Kò sógun mọ́, kò sí ọ̀tẹ̀ mọ́! Ẹ wo bí Wike àti Gómìnà Fubara ṣe parí ìjà wọn l'Abuja

Siminalayi Fubara, Aarẹ Tinubu ati Wike

Oríṣun àwòrán, Nigeria Presidency

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

"Ija dopin, ogun si tan'' ni ọrọ to gba ẹnu Minisita fun olu ilu Naijiria, Nyesom Wike, lẹyin ipade alaafia to waye laaarin rẹ pẹlu gomina Rivers tẹlẹ, Siminalayi Fubara, eyi ti Aarẹ Tinubu wa nibẹ pẹlu.

Ile ijọba, Aso Rock niluu Abuja ni ipade ọhun ti waye lalẹ Ọjọbọ, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹfa ọdun 2025.

Awọn aworan ọlọkan-o-jọkan to n ṣafihan Wike ati Fubara nibi ti wọn ti n bọ ara wọn lọwọ pẹlu ẹrin lo gba ori ayelujara kan.

Bakan naa ni awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin Rivers ati Aarẹ Tinubu ko gbẹyin ninu awọn fọto naa.

Eyi jẹ ki ọpọ eeyan maa nigbagbọ pe o ṣee ṣe ki opin de ba ijọba pajawiri to n lọ lọwọ nipinlẹ Rivers, ti Fubara yoo si gba ipo rẹ pada.

Ipade naa ti Abẹnugan ipinlẹ Rivers naa wa nibẹ, iyẹn Martins Amaewhule, ni iroyin sọ pe o waye lati ba Aarẹ Tinubu sọrọ nipa bi Fubara yoo ṣe maa ba ijọba rẹ lọ.

Ẹ o ranti pe rogbodiyan oṣelu to bẹ silẹ ni Rivers, paapaa laaarin Wike ati Fubara, lo fa a ti Aarẹ fi kede ilu o fararọ nibẹ.

Ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta ọdun 2025 ni Aarẹ Tinubu juwe ile fun Fubara, to fi Ajagunfẹyinti Vice Admiral Ibok-Ete Ekwe ṣe adari ipinlẹ Rivers.

Gẹgẹ bi Wike ṣe wi lẹyin ipade yii, o ni oun ti ṣetan lati ṣiṣẹ pẹlu Fubara, Fubara pẹlu si ti ṣetan lati ṣiṣẹ pẹlu oun.

Wike sọ pe aigbọraẹni ye lo waye, ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan naa ni awọn. O lawọn ti pada bayii ni awọn ṣe waa ba Aarẹ Tinubu.

Ninu ọrọ Fubara, gomina ti wọn ni ko lọọ sinmi na, o ni inu oun dun pẹlu ipade yii.

Fubara ṣalaye pe eyi fi han pe alaafia yoo pada jọba ni Rivers, awọn yoo si ri i pe ọrẹ tawọn bẹrẹ yii ko ni i pada di ọta mọ.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ ìṣáájú?

Aarẹ, Wike, Fubara ati awọn eeyan ile igbimọ aṣofin Rivers

Oríṣun àwòrán, Nigeria Presidency

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bii baba ati ọmọ ni Nyesom Wike ati Siminalayi Fubara ri tẹlẹ, ko too di pe ọrọ oṣelu da wahala silẹ laaarin wọn.

Lara awọn ohun to fa rogbodiyan naa ree:

Igbẹsẹ awọn aṣofin lati yọ gomina Fubara nipo, eyi to waye loṣu Kẹwaa ọdun 2023.

Awọn kan wa lẹyin Fubara, ṣugbọn ọpọ lo tẹlẹ Wike to wa lẹyin iyọnipo naa.

Wọn dana sun ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Rivers, wọn ba awọn apa kan ibẹ jẹ, bẹẹ ni awọn kan n kuro ni PDP lọ si APC, bo tilẹ jẹ pe wọn pada sọ pe awọn ko fi ẹgbẹ silẹ.

Ẹjọ ọlọkan-o-jọkan ni kootu, ti ile ẹjọ si sọ pe Martin Amaewhule loun mọ ni Abẹnugan ile igbimọ aṣofin Rivers. To fagile ibo ijọba ibilẹ ti gomina Fubara ṣe.

Ile ẹjọ to ga julọ paṣẹ pe ki Fubara tun aba iṣuna 2025 rẹ gbe kalẹ lọdọ Amaewhule.

Ṣugbọn wọn ko ti i fẹnuko lori eyi ti Aarẹ Tinubu fi ni ki Fubara fipo silẹ, lọjọ kejidinlogun oṣu Kẹta, 2025.

Aarẹ da awọn eeyan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa duro pẹlu, o si kede ilu o fararọ.

Ọpọ eeyan lo koro oju si iyansipo Ajagunfẹyinti Vice Admiral Ibok-Ete Ekwe Ibas, ọmọ ipinlẹ Cross River, ti ijọba ni ko maa tukọ Rivers lọ.

*Iyansipo awọn alabojuto ijọba ibilẹ mẹtalelogun nipinlẹ Rivers, tun da aroye silẹ.

Ọpọ eeyan lo n sọ pe eyi fi sibi kan, ati pe ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo lo n jẹ anfaani rẹ.

*Ibuwọ lu ọmọ ipinlẹ Cross River mi-in, Micheal Ekpai lati dari eto idibo ijọba ibilẹ Rivers naa si n fa awuyewuye.

Ṣugbọn boya ọrẹ ti Wike ati Fubara ni awọn yoo bẹrẹ pada yii yoo mu ayipada rere wa laipẹ ni ẹnikẹni ko ti mọ.

Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn ẹjọ to wa ni kootu lori ọrọ Wike ati Fubara yii?

Ati ijọba alabojuto ti Vice Admiral Ibok-Ete Ekwe Ibas n ṣe lọwọ?

*Iyansipo awọn alabojuto ijọba ibilẹ mẹtalelogun nipinlẹ Rivers, tun da aroye silẹ.

Ọpọ eeyan lo n sọ pe eyi fi sibi kan, ati pe ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo lo n jẹ anfaani rẹ.

*Ibuwọ lu ọmọ ipinlẹ Cross River mi-in, Micheal Ekpai lati dari eto idibo ijọba ibilẹ Rivers naa si n fa awuyewuye.

Ṣugbọn boya ọrẹ ti Wike ati Fubara ni awọn yoo bẹrẹ pada yii yoo mu ayipada rere wa laipẹ ni ẹnikẹni ko ti mọ.

Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn ẹjọ to wa ni kootu lori ọrọ Wike ati Fubara yii?

Ati ijọba alabojuto ti Vice Admiral Ibok-Ete Ekwe Ibas n ṣe lọwọ?