'Iṣẹ́ ni mo wá á ṣe ní Naijiria tí mo fi pàdé ọkọ mi tó jẹ́ ọmọ Yorùbá, mi ò sì kábàámọ̀'
Yoruba bọ, wọn ni ọrọ ifẹ laaye bi adanwo ni, ati pe irinajo ifẹ ma n yani lẹnu pupọ.
Bẹẹ lo jẹ fun Victor Babatunde Yamuso, ọmọ orilẹede Naijiria to pade Eunyhe Ju, ọmọbibi orilẹede South Korea, to si fi ṣe aya.
Ileeṣẹ BBC Yoruba ṣebẹwọ si tọkọtaya yii lati mọ nipa irinajo wọn ati erongba wọn fun ọjọ iwaju.
Yamuso, nigba to n ba BBC sọrọ ni, ọpọ eeyan lo ro pe onijibiti ni oun nitori oun fẹ ọmọ orilẹede South Korea.
O ni awọn mọlẹbi oun ko fi bẹ sọrọ nipa pe ki oun ma fẹ obinrin naa nitori pe iyawo oun naa jẹ obinrin to dara pupọ to si ni ẹran ifẹ lara.
"Alafẹfẹyẹyẹ eeyan ni iyawo mi, awọn obi mi fẹran rẹ, wọn si gba a wọle.
"Ọpọlọpọ awọn eeyan lo sọ ọrọ odi si mi nita, ọpọlọpọ ma n ro pe ti wọn ba ti ri alawọ dudu ati obinrin alawọ funfun, wọn ti ro pe o fẹ lo ni, o fẹ fi gba iwe ni, o fẹ fi salọ ni.
"Koda wọn ma n ni boya mo n ṣe isẹ gbajuẹ ti wọn pe ni Yahoo-Yahoo, ti iyawo mi si jẹ onibaara mi lori ayelujara ."
Bawo ni wọn ṣe bẹrẹ irinajo ifẹ wọn?

Oríṣun àwòrán, @victorandrenee/Instagram
Iṣẹ lo gbe Eunyhe Ju wa si orilẹede Naijiria, to gba ibẹ pade ololufẹ rẹ, Victor Yamuso.
Ọjọ kinni oṣu Kẹwaa, nibi ayẹyẹ ajayọ ominira orilẹede Naijiria ni awọn mejeeji ti pade ara wọn niluu Eko.
Ju ṣalaye pe ibi ọrẹ ni Yamuso ti bẹrẹ si ni mu si oun lara, ko to di pe ifẹ bẹrẹ si ni ma pa a bi ọti, to si tun ja si igbeyawo fun awọn mejeeji.
"Lati igba ti mo ti bẹrẹ si i fẹ ọkọ mi, ọmọ Yoruba, ni mo ti n kọ bi wọn ṣe n ṣe ounjẹ orisirisi to jẹ ti Yoruba.
"Ni bayii, mo le gun iyan, mo le ro semo ati amala, mo n ṣe orisirisi ọbẹ pẹlu ẹpo ati ororo."
Yamuso ni pe oun ko fi igba kankan ri ara oun gẹgẹ bii ọkunrin to le wa ninu ajọsepọ pẹlu obinrin ti ki se ẹya tabi elede rẹ.
"N ko ri ara mi ni iri ẹni to le wa ninu ajọsepọ pẹlu ẹni to yatọ si ede mi tabi aṣa wa yatọ patapata.
"Awọn ohun ti mo dẹ ri ni ara rẹ jẹ ohun ti mo fi tẹra mọ ọ pe, ọmọ obinrin yii ni mo gbọdọ fẹ ni wi pe, o da yatọ laarin gbogbo awọn alawọ funfun ti mo ti ba pada nibi ti mo ti n siṣẹ.
"O jẹ eeyan to jẹ pe o nifẹ aṣa ati ede wa."
"Suuru ti ọkọ mi ni jẹ ohun ti mo fi fẹran pupọ"

Oríṣun àwòrán, @victorandrenee/Instagram
Eunyhe Ju ni ohun ti oun fẹran lara ọkọ oun ni suuru, bo ti lẹ jẹ pe ko tẹ awọn obi rẹ lọrun pe oun wa si orilẹede Naijiria lati wa sisẹ, tun wa lọkọ lati ibẹ.
"Wiwa si orilẹede Naijiria fun isẹ ko tẹ awọn obi mi lọrun, ka to wa sọ pe mo fẹ ọmọ Yoruba.
"Mo tun wa pinnu pe ma gbe ni Naijiria, wọn ko fara mọ rara, ṣugbọn gbogbo nnkan ti emi ati ọkọ mi n ṣe lori ayelujara ni a n fi ransẹ si wọn.
"Ni bayii, awọn mọlẹbi mii fẹran nnkan ti emi ati ọkọ n se papọ."






