Makinde fẹ́ ṣí ibùdó ìkàwé sí pápákọ̀ òfurufú n'Ibadan, Aláàfin yóò kọ́ ibùdó àṣà sí ìlú Oyo

Gomina Makinde àtàwọn èèkàn ìlú ni ìpínlẹ̀ Oyo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina ìpínlẹ̀ Oyo, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde tí kéde pé àwọn ibùdó igbafẹ to wá ní ìpínlẹ̀ Oyo yóò wà ní arọwọto gbogbo èèyàn báyìí.

Gomina Makinde ṣe ìkéde yìí lásìkò to ń ṣe ifilọlẹ ìwé kan tí wọn pé ní "Mọ si nipa ìpínlẹ̀ Oyo" èyí tí Kọmisana feto ìròyìn, ọmọọba Dotun Oyelade kọ.

Gbọ̀ngàn Theophilus Ogunlesi to WA ni ìdojúkọ ọgbà ilé ìwòsàn UCH n'ilu Ibadan ni eto ifilọlẹ ìwé náà tí wáyé.

Arapaja, Oyelade àti Makinde

Gomina Makinde ṣàlàyé pé gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́, olùgbé ìpínlẹ̀ Oyo àtàwọn àlejò ni yóò mọ ohun tí ìpínlẹ̀ náà jẹ báyìí nípa àṣà, ìṣe àti iselu.

"Yàtọ̀ sí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò ní anfaani sì imọ nípa ìpínlẹ̀ Oyo, àwọn arìnrìn-àjò afẹ gan yóò mọ si nipa àwọn ibùdó igbafẹ to wá ní Ìpínlẹ̀ Oyo.

Bákan náà, tí àtúnṣe papakọ ofurufu Ladoke Akintola to wá ní Alakia nilu Ibadan bá parí tán, máa sì ibùdó iyawe-kawe kan sibẹ èyí tí yóò fún àwọn àlejò to bá wọ baalu wá sí ìpínlẹ̀ Oyo ni anfaani láti kọ́kọ́ ni imọ nípa ìpínlẹ̀ tí wọ́n wa."

Gomina Makinde tẹsiwaju pe eto ọgbin ni ohun gbajúmọ̀ ni ṣáá àkọ́kọ́ isejọba òun and eto irinajo afẹ ni oun gbajumọ ni saa kejì yìí.

Gomina ni ó ṣe pàtàkì kí gbogbo èèyàn mọ̀ ohun tí ìpínlẹ̀ Oyo dúró fún ati ibi tó ń lọ ní ọjọ́ ọ̀la.

Alaafin Owoade joko laarin awọn ẹmẹ̀wà rẹ

Nígbà tí òun náà ń sọrọ, Alaafin tí ìlú Oyo, Ọba Abimbola Akeem Owoade ṣàlàyé pé imọ nípa ìpínlẹ̀ Oyo jẹ pepele ìpìlẹ̀ fún atungbekalẹ imọ kíkún fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́.

Ọba Owoade ni ìwé imọ naa ni yoo maa rán gbogbo èèyàn létí nípa irú èèyàn ti a jẹ ní ìpínlẹ̀ Oyo ati ibi tí a ti wá èyí tí ó gbọdọ jẹ manìgbàgbé fún ìran yìí àti ọpọlọpọ ìran to ń bọ.

"Mọ tí ń gbé ro láti kọ ibùdó àṣà fún ìlú ńlá Oyo. Igbesẹ yìí sí wa ni ibamu pẹlu ohun tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ń ṣẹ loni."

Àwọn eeyan jàǹkàn-jàǹkàn to wá níbi ayẹyẹ naa

Lára àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn míì to peju síbi eto naa ni Gomina ológun nígbà kan rí ni ìpínlẹ̀ Oyo, Oladayo Popoola, Oloye

Mutiat Ladoja, àwọn méjì tó jẹ́ igbakeji gomina tẹ́lẹ̀, Taofeek Arapaja àti Azeem Gbolarumi.

Bákan nàá ni Soun tilẹ̀ Ogbomoso, Okere tí Saki àti Olugbon tí Orile Igbon ko gbẹyin níbi ayẹyẹ náà.