Ẹ wo fídíò àsìkò tí Iran kọlu ibùdó ológun America ní Qatar
Iran ju ado oloro si ibudo ologun Amẹrika to wa ni Qatar, eyi ti Iran ni oun fi gbẹsan ikọlu Amẹrika to ṣe lopin ọsẹ to kọja si ibudo iko nnkan ija oloro si wọn.
Ọpọ olugbe Doha ti i ṣe olu ilu Qatar sọ pe awọn gbọ iro nla loju ọrun.
Bakan naa ni oriṣiiriṣii fidio ṣafihan bi ina ṣe n kọ yanran yanran loju ọrun nigba ti ileeṣẹ ologun n gbiyanju lati dena awọn ado oloro ti Iran ju.

Oríṣun àwòrán, USAF
Idi ti Iran fi ju ado oloro si ibudo ologun Amẹrika ni Qatar
Iran ṣe ikọlu si ibudo ologun Amẹrika to wa ni Al-Udeid ni Qatar lati gbẹsan bi Amẹrika ṣe ju ado oloro si ibudo mẹta iko nnkan ogun oloro si Iran lalẹ ọjọ Abamẹta ọsẹ to kọja.
Al-Udeid yii ni ẹka ileeṣẹ ọmogun Amẹrika to wa lẹkun Middle-East, koda, awọn ọmogun ilẹ Gẹẹsi naa maa n lọ ṣiṣẹ nibẹ.
Ileeṣẹ iroyin Iran lo kọkọ sọ nipa ikọlu yii ki awọn ologun naa to fi idi rẹ mulẹ.
IRGG to jẹ ẹka ileeṣẹ ọmogun Iran sọ ninu atẹjade kan to fi sita pe ''Iran ko ni ṣai gbẹsan lori ikọlu ti Amẹrika ṣe.
Ati pe awọn ibudo ologun Amẹrika ko lagbara rara, o rọrun lati ṣe ikọlu si wọn.''
Ṣaaju ni Amẹrika ti sọ fun Iran wi pe ko ma gbẹsan lẹyin to ju ado oloro si ibudo iko nnkan ija oloro rẹ si.
Amẹrika tun rọ awọn adari Iran wi pe ki wọn wa ọna ati yanju aawọ to wa laarin Iran ati Israel ni itubi inubi.
Oriṣiiriṣii iroyin lo jade lori iye ado oloro ti Iran ju si ibudo ologun Amẹrika ni Qatar.
Iran ni ado oloro mẹfa ni, Amerika ni mẹrinla ni, nigba ti ileeṣẹ iroyin Reuters jabọ pe Qatar ni ado oloro mọkandinlogun ni Iran yin eyi ti awọn ọmogun si dena gbogbo rẹ.
Ko si ẹni to ku tabi ṣeṣe ninu ikọlu ti Iran ṣe ọhun.
Ṣaaju ikọlu Iran ni Amẹrika ati orilẹede UK ti kilọ fawọn ọmọ ilu wọn to wa ni Qatar wi pe ki wọn ṣọra ṣe.
Ko din ni ẹgbẹrun mẹjọ ọmọ ilẹ Amẹrika to n gbe ni Qatar, ẹgbẹẹgbẹrun ọmọbibi ilẹ Gẹẹsi naa lo n gbe nibẹ.
Ọrọ to jade lẹyin ikọlu Iran ni Qatar

Oríṣun àwòrán, USAF
Awọn oṣisẹ ijọba Iran mẹta sọ fun New York Times pe Iran ti sọ fun ijọba Qatar ṣaaju wi pe oun yoo ṣe ikọlu ki awọn eeyan ma ba farapa ju.
Ninu ọrọ tiẹ lẹyin ikọlu ọhun, Aarẹ Donald Trump dupẹ lọwọ Iran lori bi o ti sọ ṣaaju wi pe oun yoo ju ado oloro.
Trump ni eyi ni ko jẹ ki ẹnikankan ku tabi farapa ninu ikọlu naa.
Aarẹ Amẹrika ni ''ofuutu fẹẹtẹ ni ikọlu naa'', ko si ọmo Amẹrika kankan to farapa, akoba diẹ ni ikọlu Iran ṣe.
Trump ni asiko ti to bayii lati wa alaafia lẹyin ti Iran ti ju ado oloro si Qatar.
















