Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Nnamdi Kanu ní kí a sin òkú adarí Ipob pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún méjì orí èèyan, a ti pa ọgbọ̀n èèyàn kí ọwọ́ ọlọ́pàá tó tẹ̀ wá
Ọrọ yii lo jẹyọ lasiko igbẹjọ adari ẹgbẹ Ipob, Nnamdi Kanu, niluu Abuja
Oṣiṣẹ ajọ DSS kan to n jẹri tako Kanu nile ẹjọ ọhun sọ pe, ọkan lara awọn ọmọ ogun Ipob ti ọwọ tẹ lo sọ bẹẹ
Lọ soju opo BBC Yoruba fun ẹkunrẹrẹ
_____________________________________
Ijọba Amẹrika ti kede pe awọn to ba fẹ kawe nilẹ naa ti le bẹrẹ si n kọwe fun fisa bayii
Amọ wọn ni irufẹ ẹni bẹẹ gbọdọ ṣi oju opo ayelujara rẹ silẹ fun awọn lati ṣofintoto rẹ
Wọn ni igbesẹ naa ṣe pataki lati ti ilẹkun mọ awọn ọta Amẹrika to fẹ wọ ilẹ naa
___________________________________-
Ariwo ẹkun sọ niluu Eha-Amufu , nijọba ibilẹ Isiuzo nipinlẹ Enugu lẹyin ti awọn agbebọn ṣekupa eeyan mọkan nibẹ
A gbọ pe asiko ti awọn eeyan n sun loru ọganjọ lawọn agbebọn ya wọ agbegbe naa ti kii si ṣe igba akọkọ wọn
Fun ẹkunrẹrẹ