Ìjọba Amẹrika sọ àdó olóró mẹ́ta ọ̀tọ̀tọ̀ sí Iran

Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ Amẹrika, Donald Trump ti kede pe awọn ti sọ ado oloro si ibudo afẹfẹ oloro 'nuclear' mẹta otọọtọ ni Iran, eyii to mu ki ogun to n lọwọ laarin Israel ati Iran tubọ lagbara si.

Ninu atẹjade kan loju opo X rẹ, Trump ni "A ti ṣe aṣeyọri ninu sisọ ado oloro si ojuko nuclear mẹta ni Iran, lara wọn ni Fordow, Natanz, ati Esfahan. Gbogbo awọn ọkọ ofurufu to ṣiṣẹ naa ti kuro loju ofurufu Iran bayii.

"Ado oloro to lagbara kan ṣoṣo ni a sọ si ibi to ṣe koko julọ ni Fordow. Awọn ọkọ ofurufu to ṣiṣẹ naa si ti n pada bọ nile lai farapa.

"Mo ki awọn jagun jagun Amẹrika ku oriire fun aṣeyọri yii nitori ko si ileeṣẹ ọmọ ogun mii to le ṣe irufẹ iṣẹ bẹẹ lagbaye. Asiko ti to bayii lati jiroro alaafia."

Lasiko to n ba awọn ọmọ orilẹede naa sọrọ, Trump sọ pe yatọ si awọn ibi ti wọn sọ ado oloro si yii, awọn ibomiran ṣi wa ti wọn yoo ṣi kọlu ti ijọba Iran ko ba ju ọwọ silẹ.

Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Donald Trump

O ni "ti wọn ba kọ lati gba alaafia laaye, a o lọ si awọn agbegbe to ku lati sọ ado oloro sibẹ lai ṣe aṣiṣe kankan."

Awọn alaṣẹ ni Israel ti sọ pe gbogbo igbesẹ Amẹrika lati ṣọṣẹ ni Iran yii ko ṣẹyin awọn.

Ẹwẹ, ṣaaju ni awọn alaṣẹ orilẹede Iran ti kilọ pe, awọn yoo gbẹsan ti Amẹrika ba le kọlu wọn.

Awọn ibo ni Amẹrika ju ado oloro si ati pe ado oloro wo ni wọn lo?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn ibudo ti wọn ti n po ohun elo afẹfẹ oloro nuclear pọ ni Fordo, Natanz ati Isfahan ni AMẹrikma kọlu.

Agbegbe kan ti apata pọ si ni Guusu Tehran ni Fordo wa, igbagbọ si wa pe abẹ iho ninu apata kan ni wọn kọ si.

Iroyin ni, iho ti Fordow wa yii lọ titi de ilẹ Gẹẹsi ati ati orilẹede France.

Inu ibi ti Fordow wa naa mu ko nira fun ohun ija oloro orilẹede Israel lati de ibẹ to si jẹ pe ilẹ Amẹrika nikan lo ni ado oloro to le rin irinajo wọ ilẹ titi de ibi ti Fordow ọhun wa.

Orukọ ado oloro ti Amẹrika lo ni wọn n pe ni GBU-57 Massive Ordnance Penetrator (MOP).

Iwọn rẹ jẹ ẹgbẹrun mẹtala kilo, o si le rinrinajo wọ ilẹ titi de mita mọkanlelogota tabi mita mẹrindinlogun ogiri ti wọn fi simẹnti ṣe, ko to o bu gbamu.

A gbọ pe nnkan bii ọgọrin si aaadọrin mita inu ilẹ ni Fordow wa, eyi to tumọ si pe, o ṣe e ṣe ki ado oloro MOP kuna amọ ado oloro naa nikan lo le gbiyanju lati de ibẹ.

Bo tilẹ jẹ pe ikọlu Amẹrika yii ti din agbara Iran ku, orilẹede naa ti sọ pe oun ko ni ṣai gbẹsan ti Amẹrika ba da si ija oun ati Israel nipa kikọlu oun.