Ohun tó rọ̀ mọ́ bí Peter Rufai ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ́ orúkọ ìnagijẹ 'Dodo Mayana'

Aworan oloogbe Peter Rufai

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọjọ ti a ba ku la a dere, eeyan o ṣunwọn laaye, awọn ọmọ Naijiria atawọn ololufẹ bọọlu kaakiri agbaye si n sẹ idaro agbaọjẹ agbabọọlu Super Eagles Naijiria, Peter Rufai, to jade laye l'Ọjọbọ ọsẹ yii ti i ṣe ọjọ kẹta oṣu Keje ọdun yii.

Ọkan gboogi ninu awọn asọle fun ẹgbẹ agbaboolu Naijiria, Super Eagles, to tun jẹ olokiki ninu ere bọọlu ni ilẹ Afirika ni Peter Rufai jẹ nigba aye rẹ.

Peter Rufai ni okiki ninu ere bọọlu debi wi pe awọn ololufẹ rẹ fun un ni orukọ inagijẹ ti wọn n pe ni 'Dodo Mayana.''

Nigba kugba to ba n rin lọ loju titi papaa julọ niluu Eko to jẹ ibugbe rẹ lawọn ololufẹ rẹ maa n pe e ni ''Dodo Mayana'' ti oun naa si maa n jẹ wọn.

Amọ, ta a lo sọ aṣọle Super Eagles ni inagijẹ Dodo Mayana, bawo lorukọ naa ṣe di nnkan tawọn eeyan fi n pe e?

Ta a gan an lo fun Peter Rufai ni inagijẹ Dodo Mayana?

Nigba aye rẹ, Peter Rufai, funra rẹ ṣalaye bi orukọ Dodo Mayana ṣe waye gan an.

Nigba ti o n sọrọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu awọn akọroyin, Rufai ṣalaye pe ''orukọ inagijẹ Dodo Mayana waye lati ara ibaṣepọ mi pẹlu awọn goli ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria to ṣiwaju mi bii Peter Fregene, Best Ogedengbe ati Emmanuel Okala.

Peter Fregene maa n pe mi ni Dodo nigba kugba ti mo ba wa ninu yara pẹlu rẹ.

Awọn agbabọọlu yii lo wa lode nigba naa ninu ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria nigba ti mo darapọ mọ wọn lọdun 1981.

Bayii ni mo ṣe lanfaani lati sun mọ Peter Fregene, laaraarọ ni mo maa n ko bata awọn goli mẹtẹẹta lọ sinu ọkọ ti mo si maa n fun wọn ti wọn ba ti fẹ wọ ọ.

Koda, mo maa n fẹ ko aṣọ ti wọn ba wọ fi ṣe igbaradi ati bata lati nu un lẹyin ti wọn ba ti ṣetan ṣugbọn wọn maa n sọ fun mi pe alagbafọ lo maa fọ aṣọ naa wi pe ki n maa ṣe iyọnu.

Gbogbo nnkan yii ni mo maa n ṣe lasiko ti mo wa pẹlu wọn nibi ti ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria ti n ṣe igbaradi.''

Rufai sọ pe lati igba naa ni Fregene ti bẹrẹ sii pe oun ni Dodo tori bi oun ṣe sun mọ an toun si n wo awokọṣe rẹ ninu ile mimu.

Oloogbe Rufai ni kẹrẹ kẹrẹ lawọn jọ lọ si orilẹede Portugal labẹ aṣẹ akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria nigba naa, Otto Gloria.

''Awọn ololufẹ mi fẹran lati maa pe mi ni Dodo Mayana ju Peter Rufai lọ''

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aṣọle Naijiria tẹlẹ ni lọdun 1982 lawọn lọ ṣe igbaradi lorilẹede Portugal nibi ti Peter Fregene ti kọkọ bọ soju ile.

O ni lẹyin ti Fregene ṣetan ni Best Ogedengbe bọ soju ile fun igbaradi tiẹ naa.

''Lẹyin naa lo kan mi ti emi naa si lanfaani lati bọ soju ile, ṣugbọn bọọlu bi ọgbọn ni akọnimọọgba wa n gba soju ile nigba ti emi bọ soju ile.

Gbogbo bọọlu ọgbọn yii si ni mo n gbiyanju lati mu bi Otto Gloria ṣe gbawọn si mi.

Gbogbo nnkan ti mo ti kọ lọdọ Peter Fregene ati Best Ogedengbe ni mo n lo lati mu awọn bọọlu ti akọnimọọgba wa n gba si mi.

Tori awọn ti wọn ti n kọ mi ni ile mimu naa lawọn eeyan yii.

Amọ, awọn oluworan fẹran bi mo ṣe n lọ fun gbogbo bọọlu ti wọn n gba si mi loju ile.

Koda, ariwo sọ nigba ti wọn fọn feere wi pe a ti pari igbaradi, awọn oluworan ni ka tẹsiwaju tori awọn n gbadun mi loju ile.

Mi o tiẹ kọkọ mọ pe nitori mi lawọn oluworan fi n pariwo, ṣa deedee ni mo gbọ ti ẹnikan sọ pe ''Dodo,'' ti o si nawọ soke.

Bayii ni mo ri ọpọ eeyan ti wọn n na ọwọ soke ti wọn si n pariwo.

Lẹyin naa ni mo fi ọwọ sọ fun wọn pe a o tẹsiwaju ere bọọlu igbaradi ti a n ṣe lọla.

Ni wọn ba sọ pe 'amaya' ti emi naa si dahun pe 'Dodo', wọn sọ pe 'Dodo amaya'' emi naa ni 'amaya dodo.''

Amaya ni ede Portuguese tumọ si ọla, nigba ti Dodo tumọ si nnkan ti eeyan yoo ri lọla.

Bayii lawọn ololufẹ mi ṣe bẹrẹ si ni ki mi pe ''Dodo Amaya ti emi si maa n dahun pe ''Amayana Dodo.''

Oloogbe Rufai sọ pe awọn ololufẹ oun fẹran lati maa pe oun ni Dodo Mayana gan an ju Peter Rufai lọ.

Ki Eledua ko dẹ ilẹ fun ẹni ire to lọ.