Wo àwòrán láti Gúúsù Israel lẹ́yìn ìkọlù Iran

Aworan

Oríṣun àwòrán, EPA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ija jiju ado oloro laarin orilẹede Israel ati Iran tun tẹsiwaju ni aṣalẹ mọjumọ.

Iran kọlu ilu Beersheba, to w ani agbegbe guusu orilẹede Israel, ti eeyan mọkanlelaadọrin si farapa yanayana gẹgẹ bii ohun minisita fun eto ilera sọ.

Aworan ọhun tun ṣafihan bi ina ṣe n jo ileeṣẹ Microsoft in Beersheba ni guusu orilẹede Israel.

Awọn panapana ati oṣiṣẹ alabo ti balẹ sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye. Eeyan marun un lo farapa ni orumọju, ti wọn si ti gbe wọn lọ si ile iwosan fun itọju.

Aworan mii nipa ikọlu naa ti tẹwalọwọ, eyi to n ṣafihan bi ikọlu ṣe ba ilu naa jẹ, paapa awọn ile gbe.

O da bi pe Iran fẹ fa ajalu si imọ ẹrọ Gav-Yam, eyin ti wọn ni awọn n lepa ni owurọ ana nigba ti ado oloro kọlu ile iwosan Soroka.

Ẹwẹ ni apa ti orilẹede Israel, ajọ to n mojuto ado oloro nuclear fidi rẹ mulẹ pe ikọlu Israel si ibudo nuclear ti wọn n kọlu ni ẹgbẹ ilu Arak ṣe akoba nla fun ile pataki to wa nibẹ.

Ni Ọjọru ni ikọlu yii waye ṣugbọn ajọ IAEA ni ikọlu ko ba ohun ija Iran kankan jẹ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Israel Firefighters

Aworan

Oríṣun àwòrán, EPA

Aworan

Oríṣun àwòrán, EPA

Wo nnkan ti awọn ẹrọ momaworan Iran n sọ nipa ikọlu Israel

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn ileeṣẹ tẹlifisan Iran ni wọn ti n kan sara si ikọlu ado oloro si Israel, eyi wọn ṣapejuwe gẹgẹ bii aṣeyọri to munadoko.

Bakan naa ni wọn ko kọ bi ara si ipa ti ado oloro ti Israel n ju si ilu wọn lojojumọ ati bi ọpọ awọn olori ologun ṣe n padanu ẹmi wọn.

Ẹwẹ, awọn alaṣẹ Iran n gbiyanju lati ṣe igbelarugẹ iṣokan awọn ọmọ orilẹede Iran lati tako Israel.

Bakan naa ni ọwọ ti tẹ awọn to n yọju wọ Iran ti Israel ran wa.

Ikọlu Israel ti sọ ọpọ ọmọ orilẹede Iran di ẹni ti ko ni anfani si ẹrọ ayelujara, ti o si nira fun wọn lati san owo fun ọpọ nnkan lati ori ayelujara.

Awọn orilẹede wo ni wọn ti bẹrẹ si ni ko awọn eeyan kuro Iran ati Israel

Aworan ikolu Israel

Oríṣun àwòrán, EPA

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọpọ awọn orilẹede kaakiri agbaye ni wọn ti bẹrẹ si ni palẹmọ awọn eeyan wọn kuro ni orilẹede Iran ati Israel pẹlu bi wọn ṣe n ṣe pasiparọ ado oloro laarin ara wọn.

Ni ilẹ Afrika, awọn orilẹede bii Naijiria, Ghana ati awọn ti n wa ọna lati ko awọn eeyan kuro ni orilẹede Iran ati Israel.

Nigeria

Orilẹede Naijiria ti bẹrẹ si ni ṣe igbaradi lati ko awọn eeyan wọn kuro ni orilẹede Israel ati Iran

Awọn aṣoju Naijiria ni awọn ilu mejeeji ti gba awọn eeyan ni imọran lati wa si ile orilẹede naa lati ibẹrẹ iforukọ silẹ.

Eyi lo wa ninu atẹjade ti ajọ to n risi ọrọ ile Okere lorilẹede naa fi lede fun awọn akọroyin niluu Abuja.

"Ijọba ti n ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ajọ agbaye ati ti ẹsẹ kuku lati ko awọn eeyan rẹ kuro ni lorilẹede Iran ati Israel."

Ghana

Ijọba Ghana ni igbesẹ kiakia ni awọn n gbe lati ko awọn eeyan wọn kuro lorilẹede Iran.

Bakan naa ni ijọba ni awọn ti ile ilẹkun ileeṣẹ to n soju Ghana ni Tehran pa bayii lati le doola ẹmi awọn oṣiṣẹ wọn.

Ẹwẹ ninu Isreal, Ijọba Ghana ko ti sọ ohunkohun nipa kiko awọn eeyan rẹ kuro nitori ijọba Israel ti ẹnu ibode si orileede naa pa.

Awọn alaṣẹ Ghana ti wa fi da awọn eeyan wọn loju pe laipẹ awọn yoo bẹrẹ si ni ko awọn eeyan jade kuro ni orilẹede naa.

Uganda

Ijọba Uganda ni awọn ti kan si awọn orilẹede Middle East fun iranlọwọ lati ko awọn eeyan wọn jade, ileeṣẹ iroyin aladani Chimp Reports ṣalaye.

Pẹlu bi Uganda ko ṣe ni aṣoju ni Israel ati Iran, ti wọn titi ẹnu ibode wọn, ijọba Uganda fẹ lo anfani ko awọn eeyan wọn jade lati orilẹede Egypt, Turkey, Azerbaijan, ati Jordan.

Ijọba tib ere lọwọ orilẹede mẹrin fun fisa fun awọn eeyan wọn.

Kenya

Ijọba Kenya ti kesi awọn eeyan lati ṣe ni oju ni alakan fi sọri, ti wọn si ma rin si ibi ti ikọlu ti n waye.

Wọn awọn eeyan ni imọran lati ma jade sita nigba ti ko yẹ, ki wọn si tẹle awọn ofin ilu naa.

Bakan naa ni wọn jẹ ko di mimọ pe awọn eeyan wọn ni ore ọfẹ lati kan si ọfisi aṣoju wọn ti wọn ba nilo ohunkohun tabi ipe pajawiri ni Tel Aviv ati Tehran.

South Africa

Ijọba orilẹede South Africa ti ni ki awọn eeyan wọn lọ forukọ silẹ ni ileeṣẹ wọn ni Iran fun aabo to yẹ.

Eyi wa ninu atẹjade kan ti wọn fi lede, ti wọn si jẹ ko di mimọ ijọba orilẹede South Africa le ma ni anfani lati ṣe iranlọwọ fun Iran nigba ti wọn b anilo rẹ.