Wo àrùn márùn-ún tó máa ń jà lásìkò òjò àti bí o ṣe lè dènà wọn

Aworan ọwọ to n fa oogun sinu abẹrẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Igba ojo maa n tura pupọ, nitori ọjọ kan ṣoṣo ojo maa n bori ẹgbẹrun ọ̀da, ara yoo tu gbogbo eeyan nigba ti ooru ba ti lọ.

Koda, nigba ti ọgbẹlẹ ba n pẹ ju titi ko tete lọ, ti ooru n mu, ọpọ eeyan lo maa n foju sọna de ojo, bii ki omi ti maa bọ lo maa n ṣe wọn.

Awọn agbẹ paapaa maa n reti ojo ni, ki nnkan oko wọn le ṣe daadaa lasiko to yẹ.

Awọn ọmọde pẹlu fẹran eji wẹliwẹli, wọn yoo jade wẹ ninu ojo, wọn yoo si gba afẹfẹ atura.

Asiko ojo ni odo maa n kun, kanga pẹlu maa n ni ọpọ omi ninu rẹ, awọn adagun omi ti oyinbo n pe ni 'Dam' naa maa n kun akunfaya lasiko ojo, omiyale maa n ṣẹlẹ nigba mi-in pẹlu, ti agbara yoo gba igboro kan.

Eyi ni awọn ewu ti awọn eeyan maa n ri pe o maa n ṣẹlẹ nigba ojo, ṣugbọn yatọ fun eyi, awọn arun kan naa wa to jẹ pe igba ojo ni wọn maa n ṣọṣẹ, ti wọn si maa n daamu awọn eeyan to ba lugbadi wọn.

Bawo wa lo ṣe le mọ awọn arun ọhun, ti wa a si da aabo bo ara rẹ ati ébi rẹ nibẹ.

BBC kan si Dokita Nasir Ahmad, onimọ nipa ilera lati ileewosan adani kan l''Abuja.

Àwọn àrùn wo ló wọ́pọ̀ nígbà òjò?

Aworan ẹfọn to ba le ara eeyan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹgẹ bi Dokita Ahmad ṣe wi, eyi ni awọn arun to wọpọ lasiko ojo:

Ibà: Arun iba lo lewaju ninu awọn arun to maa n saba kọlu awọn eeyan lasiko ojo.

Nigba ti omi ba bẹrẹ si I kora jọ ninu awọn koto idaminu (gutter), asiko naa ni awọn ẹfọn to n fa iba maa n pọ gidi.

Ewu nla ni eyi jẹ fun awọn ọmọde ati awọn oloyun, bo tilẹ jẹ pe ko sẹni ti iba ko le fi ọwọ ba, ṣugbọn awọn to wa ninu ewu rẹ ju ni oloyun ati awọn ọmọde.

Inú rírun, èébì , ìgbọnsẹ gbuuru ati aisan onigbameji:

Latari omi ẹgbin to maa n dapọ mọ omi mimu lasiko ojo, o rọrun lati lugbadi awọn aisan bii inu rirun, eebi, igbọnsẹ gbuuru, arun onigbameji ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Eyi saba maa n daamu awọn ọmọde, paapaa awọn ti ọjọ ori wọn ko ti i to ọdun marun-un.

Dokita Ahmad ṣalaye pe, "Awọn ọmọde ko ni ṣọja aronilagbara pupọ lara, eyi maa n jẹ ki aisan le tete wọle si wọn lara, o si le ja si iku bi itọju ko ba to."

Ara yíyún ati kúrúnà: Asiko ojo ni gbogbo ilẹ maa n tutu, bẹẹ ni ara eeyan pẹlu. Eyi le fa ara yiyun ati kokoro bii kuruna fun awọmn eeyan mi-in.

Òtútù,ikọ̀ ati ki ọna ọfun maa dun eeyan: Otutu ati ọrinrin maa n rinpọ lasiko ojo, awọn arugbo ati agbalagba si le maa ko otutu gidi.

Ọna ọfun le maa dun wọn, wọn si le maa hukọ pẹlu, bẹẹ ni otutu aya le kọlu awọn ẹlomi-in.

"Awọn ọmọde ati agba ti ko ba wọsọ to le gba otutu, ti wọn tun n mu nnkan tutu le lugbadi otutu, wọn le maa hukọ, ikun si le maa yọ nimu wọn. "

Bẹẹ ni Dokita Nasir wi.

Arun oju (Apollo): "Apollo" ni arun to maa n kọlu ẹyinju, ti oju aa yoo pọn dẹdẹ. Asiko ojo ni Apollo maa n ja ju.

Oju a pọn, yoo tun wu, yoo maa yọ omi, yoo si maa gbona.

"Apollo maa n ràn, bi eeyan ba n pin awọn nnkan bii aṣọ inura abi ibusun pẹlu ẹni ti arun naa mu.

Àwọn àpẹẹrẹ arun asiko ojo

Aworan àwọ̀ ara to lé to si pọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Dr Ahmad ka awọn apẹẹrẹ wọnyi bii ohun ti eeyan yoo maa ri to ba ni awọn arun asiko ojo:

Àpẹẹrẹ Ibà

Akọ iba

Ara gbigbona

Otutu ti eeyan yoo maa laagun ninu rẹ

Ori fifọ ati ara riro

Ko maa rẹ eeyan ju.

Apẹẹrẹ inu rirun, eebi igbọnsẹ gbuuru ati onigbameji

Lilọ si ile igbọnsẹ lemọlemọ

Inu rirun ti ki i mu ọwọ duro rara.

Ko maa rẹ eeyan gan-an

Ki ẹnu eeyan maa gbẹ, ki àwọ̀ ara maa gbẹ pẹlu.

Àpẹẹrẹ kúrúnà

Ki ara ri wuruwuru ko si maa yun eeyan.

Ki ara pọn.

Ki roré jade si ara eeyan, awọn mi-in maa n ni ọyun ninu.

Awọn ọmọde le maa kanra tabi ki wọn maa ke nitori ara to n ni wọn.

Àpẹẹrẹ ọfinkin, ikọ ati ki ọna ọfun maa dun eeyan

Ikọ, ọfinkin, ki imu eeyan dí, ki aya eeyan wuwo.

Apẹẹrẹ Apollo

Oju naa yoo pọn yoo si wú.

Yoo maa yọ ipin.

Ooyi le maa kọ eeyan.

Ọna àbáyọ

Aworan oju to pọn dẹdẹ ti wọn n kan oogun si

Oríṣun àwòrán, Getty Images

  • Lilo apo apẹfọn.
  • Ma ṣe rẹ omi idọti silẹ, maa da idọti rẹ nu deede, tun ayika rẹ ṣe, ro oko ayika.
  • Fin ohun to n pa ẹfọn sile.
  • Ma ṣe jade lalẹ lai wọ aṣọ to bo ara rẹ daadaa.
  • Maa se omi ti o fẹẹ mu.
  • Ma ṣe mu omi lati inu kanga ti wọn ko bo ori rẹ, tabi odo ti ko mọ.
  • Fi ọṣẹ fọ ọwọ rẹ ki o too jẹun ati lẹyin ti o ba lo ile igbọnsẹ tan.
  • Ṣọra fun ounjẹ arajẹ ti o ko mọ ibi ti wọn ti se e.
  • Fi omi to mọ wẹ.
  • Nu ara rẹ lẹyin iwẹ.
  • Ṣọra fun aṣọ to fun ọ pa pinpin.
  • Ma ṣe ba eeyan pin aṣọ inura, kàn-ǹ-kàn ìwẹ̀ tabi nnkan ipara.
  • Ma a wọ aṣo to bo ara lati dena otutu, paapaa lalẹ.
  • Mu omi to lọ wọọrọ tabi tii.
  • Ma ṣe duro ninu iji.
  • Maa fọ ẹnu rẹ mọ deede.
  • Bi o ba ni Apollo, ma ṣe fi ọwọ ti ko mọ gbo oju rẹ.
  • Yago fun ẹni to ni arun naa titi ti alaafia yoo fi de.

Lakotan, Dr Ahmad ṣalaye pe bi awọn eeyan ba le mu imọtoto ni koko, paapaa awọn iyalọmọ to n tọju ọmọ ati ile, arun igba ojo yoo dinku jọjọ.