Owó epo rọ̀bì já wálẹ̀ lẹ́yìn tí Israel àti Iran gbà láti dáwọ́ ogun dúró

Tanker on the sea in the Middle East

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Dearbail Jordan
    • Role, Business reporter, BBC News
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù Kẹfà ọdún 2025 ni àdínkù bá iye tí wọ́n ń ta epo rọ̀bì lọ́jà àgbáyé pẹ̀lú ìdá márùn-ún (5%) lẹ́yìn tí Israel àti Iran gbà láti dáwọ́ ogun dúró.

Epo rọ̀bì "Brent Crude" tó jẹ́ epo rọ̀bì tí wọ́n fi ń ṣe gbèdéke epo rọ̀bì ní ọjà àgbáyé já wálẹ̀ sí dọ́là mẹ́tàdínláàádọ́rin ($67) fún àgbá kan nígbà tí ó fi máa di ìparí ọjọ́ náà ṣùgbọ́n tó tún ló sókè díẹ̀ nígbà tí àwọn orílẹ̀ èdè méjéèjì tún ń ju òkò ọ̀rọ̀ lu ara wọn.

Láti ìgbà tí ogun ti bẹ̀rẹ̀ láàárín orílẹ̀ èdè Israel àti Iran ni owó epo rọ̀bì ti gbẹ́nu sókè bí ìbẹ̀rùbojo ṣe gbilẹ̀ pé ó ṣeéṣe kí Iran gbégi dínà odò Strait of Hormuz, odò tó ṣe kókó tí wọ́n ń gbé epo rọ̀bì àti afẹ́fẹ́ gáàsì gbà.

Níṣe ni ọjà àgbáyé ní US, UK àti Yúróòpù lọ sókè, tí wọ́n sì wà lójú kan lẹ́yìn tí Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump sọ fún Israel lórí ayélujára pé wọn kò gbọdọ̀ ju àdó olóró mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé Iran kò tẹ́lẹ̀ àdéhùn dídáwọ́ ogun dúrò tí wọ́n fẹnukò lé lórí.

Ṣáájú ni owó epo rọ̀bì ti gbẹ́nu sókè di dọ́là mọ́kànlélọ́gọ́rin ($81) fún àgbá kan láti ìgbà tí ogun ti ń wáyé láàárín orílẹ̀ èdè méjéèjì, èyí tó ti ń dá ìbẹ̀rù sọ́kàn àwọn èèyàn pé ó ṣeéṣe kí owó epo bẹntiróòlù, dísù, àtàwọn ọjà míì lọ sókè.

Ní báyìí, $67.68 ni wọ́n ń ta àgbá epo rọ̀bì lọ́jà àgbáyé, iye tó jẹ́ àdínkù sí iye tí owó epo wà kí Israel tó ṣe ìkọlù sí Iran lọ́jọ́ Kẹtàlá, oṣù Kẹfà.

"Tí wọ́n bá dáwọ́ ogun dúró gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe kéde, àwọn olùdókoòwò ní ìrètí pé ohun gbogbo máa padà sípò lẹ́ka epo rọ̀bì ," Priyanka Sachdeva, onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé àgbáyé ní Phillip Nova sọ.

Ó fi kun pé bí Israel àti Iran bá ṣe dáhùn sí ìfẹnùkò lórí ìdádúró ogun máa nípa gidi lórí iye tí epo rọ̀bì máa jẹ́.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bí owó epo ṣe ń já wálẹ̀ rí àdínkù bí Israel ṣe fẹ̀sùn kàn pé Iran kò tẹ̀lé àdéhùn dídáwọ́ ogun dúró náà lọ́nà tó yẹ pé wọ́n ṣì ju àdó olóró lẹ́yìn ìfẹnùkò náà.

Ọjá àgbáyé lọ sókè si, bí iléeṣẹ́ S&P 500, Dow Jones Industries Average àti Nasdaq ṣe lọ sókè pẹ̀lú ìdá kan (1%).

Ní Nàìjíríà, láti bíi ọjọ́ méjì báyìí ni alékún ti bá owó epo bẹntiróòlù látàrí bí owó epo rọ̀bì ṣe ti gbẹ́nu sókè lọ́jà àgbáyé.

Ogun tó ń wáyé lẹ́kùn Middle East ti mú kí owó epo àtàwọn ohun àmúṣagbára lọ sókè si léyìí tó jẹ́ pé tó bá tẹ̀síwájú, ó le nípa lórí iye bẹntiróòlù káàkiri àgbáyé.

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni iye tí wọ́n ń ta afẹ́fẹ́ gáàsì ní UK rí ìjáwálẹ̀ pẹ̀lú ìdá mẹ́tàdínlógún (17%) lẹ́yìn tó ti lọ sókè ṣáájú lọ́jọ́ náà. Qatar jẹ́ orílẹ̀ èdè tó ní afẹ́fẹ́ gáàsì tó pọ̀ èyí tí wọ́n máa ń gbé gba orí omi Strait of Hormuz.

Ní ọjọ́ Ajé ni Iran ju àdó olóró sí iléeṣẹ́ ológun Amẹ́ríkà tó wà ní Qatar láti gbẹ̀san ìkọlù tí Amẹ́ríkà ṣe sáwọn iléeṣẹ́ ìpèsè ohun ìjà olórí rẹ̀.

Àlékún tó bá owó epo ti ń nú kí ìbẹ̀rù máa wà pé ó le ṣokùnfà kí ọ̀wọ́ngógó wà lórí epo bẹntiróòlù, oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì káàkiri àgbáyé.

Irúfẹ́ nǹkan báyìí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Russia ṣe ìkọlù sí Ukraine lọ́dún mẹ́ta sẹ́yìn, èyí tó ní ipa lórí ìgbé ayé àwọn èèyàn káàkiri àgbáyé.