Ṣọ́ọ̀ṣì tí ààrẹ fẹ́ fi owó ara rẹ̀ kọ́ sílé ìjọba di wàhálà

Aworan ṣọọṣi nla kan

Oríṣun àwòrán, Getty image

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

"Mi o ni i tọrọ aforiji lọwọ ẹnikẹni nitori mo fẹẹ kọ ṣọọṣi, owo apo ara mi ni mo fẹẹ fi kọ ọ. Eṣu le maa binu, o si le ṣe ohun to ba wu u. Ko si ohun ti yoo da ipinnu mi duro."

Aarẹ orilẹede Kenya, William Ruto, lo sọrọ yii lọjọ Ẹti lori ile ijọsin awọn Kristẹni to fẹẹ kọ si ile ijọba ilẹ naa.

Ọrọ ti Aarẹ Ruto sọ yii ni iroyin sọ pe o ṣi n bi awọn ọmọ orilẹede rẹ ninu, paapaa bi wọn ko ṣe faramọ iru ijọba ti Ruto yan laayo.

Ohun ti ọpọ araalu naa n sọ ni pe olori awọn ti fẹẹ da ọrọ ilu pọ mọ ti ẹsin, ti ko si jọra wọn.

Nnkan mi-in to tun n fa awuyewuye ni eṣu ti Ruto darukọ, wọn ni awọn ko mọ ẹni ti aarẹ n pe ni eṣu nile ijọba.

"Mi o kọ ṣọọṣi nigba ti mo wọle ijọba. Mo ba ṣọọṣi to jẹ pe irin ni wọn fi kọ ọ ni. Ṣe iyẹn pọn ile ijọba le?

Aarẹ Ruto lo beere bẹẹ lọwọ awọn oloṣelu ti wọn jọ ṣepade lọjọ Ẹti naa.

Lọjọ Ẹti naa ni ọkan lara awọn iwe iroyin to gbajugbaja ju ni Kenya, Daily Nation, gbe aworan ile ijọsin nla kan jade to le gba to eeyan ẹgbẹrun mẹjọ.

Iwe iroyin naa beere boya ṣọọṣi ti Ruto fẹẹ kọ yii wa ni ibamu pẹlu ofin ilẹ Kenya, nibi to jẹ ọlọkan-o-jọkan ẹsin ni wọn n ṣe nibẹ.

Bi nnkan ko si ṣe rọgbọ ni Kenya to lẹka ọrọ aje, owo to to $9m (£6.5m), ni iroyin sọ pe Ruto yoo fi kọ ṣọọṣi rẹ, bo tilẹ jẹ pe o ni owo ara oun loun yoo fi kọ ọ.

Ṣé ààrẹ lẹ́tọ̀ọ́ làti fi owó rẹ̀ kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì sílé ìjọba?

Ààrẹ orilẹede Kenya, William Ruto.

Oríṣun àwòrán, Getty image

Bi Aarẹ Ruto ti awọn eeyan Kenya fun ni inagije ' Deputy Jesus', iyẹn Igbakeji Jesu, ṣe loun yoo fi owo ara oun kọ ṣọọṣi sile ijọba yii ti mu kawọn eeyan maa beere pe ṣe ofin tilẹ faaye gba eyi.

Bi eeyan yoo ba kọ iru nnkan bẹẹ, awọn awoye sọ pe ile ijọba kọ ni yoo kọ ọ si, paapaa bi ko ṣe si mọṣalaṣi kankan nile ijọba naa.

Alufaa Philip Anyolo, ti ijọ Katooliki Nairobi, sọ pe alaye kikun gbọdọ tete waye lori ohun ti Aarẹ Ruto fẹẹ ṣe yii.

O ni bi bẹẹ kọ, yoo kan da bii pe Aarẹ fẹran ijọ Kristẹni ju omiran lọ ni.

"A gbọdọ ṣọra gan-an lori eyi, ori ilẹ ti ko ba ni nnkan lati ṣe pẹlu ijọba ni eeyan le kọ iru nnkan bayii si.

"Afi to ba jẹ pe ibudo ti ko yọ ẹlẹsin kankan silẹ nikan lo ku. Ti yoo jẹ aaye isadi fun gbogbo eeyan lati gba iranlọwọ lai fi ti ẹsin ti wọn n sin ṣe."

Alufaa Philip Anyolo lo ṣalaye bẹẹ.

Àwọn ìjọ tí kò gbàgbọ́ nínú Ọlọrun (Atheists) ní àwọn yóò pe Ààrẹ Ruto lẹ́jọ́

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bi Aarẹ William Ruto ko ba yi ipinnu rẹ pada, awọn ijọ ti ko gba pe Ọlọrun wa, (Atheists), ti n leri pe awọn yoo pe e lẹjọ.

Awọn ko gba Ọlọrun gbọ eeyan naa juwe ipinnu Aarẹ Ruto bii eyi to yani lẹnu ti ko si ṣee gba wọle rara.

" A ri igbesẹ yii bii eyi to tako ijọba awaarawa, ati eyi ti Aarẹ Ruto fẹẹ fi gbe orilẹede ẹlẹsin Kristẹni ga.

"A fẹẹ ran Aarẹ leti, pe Kenya ki i ṣe fun awọn Kristẹni nikan."

Olori awọn ẹgbẹ naa, Harrison Mumia, lo ṣalaye bẹẹ.

Ninu awọn aarẹ to ti jẹ ni Kenya, William Ruto ni akọkọ to n kede ihinrere nilana ẹsin Kristẹni.

O maa n farahan bii ẹni mímọ́, eyi ni wọn ṣe fun un ni inagijẹ "Deputy Jesus".

Fun ọpọ igba lo ti maa n fi ẹsẹ Bibeli gbe ọrọ rẹ lẹsẹ to ba n sọrọ lawujọ, eyi si maa n jẹ ki awọn eeyan Kenya ti ki i ṣe Kristẹni maa ri ara wọn bii ẹni itanu.

Bo tilẹ jẹ pe ida marundinlaadọrun-un (85%) awọn eeyan Kenya ni wọn jẹ Kristẹni, awọn Musulumi ti wọn to ida mọkanla (11%)n naa wa nibẹ.

Bakan naa si ni awọn ẹlẹsin Hindu naa wa nibẹ bi wọn ko tilẹ pọ, awọn kan si wa to jẹ ẹsin ibilẹ wọn ni wọn n ṣe.

Nigba ti Ruto wa nipo Igbakeji aarẹ ilẹ naa, o kọ ṣọọṣi kan si ile ijọba to n gbe, ni Karen, ibẹ lo to ti maa n gbalejo awọn olori ẹsin ti ki i ṣe Kristẹni nikan.