Ìdí rèé tí ìjọba Ondo fi wó gbàgede ìrántí àwọn tó kú nínú ìkọlù ìlú Owo ọ́dún 2022

Oríṣun àwòrán, Olumide Owaduge/BBC
- Author, Olumide Owaduge
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Ijọba ipinlẹ Ondo ti bẹrẹ si n wo gbagede iranti ti ijọba kọ ni iranti awọn to padanu ẹmi wọn sinu ikọlu to waye ninu ijọ St Francis Catholic Church, to wa ladugbo Owalua, niluu Owo lọdun 2022.
Iṣejọba gomina tẹlẹ, oloogbe Rotimi Akeredolu, lo kọ gbagede naa.
Ọjọ karun un, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 ni ikọlu naa waye nibi ti eeyan to le ni ogoji – ninu eyii ti ọmọde atawọn obinrin wa – ti padanu ẹmi wọn.
Irọlẹ ọjọ Abamẹta, ọjọ kọkandinlelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2025 ni wọn bẹrẹ si n wo gbagede naa niluu Owo.
Oniruru ọrọ lo n jade lẹyin igbesẹ ijọba lati wo gbagede iranti ọhun - bi awọn kan ṣe n sọ pe ohun to tọ ni ijọba ipinlẹ Ondo ṣe, lawọn mii n sọ pe niṣe lo mọọmọ fẹ pa iranti awọn to ku ninu iṣẹlẹ naa rẹ.
Koda, awọn kan tilẹ sọ pe niṣe ni gomina to wa ni ijọba lasiko yii, Lucky Aiyedatiwa n fẹ pa gbogbo iṣẹ ti ọga rẹ to ti di oloogbe, Rotimi 'Aketi' Akeredolu ti ṣe silẹ rẹ. Amọ ṣee lootọ ni?
Eredi ree ti B BC Yoruba ṣabẹwo siluu Owo lati ṣewadii ohun to ṣẹlẹ gan-an.
Awa ni a sọ fun ijọba ko wo gbagede iranti naa – Olowo ilu Owo

Oríṣun àwòrán, Olumide Owaduge/BBC
Nigba ti BBC Yoruba kan si aafin Olowo ti ilu Owo, Ọba Gbadegesin Ogunoye kẹta, ohun ti a ba bọ ni pe aafin ati awọn ọmọ ilu lo ni ki wọn wo gbagede iranti naa nitori pe o tako aṣa ilu Owo.
Oloye Babalola Olaluwoye, to jẹ Oloye Imoran ti ilu Owo ati ọkan lara awọn igbimọ Oloye agba to n ṣiṣẹ pẹlu Kabiesi Olowo, sọ pe ilu gan-an lo ni ki wọn wo.
O ni "Ilu lo ni ki wọn wo. Ohun to ṣẹlẹ ni pe ko to di pe wọn kọ gbagede naa, a gbọ pe wọn fẹ kọ, a si lọ ba gomina ana, Rotimi Akeredolu pe a ko fẹ ki wọn kọ irufẹ nnkan bẹẹ si ibi to wa.
"Ninu aṣa wa, ọba kii ri ibi ti oku ba wa, ibi ti wọn ba sin oku si tabi ibi to ba farajọ oku. Aṣa naa ti wa lati nnnkan to le ni ẹgbẹrun kan ọdun kan sẹyin.
"A lọ ba gomina, a si sọ fun pe 'ọmọ Owo ni ẹ, pe irufẹ nnkan bẹẹ ko gbọdọ wa niwaju aafin'.
"A lọ ba gomina ana, ki a to sọrọ lo ti kọ jalẹ pe ṣebi awọn Mala lo maa n wa nibẹ, a ni eewọ ilu wa ni pe Kabiesei ko gbọdọ fi oju ri ibi ti nnkan oku ba wa."
Oloye ọhun sọ pe gomina Akeredolu kọ jalẹ lati gbọ alaye igbimọ Olowo, o si tẹsiwaju lati kọ gbagede iranti naa, koda o ni ṣe lo da bii igba ti wọn le awọn kuro niwaju gomina lọjọ naa lọhun.
O ni gbogbo akitiyan awọn lati ri daju pe ijọba ko kọ gbagede iranti si ibi ti Olowo yoo ti maa ri lojojumọ, ni Akeredolu kọti ọgbọin si, o si ṣe ifẹ inu rẹ lati kọ gbagede naa lodi si ifẹ awọn agbagba ilu Owo.

Oríṣun àwòrán, Olowo ilu Owo
Babalola Olaluwoye fi kun pe lẹyin naa lawọn gba si Akeredolu lẹnu, ti awọn si fẹnuko lati kan si gomina mii to ba gori alefa lẹyin Akeredolu lati wa ojutu si ọrọ naa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, kii ṣe iwaju ile ọba lo ẹ ki wọn kọ gbagede iranti awọn to ti ku si bi ko ṣe ọgba ile ijọsin ti iṣẹlẹ naa ti waye.
Ẹwẹ, ninu atẹjade kan ti Olowo ti Olowo funra rẹ fi lede loju opo Facebook rẹ, o ni aafin oun ni ẹbẹ ti lọ si ọdọ ijọba pe ki wọn wo gbagede iranti naa.
O ni lootọ ni aafin Olowo ko faramọ ki ijọba kọ gbagede ọhun siwaju aafin laati ibẹrẹ pẹpẹ amọ ijọba ana ṣe ifẹ inu rẹ.
BBC tun ba awọn araalu kan sọrọ, to fi mọ alaga awọn ọlọkada atawọn obinrin to n ta ọja ninu ọja Ọba ilu Owo, wọn ni awọn faramọ bi ijọba ṣe wo gbagede iranti ọhun.
"Gbagede naa ni awọn janduku ẹda n lo fi ṣiṣẹ ibi"

Oríṣun àwòrán, Other
Ẹlomiran ti a tun ba sọrọ, Obayoriju Jimi Abbass to jẹ ọkan lara awọn ọmọ ilu Owo to maa n lọ si aafin Olowo daadaa.
Ninu alaye rẹ, yatọ si pe ilu ko fọwọ si kikọ gbagede naa si ibi to wa, awọn kọlọrọsi ẹda kan ti n lo gbagede naa lati maa ṣiṣẹ ibi loru ọganjọ.
O ni "To ba ti di aago mẹjọ alẹ bayii, eeyan ko ni le gba ibẹ kọja mọ nitori ibẹ lawọn ọmọ kọlọrọsi kan n sun si, ti wọn ba ti ja foonu eeyan gba bayii, ibẹ ni wọn maa n sa pamọ si."
Ni ti iha ti ijọ le ko si igbesẹ naa, o ni ko yẹ ki ile ijọsin naa le binu pe wọn wo latari pe ko ni anfani kankan ti gbagede naa n ṣe fun ile ijọsin naa ati ilu lapapọ.
Inu wa ko dun bi wọn ṣe wo gbagede naa, a fẹ ki ijọba kọ omiran fun wa – Ijọ

Oríṣun àwòrán, Olumide Owaduge/BBC
BBC tun lọ sile ijọsin ti ọrọ naa kan lati ba alufaa rẹ sọrọ.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu alufaa Micheal Abugan o ni "inu ijọ ko dun rara, koda inu ijọ bajẹ si igbesẹ wiwo gbagede iranti naa.
"Gbagede iranti to wa ninu ọgba ijọ, awa funra wa la kọ, kii ṣe ijọba lo kọ fun wa.

Oríṣun àwòrán, Olumide Owaduge/BBC
"A ko fẹ ki wọn kan wo gbagede iranti naa danu ki wọn si gbagbe nipa awọn eeyan to padanu ẹmi wọn sinu ikọlu naa bẹẹ, a fẹ ki ijọba kọ gbagede iranti mii fun wa ni agbegbe mii, inu wa yoo dun.
"Ko ṣe itẹwọgba fun wa ki ijọba kan pa orukọ awọn eeyan to ku nibi iṣẹlẹ naa rẹ bayẹn."
Ọkan lara awọn ọmọ ijọna naa to padanu iya rẹ sinu ikọlu naa to kọkọ n wa ẹkun mu ṣaaju sọ fun wa pe inu oun ko dun bi ijọba ṣe wo gbagede iranti.
Ọdọnbinrin ọhun ti ko fẹ ki a fi orukọ oun lede sọ pe "kii ṣe ohun to bujumu.
Aafin Olowo lo ni ki a wo gbagede iranti naa, ijọba yoo kọ omiran – Ijọba ipinlẹ Ondo
Nigba ti a kan si ijọba ipinlẹ Ondo, agbẹnusọ gomina, iyẹn Ọmọba Ebenezer Adeniyan sọ fidi rẹ mulẹ pe lootọ aafin Olowo lo ni ki ijọba wo gbagede naa, ati pe ijọba ko da iṣẹ ara rẹ jẹ lori ọrọ ọhun.
Adeniyan sọ pe "Aafin Olowo ni ẹbẹ ti wa pe ki a wo gbagede naa latari pe wọn ni o lodi si aṣa ilẹ Owo lati kọ irufẹ nnkan bẹẹ si ayika aafin.
"Ijọba yoo kọ gbagede iranti miran."
















