Èèyàn 24 jáde láyé, ọ̀pọ̀ dàwátì bí ẹ̀kún omi ṣe ṣọṣẹ́ ní ibùdó kan ní Amẹ́ríkà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Angélica Casas
- Role, BBC News
- Reporting from, San Antonio, Texas
- Author, Nadine Yousif
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ láti ṣàwárí àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n di àwátì ní Texas, orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà sínú àgbárà òjò tó ṣekúpa èèyàn mẹ́rìnlélógún tí ọ̀pọ̀ sì di àwátì níbi ibùdó àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi kan.
Ṣáájú ni ìkìlọ̀ ti wáyé pé odò Guadalupe River ti wọ ìwọ̀n bátà ẹsẹ̀ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n láàárín wákàtí kan, tí ẹ̀kún omi tó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn gbé ọ̀pọ̀ ilé, ọkọ̀ àti ibùdó tí wọ́n ṣe fún ìsinmi lọ níbi táwọn èèyàn ti ń ṣe ìsinmi òpin ọ̀sẹ̀ lọ́jọ́ Kẹrin, oṣù Keje.
Àwọn òṣìṣẹ́ pàjáwìrì ṣì ń wá àwọn ọmọdé mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tó wà lára àwọn obìnrin 750 tó ń kópa ní ibùdó Camp Mystic tó wà ní ẹ̀bá ìlú Kerrville ní ìwọ̀ oòrùn àríwá San Antonio.
Wọ́n ti kéde ìlú ò fararọ ní àwọn agbègbè tí ẹ̀kún omi náà ti wọ́ gbobo òpópónà wọn lọ, tí fóònù wọn kò sì ṣiṣẹ́ mọ́.
Ààrẹ Amẹ́rikà, Donald Trump ti kéde ìṣẹ̀lẹ̀ bí èyí tó wáyé lójijì tó sì lágbára, bó ṣe ní àwọn máa ṣe àfikún ìrànwọ́.
Àwọn àwòrán ṣàfihàn bí ẹ̀kún omi náà ṣe ń gbé àwọn afárá, tó sì ń ya sí gbogbo òpópónà.
Gómìnà Texas, Dan Patrick sọ pé láàárín ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta ni odò Guadalupe River kún wọ ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, tó sì fa ẹ̀kún omit ó ba nǹkan jẹ́ gidi èyí tó mú ẹ̀mí àti dúkìá lọ.
Ó fi kun pé àwọn òbí tí wọn kò bá ti kàn sí túmọ̀ sí pé wọ́n rí ọmọ nìyẹn.
Ó ní èyí kò túmọ̀ sí pé ọmọ táwọn kò ì tíì rí ti sọnù, pé ó ṣeéṣe káwọn kàn má ì tíì rí wọn ni.
Àwọn aláṣẹ sọ pé iṣẹ́ ìdóòlà tó fi mọ́ lílo ọkọ̀ òfurufú, dúróònù àtàwọn ọkọ̀ ojú omi ló ṣì ń tẹ̀síwájú títí tí àwọn fi máa ṣàwárí gbogbo èèyàn.
Ibùdó náà sọ pé àwọn kò ní iná, omi àti ìtàkùn ayélujára tó sì jẹ́ pé òpópónà náà ni ẹ̀kún omi náà ti wọ́ lọ èyí tó jẹ́ kó ṣòro fáwọn láti tètè rí ìrànlọ́wọ́.
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ẹtì ni wọ́n kéde ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ẹkùn Concho Valley látàrí ẹ̀kún omi náà.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọ̀gá àgbà ní Kerr County, Rob Kelly nígbà tí àwọn akọ̀ròyìn bèèrè pé kí ló dé tí wón kò ṣe kó àwọn ibùdó tó wà ní Guadalupe River kúrò ṣáájú, ó ní àwọn kò mọ̀ pé ẹ̀kún omi yìí máa wáyé.
Ó fi kun pé àwọn kò ní ohun tó le ṣe alamí fáwọn ní agbègbè náà àti pé ẹ̀kún omi tó wáyé lọ́jọ́ Ẹtì náà kọjá ẹ̀kún omit ó wáyé ní ọdún 1987 èyí tó ṣokùnfà ikú ọmọdé mẹ́wàá.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ìròyìn CBS News ṣe sọ, àwọn aláṣẹ ẹ̀ka tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní Texas ṣèpàdé lọ́jọ́bọ̀ láti gbáradì àmọ́ wọ́n ní àjọ tó ń mójútó ojú ọjọ́, National Weather Service kò sọ iye òjò tó rọ̀ náà.
Àwọn aláṣẹ sọ pé ẹni tí kò bá gbé ní agbègbè náà kò gbọdọ̀ lọ síbẹ̀.
Ọ̀gá àgbà Kerr County sọ fún àwọn tó ń gbé ní ẹ̀bá odò Guadalupe River láti kókúrò níbẹ̀ bọ́ sí òkè.
Ẹ̀wẹ̀, Sẹ́nétọ̀ tó ń ṣojú ẹkùn Texas, Ted Cruz sọ pé Ààrẹ Trump ti pèsè ohun tí Texas nílò.













