Ohun tó yẹ kí o mọ́ nípa pàtàkì ọdún Hijrah tí àwọn Mùsùlùmí ń ṣe lónìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ipinlẹ mẹjọ lorilẹede Naijiria lo kede ọjọ kọkandinlogun oṣu keje gẹgẹ bii ayajọ ọdun Hijah.
Kano, Oyo, Osun, Sokoto, Zamfara, Bauchi, Kebbi ati Jigawa kede ọjọ ìsinmi fun awọn osisẹ fun ayẹyẹ ọdun Hijah 1445.
Iyatọ to wa laarin ọdun musulumi yii ati ọdun yooku ni pe wọn ko kii ṣe e papọ pẹlu awọn yooku ati pe orukọ wọn yatọ.
Lorilẹede Naijiria, Sultan ti ilu Sokoto ke si awọn musulumi pe ki wọn maa foju sona fun oṣu ọdun Muharram 1445 lẹyin Hijirah.
"Riri oṣu Muharram tumọ ipari ọdun 1444, ti ọdun miiran 1445 si ti bẹrẹ."
Ki ni a n pe ni Ọdun Musulumi ati pe ki ni pataki rẹ.
Ọdun Hijirah ti wa ṣaaju ki wọn to Anọbi Muhammad (SAW) ṣugbọn wọn ko lo awọn oṣu lasiko naa.
Awọn oṣu ọdun musulumi ni wọn bẹrẹ si ni maa lo lẹyin ti Anọbi gbera kuro lati ilu Mecca lọ Medina niluu Saudi Arabia.
Idi ree ti wọn pe ọdun to pari 1442 AH (AH tumọ si ọdun 1442 lẹyin ti Anọbi rin irinajo).
Osupa wiwo ni ẹṣin Islam fi n wo asiko, ko si nkankan ninu awọn oṣu musulumi ti ọjọ rẹ pe bii ti ọdun Gregorian.
Ni ọpọ igba, ọjọ mọkanla maa n wa laarin ọdun meji ninu bí o ṣe kere.
Awọn musulumi maa n ṣe àjọyọ irinajo Anọbi Muhammad (PBUH) lati Makkah lọ Medina.
O ṣe koko fun awọn musulumi nitori o n jẹ ki wọn ní oye sii nípa Ibẹrẹ ẹṣin Islam ati bi o ṣe di ọkan gboogi.
Lọjọ kini Muharram, awọn ko ni ọjọ kan fun ijọsin ṣugbọn o duro gẹgẹ asiko lati irinajo Anọbi ati ilakọja rẹ.
Gbogbo Musulumi ni wọn ma n rọ lati gba awẹ ati adura lọjọ kini ọdun.
Oṣu melo lo wa ninu ọdun Musulumi?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Muharram
Eyi tumọ si 'Ewọ' ni ede Larubawa nitori ninu osu yii ni awọn Lalubawa maa yago fun ija, isekupani ati awọn ija miiran. Eyi osu akọkọ.
Safar
Eyi ni oṣu kejì, to si jẹ oṣu ti awọn Larubawa ma n gbe ogun ja awọn ìlu miiran.
Rabi-Al Awwal
Eyi ni oṣu kẹta, to si tumọ si Ibẹrẹ nítorí orúkọ ọhun lo bẹrẹ.
Rabi- Al Akir
Eyi tumọ si ipari gẹgẹ bí ti tẹlẹ ṣe jẹ Ibẹrẹ. Awọn miiran maa n pe e ni oṣu Rabi Al Thani.
Jumada - Al Ula
Oṣu yii ni wọn fi sori asiko ti ilẹ gbẹ.
Jumada Al Akhirah
Osu yii ni idakeji oṣu Jumada Al Ula to tumọ si asiko ti ilẹ ko gbẹ mọ.
Rajab
Eyi tumọ si oṣu ọwọ ati iyì. Asiko yii awọn Lalubawa ko ki n ja.
Sha'aban
Eyi ni oṣu kẹjọ.
Ramadan
Oṣu yii lo gbajumọ ju, koda awọn ti kí ṣe Musulumi mọ nípa rẹ nitori o jẹ asiko ti awọn musulumi ma n gba awẹ.
Shawwal
Oṣu yii ri orúkọ rẹ nitori ibasepọ to wa laarin awọn Larubawa ati ẹranko rakunmi. Ninu oṣu yii ni awon rakunmi ko ki n rí wara mu.
Dhul Qiddah
Oṣu tí ogun pari.
Dhul Hijjah
Oṣu yii ni oṣu Hajj sise fun awọn musulumi.
Ohun to yẹ ko mọ nípa oṣu Muharram

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Oṣu Muharram ni oṣu akọkọ, ti wọn si tun ma pe ni oṣu Al Hijiri
- Ọjọ mọkandinlọgbọn ati ọgbọn ọjọ lo wa ninu oṣu yii
- Awọn Musulumi gbọdọ gba awẹ lọjọ kẹsan an ati ikẹwaa oṣu yii ti wọn n pe ni Tashua ati Ashurah.
- Oṣu yii da lori irinajo Anọbi Muhammad (SAW) lati Mecca lọ Medina
- Oṣu jẹ oṣu iranti fun gbogbo ìlà kọja awọn Musulumi fun ẹṣin Islam.
- Oṣu yii kọ awọn Musulumi ni igboya ati jija fun idajọ òdodo.
- Oṣu Ewọ ni oṣu Al Muharram ti awọn musulumi yoo si yago fun ayẹyẹ lati le ṣe apọnle fun Imam Hussain.












