Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní mú aráàlú lórí ìwọ̀kuwọ̀ aṣọ, kí ni òfin sọ lórí èyí?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Delta ti kede lọjọ Abamẹta pe oun ṣetan bayii lati maa fi panpẹ ofin mu ẹnikẹni ti ko ba mura daadaa ni ipinlẹ naa.
Wọn ni igbesẹ yii fi ẹsẹ mulẹ labẹ abala ikẹrindinlogun ofin hihu iwa ipa si ọmọlakeji, 'Violence Against Persons Law, VAP ti wọn ṣe lọdun 2020.
Ileeṣ ọlọpaa ṣalaye loju opo X rẹ pe "Niwọn igba ti o ko fẹ wọ aṣọ to bo ihoho rẹ jade, ti o gba lati maa lọ si ibi iṣẹ, ile ẹkọ tabi ibikibi ninu aṣọ to ṣi ihoho ara rẹ silẹ, tẹti ki o gbọ _ijọba ipinlẹ Delta ko ni fi oju rere wo imura bẹẹ."
Atẹjade oju opo ayelujara naa tun sọ yekeyeke pe, "Ofin VAP ti ṣetan lati fi ijiya to ba tọ jẹ ẹnikẹni ti ko ba mura daadaa. Ijiya: iṣẹ isinlu tabi owo itanran ẹgbẹrun lọna aadọta Naira."
Ọrọ naa ti fa ọpọlọpọ awuyewuye laarin awọn ọmọ Naijiria, paapaajulọ awọn ti wọn ri I gẹgẹ bi titẹ ẹtọ ẹni mọlẹ, bẹẹni awọn eeyan kan pẹlu n kan saara si ofin ọhun.
Ileeṣẹ iroyin BBC News boju wo ọrọ naa, paapaa ofin VAP ti ileeṣẹ ọlọpaa tọka si ni ipinlẹ naa.
Ohunti iwadi fihan ni pe ihuwa kotọ nipa ọrọ eto iṣuna lo wa ninu abala ikẹrindinlogun ti ileeṣẹ ọlọpaa tọka sin aa.
Awọn abala mẹrẹẹrin to wa labẹ abala naa sọwi pe:
- Ẹnikẹni to ba hu iwa kotọ nipa ọrọ iṣuna si ẹlomiran le lọ si ẹwọn ọdun mẹta tabi san owo itanran ti ko le ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira, tabi ko fi mejeeji jura.
- Ẹnikẹni to ba gbiyanju latihu iwa ọdaran to wa ni abala ikinni ofin yii le fi ẹwọn ọdun kan ati oṣu mẹfa jura tabi san owo itanran ẹgbẹrun lọna igba Naira, tabi mejeeji.
- Ẹnikẹni to ba ti eniyan lati hu iwa ọdaran yii tabi ṣe agbodegba fun ẹlomiran lati hu iwa ọdaran yii le e fi ẹwọn ọdun kan abọ tabi owo itanran ti ko ni ju ẹgbẹrun lọna igba Naira lọ jura.
- Abala ikẹrindinlogun ofin ti ileeṣẹ ọlọpaa n tọka sin aa ko fi ibi kankan mẹnu ba ọrọ iwọkuwọ aṣọ rara
Wiwọ aṣọ to ṣi ihoho ara silẹ
Ko si nnkan to jọ mọ iwọkuwọ aṣọ ni abala ikẹrindinlogun ofin VAP ni ipinlẹ Delta amọṣa abala ikọkandinlọgbọn rẹ sọ ọrọ nipa iwọkuwọ aṣọ to n fi ihoho ara silẹ ati ijiya to yẹ fun ẹnikẹni to ba ṣi ihoho ara rẹ silẹ ni ita gbangba yoo fara gba.
Ohun ti abala naa sọ niwọnyii:
- Ẹnikẹni to ba mọọmọ ṣi ihoho ara rẹ sita, yala diẹ tabi lọpọlọpọ ti jbi ẹsun iwọkuwọ aṣọ to fi ihoho ara ẹni sita.
- Ẹnikẹni to ba jẹbi ẹsun yii yoo lọ fi iṣẹ itọju ilu gbara tabi san owo itanran ti ko ni ju ẹgbẹrun lọna aadọta Naira, N50, 000 jura.
Eyi ni ijiya ti ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Delta tọka si fun igbesẹ ti wọn fẹ gbe naa.














