade pe Iran ko ni gba fun Israel bo tilẹ jẹ pe Aarẹ Donald Trump Amẹrika n pe fun alaafia.
Ọjọ kejilelogun oṣu Kẹfa ni Amẹrika dasi ogun naa lẹyin ti wọn ju ado olori si ibudo nnkan ija olori Iran.
Baalu ijagun 125 ileeṣẹ ologun Amẹrika lo ṣe ikọlu si ibudo nnkan ija oloro Iran to wa ni Fordo, Natanz ati Isfahan.
Ileeṣẹ eto idajọ Iran ni ko din ẹẹdẹgbẹrun (900) eeyan to padanu ẹmi wọn ninu ogun ọhun to waye fun ọjọ mejila.















