Mọ̀ nípa òfin owó orí tuntun tí Ààrẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ buwọ́lu àti bí ó ṣe kàn ọ́

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency
Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu ti buwọ́lu àbá tuntun lórí owó di òfin èyí túmọ̀ sí ìlànà owó orí tuntun fún Nàìjíríà.
Láti ọdún tó kọjá ni ọ̀rọ̀ owó orí tuntun náà ti ń fa awuyewuye láàárín àwọn èèkàn ìlú pàápàá láti ẹkùn àríwá Nàìjíríà.
Ṣáájú ni ilé aṣòfin àpapọ̀ ti buwọ́lu àbá owó orí náà lẹ́yìn ìfaǹfà tó wáyé láàárín àwọn aṣòfin ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìlànà owó orí náà.
Kódà àwọn gómìnà kan tako ìgbésẹ̀ ìlànà owó orí tuntun yìí ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpàdé pẹ̀lú ìgbìmọ̀ owó orí tuntun náà, wọ́n padà faramọ́ ìgbésẹ̀ náà.
Èyí ni àwọn òfin tuntun lórí owó orí náà:
- Nigeria Tax Bill
- Nigeria Tax Administration Bill
- Nigeria Revenue Service (Establishment)
- Joint Revenue Board (Establishment)
Nínú àwọn owó orí mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí, èyí tó kan ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Nàìjíríà ni àkọ́kọ́ ìyẹn Nigeria Tax Bill.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ owó orí náà fi léde lọ́jọ́bọ̀, wọ́n ní ìlànà tuntun yìí yóò jẹ́ kí gbogbo àwọn tó lẹ́tọ̀ọ́ láti máa san owó láti máa san owó wọn ní ìlànà tó tọ́.
Bákan náà ni agbẹnusọ Bola Tinubu, Bayo Onanuga nínú àtẹ̀jáde tó fi sórí ìkànnì X rẹ̀ ṣàlàyé pé ìgbésẹ̀ tuntun yìí yóò mú àdínkù bá sísan owó orí lọ́nà púpọ̀ fún èèyàn kan àti pé yóò mú ìlànà òwò ṣíṣe rọrùn sí i.
Èyí ni àwọn kókó inú òfin tuntun náà

Oríṣun àwòrán, Taiwo Oyedele/X
Lára ohun tó wà nínú àbá owó orí tuntun yìí ni pé àwọn tí owó tó ń wọlé fún wọn ní ọdún kan kò bá ti pé mílíọ̀nù kan náírà kò ní máa san owó orí mọ́ lórí owó tó ń wọlé fún wọn.
- Àwọn tí owó tó ń wọlé fún wọn bá wà ní N2,200,000 yóò máa san ìdá mẹ́ẹ̀dógún (15%) gẹ́gẹ́ bí owó orí.
- Nígbà tí àwọn tí owó tó ń wọlé fún wọn bá wà ní N9,000,000 yóò máa san ìdá méjìdínógún (18%) gẹ́gẹ́ bí owó orí.
- Bákan náà àwọn tí owó tó ń wọlé fún wọn bá wà ní N13,000,000 yóò máa san ìdá mọ́kànlélógún (21%) gẹ́gẹ́ bí owó orí.
- Ìdá mẹ́tàlélógún (23%) ni àwọn tí owó tó ń wọlé fún wọn bá wà ní N25,000,000 yóò máa san.
- Àwọn tí owó tó ń wọlé fún wọn bá ti wọ N50,000,000 lọ sókè ni yóò máa san ìdá márùndínlọ́gbọ̀n (25%).
Ṣáájú àsìkò yìí, ó tó ìdá méje táwọn èèyàn tí wọn kò gbà tó N300,000 lọ́dún ń san gẹ́gẹ́ bí owó orí.
Lára awọn nǹkan míì tí òfin owó orí tuntun yìí tún dá lé ni:
- Àwọn iléeṣẹ́ kéréje tí owó tí wọ́n fi ń ṣe okoòwò lọ́dún kò wọ àádọ́ta mílíọ̀nù Náírà (N50,000,000) kò ní máa san owó orí fún iléeṣẹ́ wọn mọ́.
- Ìdá ọgbọ̀n (30%) ni owó orí táwọn iléeṣẹ́ yóò máa san láti àsìkò yìí.
- Owó tó bá wọlé fún èèyàn gẹ́gẹ́ bí owó gbà mábínú bóyá nígbà tó bá pàdánù iṣẹ́ tàbí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ tí kò bá ti ju àádọ́ta mílíọ̀nù Náírà (N50,000,000), wọn kò ní yọ owó orí lórí rẹ̀.
- Ìdá 7.5% ni owó orí VAT
- Àwọn tí owó tó ń wọlé fún wọn kéré kò ní máa san owó orí lórí ilé ìgbé, ọkọ̀ tàbí iná mọ́.
Àwọn àtúntò míì tí òfin náà gbé kalẹ̀ ni:
- Àjọ Federal Inland Revenue Service ti yípadà di National Revenue Service nígbà tí Jpoint Revenue Board ti rọ́pọ̀ Joint Tax Board.
- Owó VAT táwọn ìjọba máa ń pin ni oṣooṣù ti di ìdá àádọ́ta (50%) fáwọn ìpínlẹ̀, ìdá márùndínlógójì (35%) fáwọn ìjọba ìbílẹ̀ nígbà tí ìjọba àpapọ̀ yóò máa gba ìdá mẹ́ẹ̀dógún (15%).














